Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 29:1-30

29  Wàyí o, Dáfídì Ọba sọ fún gbogbo ìjọ+ náà pé: “Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi, ẹni tí Ọlọ́run yàn,+ jẹ́ ọ̀dọ́,+ ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ṣùgbọ́n iṣẹ́ náà pọ̀; nítorí ilé aláruru náà kì í ṣe fún ènìyàn,+ bí kò ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run.  Gẹ́gẹ́ bí gbogbo agbára mi+ sì ni mo ti fi pèsè sílẹ̀+ fún ilé Ọlọ́run mi, wúrà+ fún iṣẹ́ ọnà wúrà, àti fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà, àti bàbà fún iṣẹ́ ọnà bàbà, irin+ fún iṣẹ́ ọnà irin, àti àwọn ẹ̀là gẹdú+ fún iṣẹ́ ọnà ẹ̀là gẹdú; àwọn òkúta ónísì,+ àti àwọn òkúta tí a ó fi erùpẹ̀ àpòrọ́ líle mọ, àti àwọn òkúta róbótó-róbótó onírúurú àwọ̀, àti gbogbo òkúta iyebíye, àti àwọn òkúta alabásítà ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.  Níwọ̀n bí mo sì ti ní ìdùnnú+ nínú ilé Ọlọ́run mi, àkànṣe dúkìá kan tí ó jẹ́ tèmi+ ṣì wà, wúrà àti fàdákà; mo fi í fún ilé Ọlọ́run mi ní àfikún sí àti lékè gbogbo ohun tí mo ti pèsè sílẹ̀ fún ilé mímọ́ náà:+  ẹgbẹ̀ẹ́dógún tálẹ́ńtì wúrà ti wúrà Ófírì,+ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin tálẹ́ńtì fàdákà tí a yọ́ mọ́, fún fífi bo ògiri àwọn ilé náà;  ti wúrà fún iṣẹ́ ọnà wúrà, àti ti fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà àti fún gbogbo iṣẹ́ nípa ọwọ́ àwọn oníṣẹ́ ọnà. Ta sì ni ń bẹ níbẹ̀ tí ó fẹ́ fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ rẹ̀ lónìí fún Jèhófà?”+  Àwọn ọmọ aládé+ ti àwọn ìdí ilé baba+ àti àwọn ọmọ aládé+ ti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn olórí iṣẹ́ àmójútó+ ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n fi wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún tálẹ́ńtì fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó dáríkì àti fàdákà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tálẹ́ńtì àti bàbà tí iye rẹ̀ tó ẹgbàásàn-án tálẹ́ńtì àti irin tí iye rẹ̀ tó ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ńtì.+  Àwọn òkúta tí a sì rí lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni ni wọ́n fi fún ìṣúra ilé Jèhófà lábẹ́ ìdarí Jéhíélì+ ọmọ Gẹ́ṣónì.+  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ lórí ṣíṣe tí wọ́n ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, nítorí pé ọkàn-àyà pípé pérépéré ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún Jèhófà;+ Dáfídì Ọba pàápàá sì yọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà.+ 10  Nítorí náà, Dáfídì fi ìbùkún+ fún Jèhófà lójú gbogbo ìjọ+ náà, Dáfídì sì wí pé: “Ìbùkún ni fún ọ,+ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ baba wa, láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin. 11  Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi+ àti agbára ńlá+ àti ẹwà+ àti ìtayọlọ́lá+ àti iyì;+ nítorí ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé jẹ́ tìrẹ.+ Tìrẹ ni ìjọba,+ Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo.+ 12  Ọrọ̀+ àti ògo+ jẹ́ ní tìtorí rẹ, ìwọ sì jọba lé+ ohun gbogbo; ọwọ́ rẹ sì ni agbára+ àti agbára ńlá+ wà, ọwọ́ rẹ sì ni agbára láti sọni di ńlá+ wà àti láti fi okun fún gbogbo ènìyàn.+ 13  Wàyí o, Ọlọ́run wa, àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,+ a sì ń yin+ orúkọ rẹ alẹ́wàlógo.+ 14  “Síbẹ̀síbẹ̀, ta ni èmi,+ ta sì ni àwọn ènìyàn mi, tí àwa yóò fi ní agbára láti ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe bí èyí?+ Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá,+ láti ọwọ́ rẹ wá sì ni a ti fi fún ọ. 15  Nítorí àtìpó ni àwa jẹ́ níwájú rẹ àti olùtẹ̀dó,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo àwọn baba ńlá wa. Bí òjìji ni àwọn ọjọ́ wa rí lórí ilẹ̀ ayé,+ kò sì sí ìrètí kankan. 16  Jèhófà Ọlọ́run wa, gbogbo ọ̀pọ̀ yanturu yìí tí a ti pèsè sílẹ̀ láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọwọ́ rẹ ni ó ti wá, tìrẹ sì ni gbogbo rẹ̀ jẹ́.+ 17  Mo sì mọ̀ dáadáa, ìwọ Ọlọ́run mi, pé ìwọ jẹ́ olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà,+ àti pé ìwà òtítọ́ ni ìwọ ní ìdùnnú sí.+ Èmi, ní tèmi, ti fínnú-fíndọ̀ fún ọ ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí nínú ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà mi, nísinsìnyí mo ti gbádùn rírí àwọn ènìyàn rẹ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó níhìn-ín tí wọ́n ń ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún ọ. 18  Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì baba ńlá wa,+ pa èyí mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ,+ kí o sì darí ọkàn-àyà wọn sọ́dọ̀ rẹ.+ 19  Kí o sì fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi ní ọkàn-àyà pípé pérépéré+ láti pa àwọn àṣẹ+ rẹ, àwọn gbólóhùn ẹ̀rí+ rẹ àti àwọn ìlànà+ rẹ mọ́, àti láti ṣe ohun gbogbo, àti láti kọ́ ilé aláruru+ tí mo ti ṣe ìpèsèsílẹ̀ fún.”+ 20  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún gbogbo ìjọ+ náà pé: “Wàyí o, ẹ fi ìbùkún+ fún Jèhófà Ọlọ́run yín.” Gbogbo ìjọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìbùkún fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀,+ wọ́n sì wólẹ̀+ fún Jèhófà àti fún ọba. 21  Wọ́n sì ń bá a lọ láti rú+ àwọn ẹbọ sí Jèhófà, wọ́n sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé ọjọ́ yẹn, ẹgbẹ̀rún ẹgbọrọ akọ màlúù, ẹgbẹ̀rún àgbò, ẹgbẹ̀rún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn,+ àní àwọn ẹbọ ní iye púpọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì.+ 22  Wọ́n sì ń bá a lọ ní jíjẹ àti ní mímu níwájú Jèhófà ní ọjọ́ yẹn pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà;+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fi Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì jẹ ọba+ ní ìgbà kejì, wọ́n sì fòróró yàn án fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú+ àti Sádókù+ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 23  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí jókòó sórí ìtẹ́ Jèhófà+ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò Dáfídì baba rẹ̀, ó sì ṣe é ní àṣeyọrí sí rere,+ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì jẹ́ onígbọràn sí i. 24  Ní ti gbogbo àwọn ọmọ aládé+ àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá+ àti gbogbo àwọn ọmọ Dáfídì Ọba+ pẹ̀lú, wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún Sólómọ́nì Ọba. 25  Jèhófà sì ń bá a lọ ní sísọ Sólómọ́nì di ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá+ lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi iyì ọba sára rẹ̀, irúfẹ́ èyí tí kò tíì sí rí lára ọba èyíkéyìí ṣáájú rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì.+ 26  Ní ti Dáfídì ọmọkùnrin Jésè, ó jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì;+ 27  àwọn ọjọ́ tí ó sì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì ọdún.+ Ní Hébúrónì, ó jọba fún ọdún méje,+ ní Jerúsálẹ́mù, ó jọba fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.+ 28  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an,+ ó kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́, ọrọ̀+ àti ògo;+ Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.+ 29  Ní ti àwọn àlámọ̀rí Dáfídì Ọba, àwọn ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì aríran+ àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ Nátánì+ wòlíì àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ Gádì+ olùríran, 30  pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ipò ọba rẹ̀ àti agbára ńlá rẹ̀ àti àwọn àkókò+ tí ó kọjá lórí rẹ̀ àti lórí Ísírẹ́lì àti lórí gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé