Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 28:1-21

28  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti pe gbogbo ọmọ aládé+ Ísírẹ́lì jọpọ̀, àwọn ọmọ aládé+ ti àwọn ẹ̀yà àti àwọn ọmọ aládé+ ti ìpín àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn olórí gbogbo ẹrù+ àti ohun ọ̀sìn+ ọba àti ti àwọn ọmọ rẹ̀,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ààfin+ àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá,+ àti olúkúlùkù akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin, sí Jerúsálẹ́mù.  Nígbà náà ni Dáfídì ọba dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wí pé: “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin arákùnrin mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Ní ti èmi, ó wà ní góńgó ọkàn-àyà mi+ láti kọ́ ilé ìsinmi fún àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti gẹ́gẹ́ bí àpótí ìtìsẹ̀+ Ọlọ́run wa, mo sì ti ṣe ìpèsèsílẹ̀ láti kọ́lé.+  Ọlọ́run tòótọ́ fúnra rẹ̀ sì wí fún mi pé, ‘Ìwọ kì yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi;+ nítorí ọkùnrin ogun ni ọ́, ìwọ sì ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.’+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí nínú gbogbo ilé baba mi+ láti di ọba+ lórí Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin; nítorí Júdà ni ó yàn ṣe aṣáájú,+ ní ilé Júdà, ilé baba mi,+ àti lára àwọn ọmọkùnrin baba mi,+ èmi sì ni ẹni tí ó fọwọ́ sí,+ láti fi mí jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì;  nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin mi (nítorí àwọn ọmọkùnrin tí Jèhófà fi fún mi pọ̀)+ ó sì wá yan Sólómọ́nì+ ọmọkùnrin mi láti jókòó sórí ìtẹ́+ àkóso Jèhófà lórí Ísírẹ́lì.  “Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, ‘Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi+ àti àwọn àgbàlá mi; nítorí mo ti yàn án gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin mi,+ èmi fúnra mi yóò sì di baba rẹ̀.+  Dájúdájú, èmi yóò fìdí ipò ọba+ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin bí òun yóò bá pinnu láìyíhùn padà láti pa àwọn àṣẹ+ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.’  Wàyí o, lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ìjọ Jèhófà,+ àti ní etí Ọlọ́run wa,+ ẹ kíyè sí, kí ẹ sì wá gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ lè ni ilẹ̀ rere náà,+ kí ẹ sì lè ta àtaré rẹ̀ dájúdájú gẹ́gẹ́ bí ogún sí àwọn ọmọ yín lẹ́yìn yín fún àkókò tí ó lọ kánrin.  “Àti ìwọ, Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi, mọ+ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré+ àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn+ sìn ín;+ nítorí gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá,+ gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.+ Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun;+ ṣùgbọ́n bí o bá fi í sílẹ̀,+ òun yóò ta ọ́ nù títí láé.+ 10  Wò ó, nísinsìnyí, nítorí Jèhófà tìkára rẹ̀ ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan gẹ́gẹ́ bí ibùjọsìn. Jẹ́ onígboyà kí o sì gbé ìgbésẹ̀.”+ 11  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ ní àwòrán ìkọ́lé+ ti gọ̀bì+ àti ti àwọn ilé rẹ̀ àti àwọn yàrá ìtọ́jú nǹkan pa mọ́+ rẹ̀ àti àwọn ìyẹ̀wù òrùlé+ rẹ̀ àti àwọn yàrá rẹ̀ ṣíṣókùnkùn ti inú lọ́hùn-ún àti ilé ìbòrí ìpẹ̀tù;+ 12  àní àwòrán ìkọ́lé ohun gbogbo tí ó wá wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmísí+ fún àwọn àgbàlá+ ilé Jèhófà àti fún gbogbo àwọn yàrá ìjẹun+ yí ká, fún àwọn ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti fún àwọn ìṣúra àwọn ohun tí a sọ di mímọ́;+ 13  àti fún ìpín+ àwọn àlùfáà àti ti àwọn ọmọ Léfì àti fún gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà àti fún gbogbo nǹkan èlò ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà; 14  fún wúrà nípa ìwọ̀n, wúrà fún gbogbo nǹkan èlò fún onírúurú iṣẹ́ ìsìn, fún gbogbo nǹkan èlò fàdákà nípa ìwọ̀n, fún gbogbo nǹkan èlò+ fún onírúurú iṣẹ́ ìsìn; 15  àti ìwọ̀n fún àwọn ọ̀pá fìtílà+ wúrà àti àwọn fìtílà wúrà wọn, nípa ìwọ̀n onírúurú ọ̀pá fìtílà àti àwọn fìtílà wọn, àti fún àwọn ọ̀pá fìtílà fàdákà nípa ìwọ̀n fún ọ̀pá fìtílà àti àwọn fìtílà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn onírúurú ọ̀pá fìtílà; 16  àti wúrà nípa ìwọ̀n fún àwọn tábìlì búrẹ́dì onípele,+ fún onírúurú tábìlì, àti fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà; 17  àti àwọn àmúga àti àwọn àwokòtò+ àti àwọn orù ògidì wúrà, àti fún àwọn àwokòtò kéékèèké+ wúrà nípa ìwọ̀n fún onírúurú àwokòtò kéékèèké, àti fún àwọn àwokòtò kéékèèké fàdákà nípa ìwọ̀n fún onírúurú àwokòtò kéékèèké; 18  àti fún pẹpẹ tùràrí+ wúrà tí a yọ́ mọ́ nípa ìwọ̀n àti fún àwòrán kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ èyíinì ni, àwọn kérúbù+ wúrà fún nína ìyẹ́ apá wọn jáde tí wọ́n sì fi bo orí àpótí májẹ̀mú Jèhófà. 19  “Ó pèsè ìjìnlẹ̀ òye fún gbogbo rẹ̀ pátá nínú àkọsílẹ̀+ nípa ọwọ́ Jèhófà tí ń bẹ lára mi, àní fún gbogbo iṣẹ́ àwòrán ìkọ́lé náà.”+ 20  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Jẹ́ onígboyà+ àti alágbára kí o sì gbé ìgbésẹ̀. Má fòyà+ tàbí kí o jáyà,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ.+ Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì+ tàbí kí ó fi ọ́ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà yóò fi parí. 21  Ìpín àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì+ sì nìyí fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́; gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán+ tí ó ní òye iṣẹ́ fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn+ sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo iṣẹ́ náà, àti àwọn ọmọ aládé+ àti gbogbo àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, fún gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé