Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 21:1-30

21  Sátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí Ísírẹ́lì, ó sì ru Dáfídì lọ́kàn sókè+ láti ka iye Ísírẹ́lì.  Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Jóábù+ àti àwọn olórí àwọn ènìyàn náà pé: “Lọ, ka+ Ísírẹ́lì láti Bíá-ṣébà+ dé Dánì+ kí o sì mú un wá fún mi kí n lè mọ iye wọn.”+  Ṣùgbọ́n Jóábù sọ pé: “Kí Jèhófà fi kún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún iye tí wọ́n jẹ́.+ Olúwa mi ọba, gbogbo wọn pátá kì í ha ṣe ti olúwa mi gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ bí? Èé ṣe tí olúwa mi fi ń wá èyí?+ Èé ṣe tí òun yóò fi di okùnfà ẹ̀bi fún Ísírẹ́lì?”  Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀rọ̀ ọba+ borí ti Jóábù, tí ó fi jẹ́ pé Jóábù jáde lọ,+ ó sì rin gbogbo Ísírẹ́lì já, lẹ́yìn èyí tí ó wá sí Jerúsálẹ́mù.+  Wàyí o, Jóábù fi iye ìforúkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn náà fún Dáfídì; gbogbo Ísírẹ́lì sì jẹ́ ọ̀kẹ́ márùndínlọ́gọ́ta àwọn ọkùnrin tí ń fa idà yọ,+ Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún ó lé ẹgbàáàrún àwọn ọkùnrin tí ń fa idà yọ.  Kò sì forúkọ Léfì+ àti Bẹ́ńjámínì sílẹ̀ pẹ̀lú wọn,+ nítorí pé ọ̀rọ̀ ọba jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jóábù.  Wàyí o, ohun yìí burú ní ojú Ọlọ́run tòótọ́,+ nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣá Ísírẹ́lì balẹ̀.  Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Mo ti ṣẹ̀+ gidigidi ní ti pé mo ti ṣe ohun yìí. Wàyí o, jọ̀wọ́, mú kí ìṣìnà ìránṣẹ́ rẹ kọjá lọ;+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Gádì,+ olùríran+ fún Dáfídì sọ̀rọ̀ pé: 10  “Lọ, kí o sì bá Dáfídì sọ̀rọ̀ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí èmi yóò dojú rẹ̀ kọ ọ́.+ Yan ọ̀kan nínú wọn fún ara rẹ, kí èmi lè ṣe é sí ọ.”’”+ 11  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Gádì wọlé lọ bá Dáfídì+ ó sì sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Mú èyí tí o bá fẹ́, 12  yálà fún ọdún mẹ́ta, kí ìyàn mú;+ tàbí fún oṣù mẹ́ta, kí gbígbálọ kúrò níwájú àwọn elénìní+ rẹ ṣẹlẹ̀, kí idà àwọn ọ̀tá rẹ sì lé ọ bá, tàbí fún ọjọ́ mẹ́ta, kí idà Jèhófà+ kí ó wà, àní àjàkálẹ̀ àrùn,+ ní ilẹ̀ yìí, pẹ̀lú áńgẹ́lì Jèhófà tí yóò mú ìparun+ wá ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì.’ Wàyí o, wá ohun tí èmi yóò fi fèsì fún Ẹni tí ó rán mi.” 13  Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Èyí mú wàhálà-ọkàn bá mi gidigidi. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà,+ nítorí àánú rẹ̀ pọ̀ púpọ̀;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn.”+ 14  Nígbà náà ni Jèhófà mú àjàkálẹ̀ àrùn+ bá Ísírẹ́lì, tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ ènìyàn ṣubú ní Ísírẹ́lì.+ 15  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọ́run tòótọ́ rán áńgẹ́lì kan sí Jerúsálẹ́mù láti mú ìparun wá bá a;+ gbàrà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìparun wá, Jèhófà rí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́dùn nítorí ìyọnu àjálù náà;+ nítorí náà, ó sọ fún áńgẹ́lì tí ń mú ìparun náà wá pé: “Ó tó!+ Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ wálẹ̀ wàyí.” Áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró nítòsí ilẹ̀ ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.+ 16  Nígbà tí Dáfídì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó wá rí áńgẹ́lì+ Jèhófà tí ó dúró láàárín ilẹ̀ ayé àti ọ̀run pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fà yọ+ ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó nà síhà Jerúsálẹ́mù; Dáfídì àti àwọn àgbà ọkùnrin, tí wọ́n fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora,+ sì da ojú wọn bolẹ̀ kíákíá.+ 17  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Èmi ha kọ́ ni ó sọ pé kí a ka iye àwọn ènìyàn náà, èmi ha sì kọ́ ni ó ṣẹ̀, tí ó sì ṣe búburú láìsí tàbí-ṣùgbọ́n?+ Ní ti àwọn àgùntàn wọ̀nyí,+ kí ni wọ́n ṣe? Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ wà lára èmi àti ilé baba mi; ṣùgbọ́n kí ó má ṣe jẹ́ lára àwọn ènìyàn rẹ,+ ní mímú òjòjò àrànkálẹ̀ wá bá wọn.” 18  Áńgẹ́lì Jèhófà, ní tirẹ̀, sì sọ fún Gádì+ pé kí ó sọ fún Dáfídì pé kí Dáfídì gòkè lọ gbé pẹpẹ kan nà ró fún Jèhófà ní ilẹ̀ ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì.+ 19  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì gòkè lọ nípa ọ̀rọ̀ Gádì tí ó sọ ní orúkọ Jèhófà.+ 20  Láàárín àkókò yìí, Ọ́nánì+ yí padà ó sì rí áńgẹ́lì náà; àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì fi ara wọn pa mọ́. Wàyí o, Ọ́nánì ń pakà àlìkámà. 21  Nítorí náà, Dáfídì lọ títí ó fi dé ọ̀dọ̀ Ọ́nánì. Nígbà tí Ọ́nánì wò tí ó sì rí Dáfídì,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó jáde kúrò ní ilẹ̀ ìpakà náà, ó sì tẹrí ba fún Dáfídì ní dídojúbolẹ̀. 22  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Fún mi ní ibi ilẹ̀ ìpakà yìí, kí n lè mọ pẹpẹ kan sí ibẹ̀ fún Jèhófà. Fi fún mi ní iye owó+ rẹ̀ kíkún,+ kí a lè dáwọ́ òjòjò àrànkálẹ̀+ náà dúró lára àwọn ènìyàn náà.” 23  Ṣùgbọ́n Ọ́nánì sọ fún Dáfídì pé: “Mú un fi ṣe tìrẹ,+ kí olúwa mi ọba sì ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú tirẹ̀. Wò ó, mo pèsè màlúù+ fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti ohun èlò ìpakà+ fún igi+ àti àlìkámà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà. Gbogbo rẹ̀ ni mo pèsè.”+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì Ọba sọ fún Ọ́nánì pé: “Rárá, ṣùgbọ́n láìkùnà, èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ kíkún,+ nítorí pé èmi kì yóò gbé ohun tí ó jẹ́ tìrẹ lọ fún Jèhófà láti fi rú àwọn ẹbọ sísun láìná nǹkan kan.” 25  Nítorí náà, Dáfídì fún Ọ́nánì ní àwọn ṣékélì wúrà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta+ fún ibẹ̀. 26  Lẹ́yìn náà ni Dáfídì mọ pẹpẹ+ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà,+ ẹni tí ó fi iná+ dá a lóhùn wàyí láti ọ̀run lórí pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun. 27  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jèhófà bá áńgẹ́lì náà sọ̀rọ̀,+ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó dá idà rẹ̀ padà sínú àkọ̀ rẹ̀. 28  Ní àkókò yẹn, nígbà tí Dáfídì rí i pé Jèhófà ti dá òun lóhùn ní ilẹ̀ ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì, ó ń bá a lọ láti rúbọ níbẹ̀.+ 29  Ṣùgbọ́n àgọ́ ìjọsìn Jèhófà tí Mósè ṣe ní aginjù àti pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun wà ní ibi gíga Gíbéónì ní àkókò yẹn.+ 30  Dáfídì kò sì tíì lè lọ síwájú rẹ̀ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nítorí pé ìpayà+ ti bá a nítorí idà áńgẹ́lì Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé