Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 24:1-31

24  Wàyí o, àwọn ọmọ Áárónì ní àwọn ìpín tiwọn. Àwọn ọmọkùnrin Áárónì ni Nádábù+ àti Ábíhù,+ Élíásárì+ àti Ítámárì.+  Àmọ́ ṣá o, Nádábù àti Ábíhù+ kú ṣáájú baba wọn,+ wọn kò sì ní ọmọkùnrin kankan, ṣùgbọ́n Élíásárì+ àti Ítámárì ń bá a lọ láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.  Dáfídì, àti Sádókù+ láti inú àwọn ọmọ Élíásárì, àti Áhímélékì+ láti inú àwọn ọmọ Ítámárì sì bẹ̀rẹ̀ sí pín wọn sí àwọn ìpín fún ipò iṣẹ́ wọn nínú iṣẹ́ ìsìn wọn.+  Ṣùgbọ́n a rí i pé àwọn ọmọkùnrin Élíásárì tí í ṣe onípò orí pọ̀ níye ju àwọn ti ọmọkùnrin Ítámárì. Nítorí náà, wọ́n pín wọn fún àwọn ọmọkùnrin Élíásárì, gẹ́gẹ́ bí olórí fún àwọn ìdí ilé baba wọn, mẹ́rìndínlógún, àti fún àwọn ọmọkùnrin Ítámárì, gẹ́gẹ́ bí olórí fún àwọn ìdí ilé baba wọn, mẹ́jọ.  Síwájú sí i, wọ́n fi kèké+ pín wọn, àwọn wọ̀nyí pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì, nítorí tí àwọn olórí ibi mímọ́+ àti àwọn olórí ti Ọlọ́run tòótọ́ ní láti wà láti inú àwọn ọmọ Élíásárì àti láti inú àwọn ọmọ Ítámárì.  Nígbà náà ni Ṣemáyà ọmọkùnrin Nétánélì akọ̀wé+ láti inú àwọn ọmọ Léfì kọ wọ́n sílẹ̀ níwájú ọba àti àwọn ọmọ aládé àti Sádókù+ àlùfáà àti Áhímélékì+ ọmọkùnrin Ábíátárì+ àti àwọn olórí àwọn baba ti àwọn àlùfáà àti ti àwọn ọmọ Léfì,+ ìdí ilé kan ti baba ni a mú fún Élíásárì+ ọ̀kan sì ni a mú fún Ítámárì.+  Kèké náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá: èkíní fún Jèhóáríbù;+ ìkejì fún Jedáyà,  ìkẹta fún Hárímù, ìkẹrin fún Séórímù,  ìkarùn-ún fún Málíkíjà, ìkẹfà fún Míjámínì, 10  ìkeje fún Hákósì, ìkẹjọ fún Ábíjà,+ 11  ìkẹsàn-án fún Jéṣúà, ìkẹwàá fún Ṣẹkanáyà, 12  ìkọkànlá fún Élíáṣíbù, ìkejìlá fún Jákímù, 13  ìkẹtàlá fún Húpà, ìkẹrìnlá fún Jéṣébéábù, 14  ìkẹẹ̀ẹ́dógún fún Bílígà, ìkẹrìndínlógún fún Ímérì, 15  ìkẹtàdínlógún fún Hésírì, ìkejìdínlógún fún Hápísésì, 16  ìkọkàndínlógún fún Petaháyà, ogún fún Jéhésíkélì, 17  ìkọkànlélógún fún Jákínì, ìkejìlélógún fún Gámúlì, 18  ìkẹtàlélógún fún Deláyà, ìkẹrìnlélógún fún Maasáyà. 19  Ìwọ̀nyí ni ipò iṣẹ́+ wọn fún iṣẹ́ ìsìn+ wọn, láti wá sínú ilé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó tọ́ sí wọn+ nípa ọwọ́ Áárónì baba ńlá wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti pàṣẹ fún un. 20  Àti lára àwọn ọmọ Léfì tí ó ṣẹ́ kù, lára àwọn ọmọ Ámúrámù+ ni Ṣúbáélì;+ lára àwọn ọmọ Ṣúbáélì, Jedeáyà; 21  lára Rehabáyà:+ lára àwọn ọmọ Rehabáyà, Isiṣáyà olórí; 22  lára àwọn ọmọ Ísárì,+ Ṣẹ́lómótì;+ lára àwọn ọmọ Ṣẹ́lómótì, Jáhátì; 23  àti àwọn ọmọkùnrin Hébúrónì,+ Jeráyà+ olórí, Amaráyà ìkejì, Jahasíẹ́lì ìkẹta, Jekaméámì ìkẹrin. 24  Àwọn ọmọkùnrin Úsíélì, Míkà; lára àwọn ọmọ Míkà,+ Ṣámírù. 25  Arákùnrin Míkà ni Isiṣáyà; lára àwọn ọmọ Isiṣáyà, Sekaráyà. 26  Àwọn ọmọkùnrin Mérárì+ ni Máhílì+ àti Múṣì;+ àwọn ọmọkùnrin Jaasáyà, Bénò. 27  Àwọn ọmọ Mérárì: Lára Jaasáyà, Bénò àti Ṣóhámù àti Sákúrì àti Íbírì. 28  Lára Máhílì, Élíásárì, ẹni tí kò wá ní ọmọkùnrin kankan.+ 29  Lára Kíṣì: àwọn ọmọkùnrin Kíṣì ni Jéráméélì. 30  Àwọn ọmọkùnrin Múṣì sì ni Máhílì+ àti Édérì àti Jérímótì.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọ Léfì nípa ìdí ilé baba+ wọn. 31  Àwọn fúnra wọn pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ kèké,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Áárónì ti ṣe níwájú Dáfídì Ọba àti Sádókù àti Áhímélékì àti àwọn olórí àwọn ìdí ilé baba ti àwọn àlùfáà àti ti àwọn ọmọ Léfì. Ní ti àwọn ìdí ilé baba,+ olórí jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ti jẹ́ gan-an.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé