Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 27:1-34

27  Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa iye wọn, àwọn olórí ìdí ilé baba+ àti àwọn olórí+ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín wọn tí ń ṣe ìránṣẹ́+ fún ọba nínú gbogbo ọ̀ràn ìpín àwọn tí ń wọlé wá àti àwọn tí ń jáde lọ ní oṣooṣù ní gbogbo oṣù tí ó wà nínú ọdún, ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì.  Lórí ìpín kìíní ti oṣù kìíní ni Jáṣóbéámù+ ọmọkùnrin Sábídíẹ́lì, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín rẹ̀.  Àwọn kan lára àwọn ọmọ Pérésì+ olórí gbogbo àwọn olórí àwọn àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn wà fún oṣù kìíní.  Àti lórí ìpín ti oṣù kejì ni Dódáì+ ọmọ Áhóhì+ pẹ̀lú ìpín tirẹ̀, Míkílótì sì ni aṣáájú, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀.  Olórí àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn kẹta fún oṣù kẹta ni Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà+ olórí àlùfáà, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀.  Bẹnáyà+ yìí jẹ́ alágbára ńlá lára ọgbọ̀n,+ ó sì wà lórí ọgbọ̀n náà; Ámísábádì ọmọkùnrin rẹ̀ sì wà lórí ìpín tirẹ̀.  Ìkẹrin fún oṣù kẹrin ni Ásáhélì,+ arákùnrin Jóábù,+ àti Sebadáyà ọmọkùnrin rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀.  Olórí karùn-ún fún oṣù karùn-ún ni Ṣámíhútì+ tí í ṣe Ísíráhì, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀.  Ìkẹfà fún oṣù kẹfà ni Írà+ ọmọkùnrin Íkéṣì+ ará Tékóà,+ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 10  Ìkeje fún oṣù keje ni Hélésì+ tí í ṣe Pélónì+ lára àwọn ọmọ Éfúráímù, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 11  Ìkẹjọ fún oṣù kẹjọ ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà lára àwọn ọmọ Síírà,+ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 12  Ìkẹsàn-án fún oṣù kẹsàn-án ni Abi-ésérì+ ọmọ Ánátótì+ lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 13  Ìkẹwàá fún oṣù kẹwàá ni Máháráì+ ará Nétófà lára àwọn ọmọ Síírà,+ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 14  Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá ni Bẹnáyà+ ará Pírátónì lára àwọn ọmọ Éfúráímù,+ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 15  Ìkejìlá fún oṣù kejìlá ni Hélídáì+ ará Nétófà, ti Ótíníẹ́lì, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ni ó sì wà nínú ìpín tirẹ̀. 16  Lórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì,+ lára àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Élíésérì ọmọkùnrin Síkírì sì ni aṣáájú; lára àwọn ọmọ Síméónì, Ṣẹfatáyà ọmọkùnrin Máákà; 17  lára Léfì, Haṣabáyà ọmọkùnrin Kémúélì; lára Áárónì, Sádókù;+ 18  lára Júdà, Élíhù,+ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin Dáfídì;+ lára Ísákárì, Ómírì ọmọkùnrin Máíkẹ́lì; 19  lára Sébúlúnì, Iṣimáyà ọmọkùnrin Ọbadáyà; lára Náfútálì, Jérímótì ọmọkùnrin Ásíríẹ́lì; 20  lára àwọn ọmọ Éfúráímù, Hóṣéà ọmọkùnrin Asasáyà; lára ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, Jóẹ́lì ọmọkùnrin Pedáyà; 21  lára ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Gílíádì, Ídò ọmọkùnrin Sekaráyà; lára Bẹ́ńjámínì, Jáásíélì ọmọkùnrin Ábínérì;+ 22  lára Dánì, Ásárẹ́lì ọmọkùnrin Jéróhámù. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọ aládé+ ti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. 23  Dáfídì kò sì ka iye àwọn tí ó jẹ́ láti ẹni ogún ọdún sísàlẹ̀, nítorí pé Jèhófà ti ṣèlérí láti sọ Ísírẹ́lì di púpọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ tí ó wà ní ojú ọ̀run.+ 24  Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà alára ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kíkà náà, ṣùgbọ́n kò parí rẹ̀;+ nítorí èyí, ìkannú+ sì wá wà lòdì sí Ísírẹ́lì, iye náà kò sì wọnú ìròyìn àwọn àlámọ̀rí àwọn ọjọ́ Dáfídì Ọba. 25  Lórí àwọn ìṣúra ọba+ sì ni Ásímáfẹ́tì ọmọkùnrin Ádíélì. Lórí àwọn ìṣúra ní pápá,+ ní àwọn ìlú ńlá+ àti ní àwọn abúlé àti nínú àwọn ilé gogoro sì ni Jónátánì ọmọkùnrin Ùsáyà. 26  Lórí àwọn olùṣe iṣẹ́ ní pápá,+ fún ríro ilẹ̀, sì ni Ẹ́síráì ọmọkùnrin Kélúbù. 27  Lórí àwọn ọgbà àjàrà+ sì ni Ṣíméì ará Rámà; lórí èyíinì tí ó wà nínú àwọn ọgbà àjàrà fún ìpèsè wáìnì sì ni Sábídì tí í ṣe Ṣífímì. 28  Lórí àwọn oko ólífì àti àwọn igi síkámórè+ tí ó wà ní Ṣẹ́fẹ́là+ sì ni Baali-hánánì ará Gédérì; lórí ìpèsè òróró+ sì ni Jóáṣì. 29  Lórí àwọn ọ̀wọ́ ẹran tí ń jẹko ní Ṣárónì+ sì ni Ṣítíráì ará Ṣárónì; lórí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ sì ni Ṣáfátì ọmọkùnrin Ádíláì. 30  Lórí àwọn ràkúnmí+ sì ni Óbílì ọmọ Íṣímáẹ́lì;+ lórí àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ni Jedeáyà ará Mérónótì. 31  Lórí àwọn agbo ẹran sì ni Jásísì ọmọ Hágárì. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni olórí àwọn ẹrù tí í ṣe ti Dáfídì Ọba. 32  Jónátánì,+ ọmọ arákùnrin Dáfídì, sì jẹ́ agbani-nímọ̀ràn, ọkùnrin olóye,+ ó tún jẹ́ akọ̀wé; Jéhíélì ọmọkùnrin Hákímónì+ sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ọba.+ 33  Áhítófẹ́lì+ sì jẹ́ agbani-nímọ̀ràn+ fún ọba; Húṣáì+ tí í ṣe Áríkì+ sì ni alábàákẹ́gbẹ́+ ọba. 34  Lẹ́yìn Áhítófẹ́lì sì ni Jèhóádà ọmọkùnrin Bẹnáyà+ àti Ábíátárì;+ Jóábù+ sì ni olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé