Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 16:1-43

16  Bí wọ́n ṣe gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wọlé wá+ nìyẹn, tí wọ́n sì gbé e sínú àgọ́ tí Dáfídì pa fún un;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́.+  Nígbà tí Dáfídì parí rírú ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ náà,+ ó wá bẹ̀rẹ̀ sí súre+ fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Jèhófà.+  Síwájú sí i, ó pín+ ìṣù búrẹ́dì ribiti àti ìṣù èso déètì àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ fún olúkúlùkù, fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin.  Lẹ́yìn náà, ó fi àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì+ síwájú àpótí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́,+ láti máa rántí+ àti láti máa dúpẹ́+ àti láti máa yin+ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,  Ásáfù+ olórí, igbá-kejì rẹ̀ sì ni Sekaráyà, àti Jéélì àti Ṣẹ́mírámótì àti Jéhíélì àti Matitáyà àti Élíábù àti Bẹnáyà àti Obedi-édómù àti Jéélì,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin tí í ṣe olókùn tín-ín-rín àti pẹ̀lú háàpù,+ àti Ásáfù+ pẹ̀lú aro tí ń dún sókè,+  àti Bẹnáyà àti Jahasíẹ́lì àlùfáà pẹ̀lú kàkàkí+ nígbà gbogbo níwájú àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́.  Nígbà náà, ní ọjọ́ yẹn ni Dáfídì ṣe ìtìlẹyìn+ ní ìgbà àkọ́kọ́ láti dúpẹ́+ lọ́wọ́ Jèhófà nípasẹ̀ Ásáfù+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pé:  “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà;+ ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,+ ẸSb sọ àwọn ìṣe rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn!+  Ẹ kọrin+ sí i, ẹ kọ orin atunilára sí i,+ Ẹ máa fi gbogbo àwọn ìṣe àgbàyanu rẹ̀ ṣe ìdàníyàn yín.+ 10  Ẹ máa ṣògo nínú orúkọ+ mímọ́+ rẹ̀, Kí ọkàn-àyà àwọn tí ń wá Jèhófà máa yọ̀.+ 11  Ẹ máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀,+ Ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.+ 12  Ẹ máa rántí àwọn ìṣe àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe,+ Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ ẹnu rẹ̀,+ 13  Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+ 14  Òun ni Jèhófà Ọlọ́run wa;+ gbogbo ilẹ̀ ayé ni àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ wà.+ 15  Ẹ máa rántí májẹ̀mú rẹ̀ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Ọ̀rọ̀ tí ó pa láṣẹ, títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+ 16  Májẹ̀mú tí ó bá Ábúráhámù dá,+ Àti gbólóhùn ìbúra rẹ̀ fún Ísákì.+ 17  Àti gbólóhùn tí ó mú kí ó máa dúró nìṣó gẹ́gẹ́ bí ìlànà àní fún Jékọ́bù,+ Gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin àní fún Ísírẹ́lì,+ 18  Pé, ‘Ìwọ ni èmi yóò fi ilẹ̀ Kénáánì fún,+ Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìpín ogún yín.’+ 19  Èyí jẹ́ nígbà tí ẹ kéré níye,+ Bẹ́ẹ̀ ni, tí ẹ kéré níye gan-an, tí ẹ sì jẹ́ àtìpó nínú rẹ̀.+ 20  Wọ́n sì ń rìn káàkiri ṣáá láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,+ Àti láti ọ̀dọ̀ ìjọba kan dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn.+ 21  Kò gba ẹnikẹ́ni láyè láti lù wọ́n ní jìbìtì,+ Ṣùgbọ́n ó fi ìbáwí tọ́ àwọn ọba sọ́nà ní tìtorí wọn,+ 22  Pé, ‘Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, Ẹ má sì ṣe ohun búburú kankan sí àwọn wòlíì mi.’+ 23  Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tí ń bẹ ní ilẹ̀ ayé!+ Ẹ máa kéde ìgbàlà tí ó ń fi fúnni láti ọjọ́ dé ọjọ́!+ 24  Ẹ máa ṣèròyìn ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, Àwọn ìṣe àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn. 25  Nítorí pé Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi,+ Ó sì yẹ ní bíbẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù.+ 26  Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí.+ Ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run.+ 27  Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú rẹ̀,+ Okun àti ìdùnnú ń bẹ ní ipò rẹ̀.+ 28  Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ìdílé àwọn ènìyàn, Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.+ 29  Ẹ gbé ògo tí ó yẹ orúkọ Jèhófà fún un,+ Ẹ gbé ẹ̀bùn kí ẹ sì wọlé wá síwájú rẹ̀.+ Ẹ tẹrí ba fún Jèhófà nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́.+ 30  Ẹ jẹ ìrora mímúná ní tìtorí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé! Ilẹ̀ eléso pẹ̀lú fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in: A kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.+ 31  Kí ọ̀run kí ó yọ̀, kí ilẹ̀ ayé sì kún fún ìdùnnú,+ Kí wọ́n sì wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé, ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba!’+ 32  Kí òkun sán ààrá àti ohun tí ó kún inú rẹ̀ pẹ̀lú,+ Kí pápá máa yọ ayọ̀ ńláǹlà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.+ 33  Ní àkókò kan náà, kí àwọn igi igbó fi ìdùnnú bú jáde ní tìtorí Jèhófà,+ Nítorí ó ti wá ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé.+ 34  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere,+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 35  Ẹ sì wí pé, ‘Gbà wá là, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa,+ Kí o sì kó wa jọpọ̀, kí o sì dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,+ Kí a lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,+ kí a lè máa fi ayọ̀ ńláǹlà sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ.+ 36  Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti àkókò tí ó lọ kánrin dé àkókò tí ó lọ kánrin.’”+ Gbogbo ènìyàn sì sọ pé, “Àmín!” wọ́n sì fi ìyìn fún Jèhófà.+ 37  Nígbà náà ni ó fi Ásáfù+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́+ níwájú Àpótí nígbà gbogbo, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan béèrè;+ 38  àti Obedi-édómù àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjì-dín-láàádọ́rin, àti Obedi-édómù ọmọkùnrin Jédútúnì àti Hósà gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ́bodè; 39  àti Sádókù+ àlùfáà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àlùfáà níwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà ní ibi gíga tí ó wà ní Gíbéónì,+ 40  láti máa fi àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rúbọ sí Jèhófà lórí pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní òwúrọ̀ àti ní alẹ́ àti fún gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Jèhófà èyí tí ó gbé kalẹ̀ fún Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ;+ 41  àti pẹ̀lú wọn, Hémánì+ àti Jédútúnì àti ìyókù àwọn àṣàyàn ọkùnrin tí a yàn sọ́tọ̀+ nípa orúkọ láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà,+ nítorí tí “inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin”;+ 42  àti pẹ̀lú wọn, Hémánì+ àti Jédútúnì,+ láti máa mú kí kàkàkí+ dún jáde àti aro àti àwọn ohun èlò orin Ọlọ́run tòótọ́; àti àwọn ọmọ+ Jédútúnì ní ẹnubodè. 43  Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, olúkúlùkù sí ilé tirẹ̀.+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì lọ yí ká láti súre fún ilé tirẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé