Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 26:1-32

26  Ní ti ìpín ti àwọn aṣọ́bodè:+ Lára àwọn ọmọ Kórà,+ Meṣelemáyà+ ọmọkùnrin Kórè lára àwọn ọmọ Ásáfù.  Meṣelemáyà sì ní àwọn ọmọkùnrin: Sekaráyà àkọ́bí, Jédáélì ìkejì, Sebadáyà ìkẹta, Játíníélì ìkẹrin,  Élámù ìkarùn-ún, Jèhóhánánì ìkẹfà, Elieho-énáì ìkeje.  Obedi-édómù+ sì ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣemáyà àkọ́bí, Jèhósábádì ìkejì, Jóà ìkẹta àti Sákà ìkẹrin àti Nétánélì ìkarùn-ún,  Ámíélì ìkẹfà, Ísákárì ìkeje, Péúlétáì ìkẹjọ; nítorí pé Ọlọ́run bù kún un.+  Fún Ṣemáyà ọmọkùnrin rẹ̀, a sì bí àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olùṣàkóso ilé baba wọn, nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ọkùnrin dídáńgájíá, alágbára ńlá.  Àwọn ọmọkùnrin Ṣemáyà, Ótínì àti Réfáélì àti Óbédì, Élísábádì, tí àwọn arákùnrin wọn dáńgájíá, Élíhù àti Semakáyà.  Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ lára àwọn ọmọkùnrin Obedi-édómù, àwọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá tí wọ́n ní agbára fún iṣẹ́ ìsìn náà, méjìlélọ́gọ́ta jẹ́ ti Obedi-édómù.  Meṣelemáyà+ sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá, méjìdínlógún. 10  Hósà lára àwọn ọmọ Mérárì sì ní àwọn ọmọkùnrin. Ṣímúrì ni olórí, nítorí pé òun kọ́ ni àkọ́bí+ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ yàn án ṣe olórí;+ 11  Hilikáyà ìkejì, Tebaláyà ìkẹta, Sekaráyà ìkẹrin. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin Hósà jẹ́ mẹ́tàlá. 12  Lára ìpín wọ̀nyí tí í ṣe ti àwọn aṣọ́bodè, àwọn onípò orí ní àwọn iṣẹ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn ti ní,+ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ní ilé Jèhófà. 13  Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ fún ẹni kékeré lọ́nà kan náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún ẹni ńlá nípa ìdí ilé baba wọn,+ fún onírúurú ẹnubodè. 14  Nígbà náà ni ìpín síhà ìlà-oòrùn bọ́ sọ́wọ́ Ṣelemáyà.+ Wọ́n ṣẹ́ kèké fún Sekaráyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, agbani-nímọ̀ràn+ pẹ̀lú ọgbọ́n inú, ìpín tirẹ̀ sì jáde wá síhà àríwá.+ 15  Ti Obedi-édómù wá síhà gúúsù, àwọn ọmọkùnrin+ rẹ̀ ni ó sì ni àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí.+ 16  Ti Ṣúpímù àti Hósà+ wá síhà ìwọ̀-oòrùn nítòsí Ẹnubodè Ṣálékétì lẹ́bàá òpópó tí ó lọ sókè, tí àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́+ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́;+ 17  síhà ìlà-oòrùn àwọn ọmọ Léfì mẹ́fà ni ó wà; síhà àríwá fún ọjọ́ kan,+ mẹ́rin; síhà gúúsù fún ọjọ́ kan, mẹ́rin; àti fún àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí,+ méjì-méjì; 18  fún ìloro olórùlé síhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin ní òpópó,+ méjì ní ìloro olórùlé. 19  Ìwọ̀nyí ni ìpín àwọn aṣọ́bodè láti inú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kórà+ àti lára àwọn ọmọ Mérárì.+ 20  Ní ti àwọn ọmọ Léfì, Áhíjà ni ó ń bójú tó àwọn ìṣúra+ ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn ìṣúra àwọn ohun tí a sọ di mímọ́.+ 21  Àwọn ọmọ Ládánì,+ àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì tí wọ́n jẹ́ ti Ládánì; àwọn olórí ìdí ilé baba tí wọ́n jẹ́ ti Ládánì ọmọ Gẹ́ṣónì, Jẹ́híélì.+ 22  Àwọn ọmọkùnrin Jẹ́híélì, Sétámù àti Jóẹ́lì+ arákùnrin rẹ̀, ni wọ́n ń bójú tó àwọn ìṣúra+ ilé Jèhófà. 23  Fún àwọn ọmọ Ámúrámù, fún àwọn ọmọ Ísárì, fún àwọn ọmọ Hébúrónì, fún àwọn ọmọ Úsíélì,+ 24  àní Ṣẹ́búẹ́lì+ ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù ọmọkùnrin Mósè ni aṣáájú lórí àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí. 25  Ní ti àwọn arákùnrin rẹ̀, ti Élíésérì,+ Rehabáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ ń bẹ àti Jeṣáyà ọmọkùnrin rẹ̀ àti Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ àti Síkírì ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ṣẹ́lómótì ọmọkùnrin rẹ̀. 26  Ṣẹ́lómótì yìí àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ni wọ́n ń bójú tó gbogbo àwọn ìṣúra àwọn ohun tí a sọ di mímọ́,+ tí Dáfídì+ Ọba àti àwọn olórí ìdí ilé baba,+ àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ di mímọ́. 27  Láti inú ogun+ àti láti inú ohun ìfiṣèjẹ+ ni wọ́n ti sọ àwọn nǹkan di mímọ́ láti máa fi tọ́jú ilé Jèhófà. 28  Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo ohun tí Sámúẹ́lì aríran+ àti Sọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Kíṣì àti Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì àti Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà+ ti sọ di mímọ́. Ohun tí ẹnikẹ́ni sọ di mímọ́ wà lábẹ́ àkóso Ṣẹ́lómítì àti àwọn arákùnrin rẹ̀. 29  Lára àwọn ọmọ Ísárì,+ Kenanáyà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà fún iṣẹ́ àmójútó ti òde+ gẹ́gẹ́ bí àwọn onípò àṣẹ àti gẹ́gẹ́ bí àwọn onídàájọ́+ lórí Ísírẹ́lì. 30  Lára àwọn ọmọ Hébúrónì,+ Haṣabáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ni wọ́n wà lórí iṣẹ́ àbójútó Ísírẹ́lì ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì níhà ìwọ̀-oòrùn fún gbogbo iṣẹ́ Jèhófà àti fún iṣẹ́ ìsìn ọba. 31  Lára àwọn ọmọ Hébúrónì, Jéríjà+ ni olórí àwọn ọmọ Hébúrónì nípa ìran-ìran rẹ̀ nípa àwọn baba ńlá. Ọdún ogójì+ àkóso Dáfídì ni a wá wọn jáde, a sì wá rí àwọn akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin lára wọn ní Jásérì+ ní Gílíádì.+ 32  Àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá,+ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá, àwọn olórí ìdí ilé baba.+ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì Ọba yàn wọ́n lórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè,+ fún gbogbo ọ̀ràn Ọlọ́run tòótọ́ àti ọ̀ràn+ ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé