Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 20:1-8

20  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo ọdún,+ nígbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun,+ pé Jóábù bẹ̀rẹ̀ sí ṣíwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun agbóguntini,+ ó sì run ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì, ó sì wá sàga ti Rábà,+ nígbà tí Dáfídì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù; Jóábù sì tẹ̀ síwájú láti kọlu+ Rábà, ó sì wó o palẹ̀.  Ṣùgbọ́n Dáfídì mú adé Málíkámù kúrò ní orí rẹ̀,+ ó sì rí i pé ó jẹ́ tálẹ́ńtì wúrà kan ní ìwọ̀n, àwọn òkúta iyebíye sì ń bẹ nínú rẹ̀; ó sì wá wà ní orí Dáfídì. Ohun ìfiṣèjẹ tí ó kó jáde láti inú ìlú ńlá náà sì pọ̀ gidigidi.+  Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó sì kó jáde, ó sì fi wọ́n sí ẹnu iṣẹ́+ nídìí fífi ayùn rẹ́ òkúta àti nídìí àwọn ohun èlò mímú tí a fi irin ṣe àti nídìí àáké;+ bẹ́ẹ̀ sì ni Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àwọn ọmọ Ámónì. Níkẹyìn, Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà padà sí Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí pé ogun bẹ̀rẹ̀ sí bẹ́ sílẹ̀ ní Gésérì+ pẹ̀lú àwọn Filísínì.+ Nígbà yẹn ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà ṣá Sípáì balẹ̀ tí í ṣe ara àwọn tí a bí fún àwọn Réfáímù,+ tí a fi tẹ̀ wọ́n lórí ba.  Ogun sì tún wá wà pẹ̀lú àwọn Filísínì; Élíhánánì+ ọmọkùnrin Jáírì sì ṣá Láámì arákùnrin Gòláyátì+ ará Gátì balẹ̀, ẹni tí ẹ̀rú ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ìtì igi àwọn olófì.+  Ogun sì tún wá wà ní Gátì,+ nígbà tí ọkùnrin kan báyìí wà tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀,+ ẹni tí àwọn ìka ọwọ́ àti ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹ́fà-mẹ́fà, mẹ́rìnlélógún;+ òun, pẹ̀lú, ni a sì bí fún àwọn Réfáímù.+  Ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣáátá+ Ísírẹ́lì. Níkẹyìn, Jónátánì ọmọkùnrin Ṣíméà+ arákùnrin Dáfídì ṣá a balẹ̀.  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a bí fún àwọn Réfáímù+ ní Gátì;+ wọ́n sì wá ṣubú+ nípa ọwọ́ Dáfídì àti nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé