Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 22:1-19

22  Nígbà náà ni Dáfídì sọ pé: “Èyí ni ilé+ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, èyí sì jẹ́ pẹpẹ+ kan fún ọrẹ ẹbọ sísun fún Ísírẹ́lì.”  Wàyí o, Dáfídì sọ pé kí a kó àwọn àtìpó+ tí ń bẹ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì jọpọ̀, nígbà náà, ó yàn wọ́n ṣe agbẹ́kùúta+ láti máa gbẹ́ àwọn òkúta tí ó dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin+ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́.  Dáfídì sì pèsè irin sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ láti fi ṣe ìṣó fún ilẹ̀kùn àwọn ẹnubodè àti fún àwọn ẹ̀mú-amóhunpọ̀, àti bàbà pẹ̀lú ní iye tí ó pọ̀ débi pé ó ré kọjá wíwọ̀n,+  àti ẹ̀là gẹdú kédárì+ pẹ̀lú láìníye; nítorí pé àwọn ọmọ Sídónì+ àti àwọn ará Tírè+ kó ẹ̀là gẹdú kédárì wá fún Dáfídì ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì sọ pé: “Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi jẹ́ ọ̀dọ́, ó sì ṣe ẹlẹgẹ́,+ ilé tí a óò kọ́ fún Jèhófà yóò sì jẹ́ ọlọ́lá ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá+ ní ti ìtayọ alẹ́wàlógo+ ní gbogbo àwọn ilẹ̀. Nítorí náà, jẹ́ kí n ṣe ìpèsèsílẹ̀ fún un.” Nípa báyìí, Dáfídì ṣe ìpèsèsílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ṣáájú ikú rẹ̀.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó pe Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ kí ó lè pàṣẹ fún un láti kọ́ ilé fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Ní ti èmi, ó wà ní góńgó ọkàn-àyà mi+ láti kọ́ ilé fún orúkọ+ Jèhófà Ọlọ́run mi.  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Jèhófà wá lòdì sí mi, pé, ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀,+ o sì ti ja àwọn ogun ńláńlá.+ Ìwọ kì yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ nítorí o ti ta ẹ̀jẹ̀ sórí ilẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ níwájú mi.  Wò ó! A óò bí ọmọkùnrin+ kan fún ọ. Òun fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ ọkùnrin tí ó ní ìsinmi, dájúdájú, èmi yóò fún un ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yí ká;+ nítorí Sólómọ́nì+ ni orúkọ rẹ̀ yóò jẹ́, àlàáfíà+ àti ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ni èmi yóò sì fi jíǹkí Ísírẹ́lì ní àwọn ọjọ́ rẹ̀. 10  Òun ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ òun fúnra rẹ̀ yóò sì di ọmọkùnrin+ mi, èmi yóò sì di baba+ rẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò fìdí ìtẹ́ àkóso+ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in lórí Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ 11  “Wàyí o, ọmọkùnrin mi, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere, kí o sì kọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.+ 12  Kìkì pé kí Jèhófà fún ọ ní ọgbọ́n inú àti òye,+ kí ó sì pa àṣẹ fún ọ nípa Ísírẹ́lì, àní láti máa pa òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́.+ 13  Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ṣe àṣeyọrí sí rere+ bí o bá kíyè sí àtimú àwọn ìlànà+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ ṣẹ, tí Jèhófà pa láṣẹ+ fún Mósè nípa Ísírẹ́lì. Jẹ́ onígboyà àti alágbára.+ Má fòyà+ tàbí kí o jáyà.+ 14  Sì kíyè sí i, nígbà ṣíṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́,+ mo ti pèsè ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ńtì wúrà+ sílẹ̀ fún ilé Jèhófà àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ tálẹ́ńtì fàdákà, àti bàbà+ àti irin+ láìsí ọ̀nà tí a fi lè wọ̀n wọ́n nítorí tí wọ́n wá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀n; mo sì ti pèsè àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yóò ṣe àwọn àfikún sí wọn. 15  Àwọn tí ó pọ̀ ní iye sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ tí wọ́n jẹ́ olùṣe iṣẹ́, àwọn agbẹ́kùúta àti oníṣẹ́ òkúta+ àti igi àti olúkúlùkù ẹni tí ó jáfáfá nínú gbogbo onírúurú iṣẹ́.+ 16  Kò sí ọ̀nà bí a ṣe lè ka iye wúrà, fàdákà àti bàbà àti irin.+ Dìde kí o sì gbé ìgbésẹ̀,+ kí Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ.”+ 17  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ran Sólómọ́nì ọmọkùnrin òun lọ́wọ́, pé: 18  “Jèhófà Ọlọ́run yín kò ha wà pẹ̀lú yín bí,+ kò ha sì ti fún yín ní ìsinmi ní gbogbo àyíká?+ Nítorí ó ti fi àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́, a sì ti tẹ ilẹ̀ náà lórí ba níwájú Jèhófà+ àti níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀. 19  Wàyí o, ẹ gbé ọkàn-àyà yín àti ọkàn+ yín lé ṣíṣe ìwádìí nípa Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ dìde kí ẹ sì kọ́ ibùjọsìn+ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́,+ láti gbé àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà àti àwọn nǹkan èlò mímọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́ wá sínú ilé tí a kọ́ fún orúkọ+ Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé