Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 2:1-55

2  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì:+ Rúbẹ́nì,+ Síméónì,+ Léfì+ àti Júdà,+ Ísákárì+ àti Sébúlúnì,+  Dánì,+ Jósẹ́fù+ àti Bẹ́ńjámínì,+ Náfútálì,+ Gádì+ àti Áṣérì.+  Àwọn ọmọkùnrin Júdà ni Éérì+ àti Ónánì+ àti Ṣélà.+ Àwọn mẹ́ta yìí ni ọmọbìnrin Ṣúà, obìnrin ará Kénáánì, bí fún un. Éérì àkọ́bí Júdà sì wá burú ní ojú Jèhófà, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ikú pa á.+  Támárì+ aya ọmọ rẹ̀ ni ó sì bí Pérésì+ àti Síírà fún un. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Júdà jẹ́ márùn-ún.  Àwọn ọmọkùnrin Pérésì ni Hésírónì àti Hámúlù.+  Àwọn ọmọkùnrin Síírà+ sì ni Símírì àti Étánì àti Hémánì àti Kálíkólì àti Dárà.+ Gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.  Àwọn ọmọkùnrin Kámì+ sì ni Ákárì, ẹni tí ó mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí Ísírẹ́lì,+ ẹni tí ó hu ìwà àìṣòótọ́ ní ti ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+  Àwọn ọmọkùnrin Étánì+ sì ni Asaráyà.  Àwọn ọmọkùnrin Hésírónì+ tí a bí fún un sì ni Jéráméélì+ àti Rámù+ àti Kélúbáì. 10  Ní ti Rámù, ó bí Ámínádábù.+ Ámínádábù, ẹ̀wẹ̀, bí Náṣónì+ ìjòyè àwọn ọmọ Júdà. 11  Náṣónì, ẹ̀wẹ̀, bí Sálímà.+ Sálímà, ẹ̀wẹ̀, bí Bóásì.+ 12  Bóásì, ẹ̀wẹ̀, bí Óbédì.+ Óbédì, ẹ̀wẹ̀, bí Jésè.+ 13  Jésè, ẹ̀wẹ̀, bí àkọ́bí rẹ̀ Élíábù,+ àti Ábínádábù+ ìkejì, àti Ṣíméà+ ìkẹta, 14  Nétánélì ìkẹrin, Rádáì ìkarùn-ún, 15  Ósémù ìkẹfà, Dáfídì+ ìkeje. 16  Àwọn arábìnrin wọn sì ni Seruáyà àti Ábígẹ́lì;+ àwọn ọmọkùnrin Seruáyà sì ni Ábíṣáì+ àti Jóábù+ àti Ásáhélì,+ mẹ́ta. 17  Ní ti Ábígẹ́lì, ó bí Ámásà;+ baba Ámásà sì ni Jétà+ ọmọ Íṣímáẹ́lì. 18  Ní ti Kálébù ọmọkùnrin Hésírónì,+ ó bí àwọn ọmọkùnrin nípasẹ̀ Ásúbà aya rẹ̀ àti nípasẹ̀ Jéríótì; ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀: Jéṣà àti Ṣóbábù àti Árídónì. 19  Nígbà tí ó ṣe, Ásúbà kú. Nítorí náà, Kálébù fẹ́ Éfúrátì+ fún ara rẹ̀, ẹni tí ó bí Húrì+ fún un nígbà tí ó ṣe. 20  Húrì, ẹ̀wẹ̀, bí Úráì,+ Úráì, ẹ̀wẹ̀, bí Bẹ́sálẹ́lì.+ 21  Lẹ́yìn ìgbà náà, Hésírónì sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírù+ baba Gílíádì.+ Òun fúnra rẹ̀ sì fẹ́ ẹ nígbà tí ó jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún, ṣùgbọ́n ó bí Ségúbù fún un. 22  Ségúbù, ẹ̀wẹ̀, bí Jáírì,+ ẹni tí ó wá ní ìlú ńlá mẹ́tàlélógún+ ní ilẹ̀ Gílíádì. 23  Lẹ́yìn náà, Géṣúrì+ àti Síríà+ gba Hafotu-jáírì+ lọ́wọ́ wọn, pẹ̀lú Kénátì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, ọgọ́ta ìlú ńlá. Gbogbo ìwọ̀nyí ni ọmọ Mákírù baba Gílíádì. 24  Àti pé lẹ́yìn ikú Hésírónì+ ní Kalebu-éfúrátà, ni Ábíjà tí í ṣe aya Hésírónì, wá bí Áṣíhúrì baba Tékóà+ fún un. 25  Àwọn ọmọkùnrin Jéráméélì+ àkọ́bí Hésírónì ni Rámù+ àkọ́bí àti Búnà àti Órénì àti Ósémù, Áhíjà. 26  Jéráméélì sì wá ní aya mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Átárà. Òun ni ìyá Ónámù. 27  Àwọn ọmọkùnrin Rámù+ àkọ́bí Jéráméélì sì wá jẹ́ Máásì àti Jámínì àti Ékérì. 28  Àwọn ọmọkùnrin Ónámù+ sì wá jẹ́ Ṣámáì àti Jádà. Àwọn ọmọkùnrin Ṣámáì sì ni Nádábù àti Ábíṣúrì. 29  Orúkọ aya Ábíṣúrì sì ni Ábíháílì, ẹni tí ó bí Ábánì àti Mólídì fún un nígbà tí ó ṣe. 30  Àwọn ọmọkùnrin Nádábù+ sì ni Sélédì àti Ápáímù. Ṣùgbọ́n Sélédì kú láìní ọmọ. 31  Àwọn ọmọkùnrin Ápáímù sì ni Íṣì. Àwọn ọmọkùnrin Íṣì sì ni Ṣéṣánì;+ àti àwọn ọmọkùnrin Ṣéṣánì, Áláì. 32  Àwọn ọmọkùnrin Jádà arákùnrin Ṣámáì sì ni Jétà àti Jónátánì. Ṣùgbọ́n Jétà kú láìní ọmọ. 33  Àwọn ọmọkùnrin Jónátánì sì ni Péléétì àti Sásà. Ìwọ̀nyí di àwọn ọmọkùnrin Jéráméélì. 34  Ṣéṣánì+ kò sì ní ọmọkùnrin kankan, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin. Wàyí o, Ṣéṣánì ní ìránṣẹ́ kan tí ó jẹ́ ará Íjíbítì,+ ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jááhà. 35  Nítorí náà, Ṣéṣánì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún Jááhà ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fi ṣe aya, ẹni tí ó bí Átáì fún un nígbà tí ó ṣe. 36  Átáì, ẹ̀wẹ̀, bí Nátánì. Nátánì, ẹ̀wẹ̀, bí Sábádì.+ 37  Sábádì, ẹ̀wẹ̀, bí Éfílálì. Éfílálì, ẹ̀wẹ̀, bí Óbédì. 38  Óbédì, ẹ̀wẹ̀, bí Jéhù. Jéhù, ẹ̀wẹ̀, bí Asaráyà. 39  Asaráyà, ẹ̀wẹ̀, bí Hélésì. Hélésì, ẹ̀wẹ̀, bí Éléásà. 40  Éléásà, ẹ̀wẹ̀, bí Sísímáì. Sísímáì, ẹ̀wẹ̀, bí Ṣálúmù. 41  Ṣálúmù, ẹ̀wẹ̀, bí Jekamáyà. Jekamáyà, ẹ̀wẹ̀, bí Élíṣámà. 42  Àwọn ọmọkùnrin Kálébù+ arákùnrin Jéráméélì sì ni Méṣà àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba Sífù, àti àwọn ọmọkùnrin Máréṣà baba Hébúrónì. 43  Àwọn ọmọkùnrin Hébúrónì sì ni Kórà àti Tápúà àti Rékémù àti Ṣémà. 44  Ṣémà, ẹ̀wẹ̀, bí Ráhámù baba Jọ́kéámù. Rékémù, ẹ̀wẹ̀, bí Ṣámáì. 45  Ọmọkùnrin Ṣámáì sì ni Máónì; Máónì sì ni baba Bẹti-súrì.+ 46  Ní ti Eéfà wáhàrì Kálébù, ó bí Háránì àti Mósà àti Gásésì. Ní ti Háránì, ó bí Gásésì. 47  Àwọn ọmọkùnrin Jáádáì sì ni Régémù àti Jótámù àti Géṣánì àti Pélétì àti Eéfà àti Ṣááfà. 48  Ní ti Máákà wáhàrì Kálébù, ó bí Ṣébérì àti Tíhánà. 49  Nígbà tí ó ṣe, ó bí Ṣááfà baba Mádímánà,+ Ṣéfà baba Mákíbénà àti baba Gíbéà.+ Ọmọbìnrin Kálébù+ sì ni Ákúsà.+ 50  Ìwọ̀nyí di àwọn ọmọkùnrin Kálébù. Àwọn ọmọkùnrin Húrì+ àkọ́bí Éfúrátà:+ Ṣóbálì+ baba Kiriati-jéárímù,+ 51  Sálímà baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ Háréfì baba Bẹti-gádérì. 52  Ṣóbálì+ baba Kiriati-jéárímù sì wá ní àwọn ọmọkùnrin: Háróè, ìdajì àwọn Mẹ́núhótì. 53  Ìdílé Kiriati-jéárímù sì ni àwọn Ítírì+ àti àwọn Púútì àti àwọn Ṣúmátì àti àwọn Míṣíráì. Inú àwọn wọ̀nyí ni àwọn Sórátì+ àti àwọn ará Éṣítáólì+ ti jáde wá. 54  Àwọn ọmọkùnrin Sálímà ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ àti àwọn ará Nétófà,+ Atiroti-bẹti-jóábù àti ìdajì àwọn ọmọ Mánáhátì, àti àwọn Sórítì. 55  Ìdílé àwọn akọ̀wé òfin tí ń gbé ní Jábésì+ sì ni àwọn Tírátì, àwọn Ṣímíátì, àwọn Súkátì. Ìwọ̀nyí ni àwọn Kénì+ tí ó wá láti Hémátì baba ilé Rékábù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé