Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 4:1-43

4  Àwọn ọmọkùnrin Júdà ni Pérésì,+ Hésírónì+ àti Kámì+ àti Húrì+ àti Ṣóbálì.+  Ní ti Reáyà+ ọmọkùnrin Ṣóbálì, ó bí Jáhátì; Jáhátì, ẹ̀wẹ̀, bí Áhúmáì àti Láhádì. Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn Sórátì.+  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin baba Étámì:+ Jésíréélì+ àti Íṣímà àti Ídíbáṣì, (orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haselelipónì,)  àti Pénúélì baba Gédórì+ àti Ésérì baba Húṣà. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Húrì+ àkọ́bí Éfúrátà baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+  Áṣíhúrì+ baba Tékóà+ sì wá ní aya méjì, Hélà àti Náárà.  Nígbà tí ó ṣe, Náárà bí Áhúsámù àti Héfà àti Téménì àti Hááháṣítárì fún un. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Náárà.  Àwọn ọmọkùnrin Hélà sì ni Sérétì, Ísárì àti Étínánì.  Ní ti Kósì, ó bí Ánúbù àti Sóbébà àti àwọn ìdílé Áhárélì ọmọkùnrin Hárúmù.  Jábésì+ sì wá ní ọlá+ ju àwọn arákùnrin rẹ̀; ìyá rẹ̀ sì ni ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jábésì, ó wí pé: “Mo bí i nínú ìrora.”+ 10  Jábésì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Ọlọ́run+ Ísírẹ́lì, pé: “Bí ìwọ yóò bá bù kún+ mi láìsí àní-àní, tí o sì sọ ìpínlẹ̀+ mi di títóbi ní tòótọ́, tí ọwọ́+ rẹ sì wà pẹ̀lú mi ní ti gidi, tí o sì pa mí mọ́ ní ti gidi kúrò nínú ìyọnu àjálù,+ kí ó má bàa ṣe mí lọ́ṣẹ́,+—” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run mú ohun tí ó béèrè ṣẹ.+ 11  Ní ti Kélúbù arákùnrin Ṣúhà, ó bí Méhírì, tí í ṣe baba Éṣítónì. 12  Éṣítónì, ẹ̀wẹ̀, bí Bẹti-ráfà àti Páséà àti Téhínà baba Iri-náháṣì. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin Rékà. 13  Àwọn ọmọkùnrin Kénásì+ sì ni Ótíníẹ́lì+ àti Seráyà, àti àwọn ọmọkùnrin Ótíníẹ́lì, Hátátì. 14  Ní ti Mèónótáì, ó bí Ọ́fírà. Ní ti Seráyà, ó bí Jóábù baba Ge-háráṣímù; nítorí pé oníṣẹ́ ọnà+ ni wọ́n. 15  Àwọn ọmọkùnrin Kálébù+ ọmọkùnrin Jéfúnè+ sì ni Írù, Éláhì àti Náámù; àti àwọn ọmọkùnrin Éláhì, Kénásì. 16  Àwọn ọmọkùnrin Jéhálélélì sì ni Sífù àti Sífà, Tíríà àti Ásárélì. 17  Àwọn ọmọkùnrin Ésírà sì ni Jétà àti Mérédì àti Éférì àti Jálónì; ó sì wá lóyún Míríámù àti Ṣámáì àti Íṣíbà baba Éṣítémóà.+ 18  Ní ti aya rẹ̀ tí í ṣe Júù, ó bí Jérédì baba Gédórì àti Hébà baba Sókò àti Jékútíélì baba Sánóà. Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Bitáyà ọmọbìnrin Fáráò, tí Mérédì fẹ́. 19  Àwọn ọmọkùnrin aya Hodáyà, arábìnrin Náhámù, sì ni baba Kéílà+ tí í ṣe Gámì àti Éṣítémóà ará Máákátì. 20  Àwọn ọmọkùnrin Ṣímónì sì ni Ámínónì àti Rínà, Bẹni-hánánì àti Tílónì. Àwọn ọmọkùnrin Íṣì sì ni Sóhétì àti Bẹni-sóhétì. 21  Àwọn ọmọkùnrin Ṣélà+ ọmọkùnrin Júdà ni Éérì baba Lékà àti Láádà baba Máréṣà àti àwọn ìdílé ilé àwọn oníṣẹ́ aṣọ híhun àtàtà+ ti ilé Áṣíbéà; 22  àti Jókímù àti àwọn ọkùnrin Kósébà àti Jóáṣì àti Sáráfì, àwọn tí ó di olúwa àwọn aya tí í ṣe ará Móábù,+ àti Jaṣubi-léhémù. Àwọn àsọjáde náà sì jẹ́ ti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtijọ́.+ 23  Àwọn ni amọ̀kòkò+ àti olùgbé Nétáímù àti Gédérà. Pẹ̀lú ọba nínú iṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ń gbé ibẹ̀.+ 24  Àwọn ọmọkùnrin Síméónì ni Némúẹ́lì+ àti Jámínì,+ Járíbù, Síírà, Ṣọ́ọ̀lù,+ 25  Ṣálúmù ọmọkùnrin rẹ̀, Míbúsámù ọmọkùnrin rẹ̀, Míṣímà ọmọkùnrin rẹ̀. 26  Àwọn ọmọkùnrin Míṣímà sì ni Hámúélì ọmọkùnrin rẹ̀, Sákúrì ọmọkùnrin rẹ̀, Ṣíméì ọmọkùnrin rẹ̀. 27  Ṣíméì sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà; ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò ní ọmọkùnrin púpọ̀, kò sì sí ìkankan nínú ìdílé wọn tí ó ní ọmọkùnrin tí ó pọ̀ tó ti Júdà.+ 28  Wọ́n sì ń bá a lọ ní gbígbé ní Bíá-ṣébà+ àti Móládà+ àti Hasari-ṣúálì+ 29  àti ní Bílíhà+ àti ní Ésémù+ àti ní Tóládì+ 30  àti ní Bẹ́túélì+ àti ní Hóómà+ àti ní Síkílágì+ 31  àti ní Bẹti-mákábótì àti ní Hasari-súsímù+ àti ní Bẹti-bírì àti ní Ṣááráímù.+ Ìwọ̀nyí ni ìlú ńlá wọn títí di ìgbà tí Dáfídì jọba. 32  Ibi ìtẹ̀dó wọn sì ni Étámì àti Áyínì, Rímónì àti Tókénì àti Áṣánì,+ ìlú ńlá márùn-ún. 33  Gbogbo ibi ìtẹ̀dó wọn tí ó sì wà ní gbogbo àyíká ìlú ńlá wọ̀nyí lọ jìnnà títí dé Báálì.+ Ìwọ̀nyí ni ibi gbígbé wọn àti àwọn àkọsílẹ̀ orúkọ ìtàn ìlà ìdílé wọn fún wọn. 34  Àti Méṣóbábù àti Jámílẹ́kì àti Jóṣà ọmọkùnrin Amasááyà, 35  àti Jóẹ́lì àti Jéhù ọmọkùnrin Joṣibáyà ọmọkùnrin Seráyà ọmọkùnrin Ásíélì, 36  àti Élíóénáì àti Jáákóbà àti Jeṣoháyà àti Ásáyà àti Ádíélì àti Jésímíélì àti Bẹnáyà, 37  àti Sísà ọmọkùnrin Ṣífì ọmọkùnrin Álónì ọmọkùnrin Jedáyà ọmọkùnrin Ṣímúrì ọmọkùnrin Ṣemáyà. 38  Àwọn wọ̀nyí tí orúkọ wọ́n wọlé jẹ́ àwọn ìjòyè láàárín ìdílé wọn,+ agbo ilé náà tí ó jẹ́ ti àwọn baba ńlá wọn sì pọ̀ sí i ní ògìdìgbó. 39  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ọ̀nà àbáwọ Gédórì, títí lọ dé ìlà-oòrùn àfonífojì, láti lọ wá pápá ìjẹko fún àwọn agbo ẹran wọn. 40  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n rí pápá ìjẹko tí ó lọ́ràá tí ó sì dára,+ ilẹ̀ náà sì gbòòrò gan-an, kò sì ní ìyọlẹ́nu+ rárá, ṣùgbọ́n ó wà ní ìdẹ̀rùn; nítorí pé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ ní àwọn ìgbà àtijọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Hámù.+ 41  Àwọn wọ̀nyí tí a ṣe àkọsílẹ̀ wọn ní orúkọ-orúkọ sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé wá ní àwọn ọjọ́ Hesekáyà+ ọba Júdà, wọ́n sì wó+ àgọ́ àwọn ọmọ Hámù àti ti Méúnímù èyí tí ó wà níbẹ̀ palẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun+ títí di òní yìí; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní àyè wọn, nítorí pé pápá ìjẹko+ wà níbẹ̀ fún àwọn agbo ẹran wọn. 42  Láti inú wọn, a sì rí díẹ̀ lára àwọn ọmọkùnrin Síméónì tí wọ́n lọ sí Òkè Ńlá Séírì,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin, pẹ̀lú Pẹlatáyà àti Nearáyà àti Refáyà àti Úsíélì àwọn ọmọkùnrin Íṣì tí wọ́n ṣe olórí wọn. 43  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àṣẹ́kù tí ó sá àsálà láti inú Ámálékì+ balẹ̀, wọ́n sì ń bá a lọ ní gbígbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé