Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 18:1-17

18  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn Filísínì+ balẹ̀, ó sì tẹ̀ wọ́n lórí ba, ó sì gba Gátì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.  Lẹ́yìn náà, ó ṣá Móábù+ balẹ̀, àwọn ọmọ Móábù sì wá di ìránṣẹ́ Dáfídì tí ń mú owó òde wá.+  Dáfídì sì ń bá a lọ láti ṣá Hadadésà+ ọba Sóbà+ balẹ̀ ní Hámátì,+ bí ó ti ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ láti gbé àkóso rẹ̀ kalẹ̀ ní Odò Yúfírétì.+  Síwájú sí i, Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ẹlẹ́ṣin àti ọ̀kẹ́ kan àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn+ lọ́wọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Dáfídì já+ gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́+ náà ní pátì, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí ọgọ́rùn-ún ẹṣin kẹ̀kẹ́ ṣẹ́ kù lára wọn.  Nígbà tí Síríà ti Damásíkù wá ran Hadadésà ọba Sóbà+ lọ́wọ́, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá ọkùnrin balẹ̀ lára àwọn ará Síríà.  Lẹ́yìn ìyẹn, Dáfídì fi àwọn ẹgbẹ́ ogun sí Síríà ti Damásíkù,+ àwọn ará Síríà sì wá di ìránṣẹ́ Dáfídì tí ń mú owó òde wá.+ Jèhófà sì ń bá a nìṣó ní fífún Dáfídì ní ìgbàlà ní ibikíbi tí ó bá lọ.+  Síwájú sí i, Dáfídì gba àwọn apata bìrìkìtì+ wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù.+  Dáfídì sì kó bàbà tí ó pọ̀ gan-an láti Tíbátì+ àti Kúnì, àwọn ìlú ńlá Hadadésà. Òun ni Sólómọ́nì fi ṣe òkun bàbà+ àti àwọn ọwọ̀n+ àti àwọn nǹkan èlò bàbà.+  Nígbà tí Tóù ọba Hámátì+ gbọ́ pé Dáfídì ti ṣá gbogbo ẹgbẹ́ ológun Hadadésà+ ọba Sóbà balẹ̀, 10  lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán Hádórámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sí Dáfídì Ọba láti béèrè nípa àlàáfíà rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ àti láti bá a yọ̀ nítorí òtítọ́ náà pé ó ti bá Hadadésà jà, tí ó sì ṣá a balẹ̀, (nítorí Hadadésà ti di ẹni tí a kọ́ ní iṣẹ́ ogun láti gbéjà ko Tóù,) gbogbo onírúurú ohun èlò wúrà àti fàdákà+ àti bàbà sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 11  Ìwọ̀nyí pẹ̀lú ni Dáfídì Ọba sọ di mímọ́+ fún Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti kó láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,+ láti ọ̀dọ̀ Édómù àti láti ọ̀dọ̀ Móábù+ àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ àti láti ọ̀dọ̀ àwọn Filísínì+ àti láti ọ̀dọ̀ Ámálékì.+ 12  Ní ti Ábíṣáì+ ọmọkùnrin Seruáyà,+ ó ṣá àwọn ọmọ Édómù balẹ̀ ní Àfonífojì Iyọ̀,+ ẹgbàásàn-án. 13  Nítorí náà, ó fi àwọn ẹgbẹ́ ogun sí Édómù, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì wá di ìránṣẹ́ Dáfídì.+ Jèhófà sì ń bá a nìṣó ní gbígba Dáfídì là ní ibikíbi tí ó bá lọ.+ 14  Dáfídì sì ń bá a lọ láti jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìpinnu ìdájọ́ àti òdodo fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 15  Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà sì ni ó wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin Áhílúdù sì ni akọ̀wé-ìrántí. 16  Sádókù+ ọmọkùnrin Áhítúbù àti Áhímélékì+ ọmọkùnrin Ábíátárì sì ni àlùfáà, Ṣáfúṣà+ sì ni akọ̀wé. 17  Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà+ sì ni ó wà lórí àwọn Kérétì+ àti àwọn Pẹ́lẹ́tì;+ àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì ni ó wà ní ipò àkọ́kọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé