Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 15:1-29

15  Ó sì ń bá a lọ ní kíkọ́ àwọn ilé+ fún ara rẹ̀ ní Ìlú Ńlá Dáfídì; ó sì tẹ̀ síwájú láti pèsè ibì kan+ sílẹ̀ fún àpótí Ọlọ́run tòótọ́, ó sì pa àgọ́ fún un.  Ìgbà náà ni Dáfídì wí pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ru àpótí Ọlọ́run tòótọ́ bí kò ṣe àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ni Jèhófà ti yàn láti máa ru àpótí Jèhófà+ àti láti máa ṣe ìránṣẹ́+ fún un títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.”  Nígbà náà ni Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù+ láti gbé àpótí+ Jèhófà gòkè wá sí àyè rẹ̀ tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Áárónì+ àti àwọn ọmọ Léfì jọ;  lára àwọn ọmọ Kóhátì, Úríélì+ olórí àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ọgọ́fà;  lára àwọn ọmọ Mérárì,+ Ásáyà+ olórí àti àwọn arákùnrin rẹ̀, okòó-lérúgba;  lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù,+ Jóẹ́lì+ olórí àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àádóje;  lára àwọn ọmọ Élísáfánì,+ Ṣemáyà+ olórí àti àwọn arákùnrin rẹ̀, igba;  lára àwọn ọmọ Hébúrónì, Élíélì olórí àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ọgọ́rin; 10  lára àwọn ọmọ Úsíélì,+ Ámínádábù olórí àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjì-lé-láàádọ́fà. 11  Síwájú sí i, Dáfídì pe Sádókù+ àti Ábíátárì+ àlùfáà, àti àwọn ọmọ Léfì Úríélì,+ Ásáyà+ àti Jóẹ́lì,+ Ṣemáyà+ àti Élíélì+ àti Ámínádábù, 12  ó sì ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni olórí+ àwọn baba àwọn ọmọ Léfì. Ẹ sọ ara yín di mímọ́,+ ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín, kí ẹ sì gbé àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì gòkè wá sí ibi tí mo ti pèsè sílẹ̀ fún un. 13  Nítorí pé ẹ kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́,+ Jèhófà Ọlọ́run wa ya lù wá,+ nítorí a kò wá a gẹ́gẹ́ bí àṣà.”+ 14  Nítorí náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sọ ara wọn di mímọ́+ láti gbé àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì gòkè wá. 15  Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin Léfì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀pá ru+ àpótí Ọlọ́run tòótọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti pàṣẹ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà, lé èjìká wọn.+ 16  Wàyí o, Dáfídì sọ fún àwọn olórí ọmọ Léfì pé kí wọ́n yan àwọn arákùnrin wọn sípò àwọn akọrin+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin,+ àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti háàpù+ àti aro,+ kí wọ́n máa kọrin sókè láti mú kí ìró ayọ̀ yíyọ̀ ròkè. 17  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọmọ Léfì yan Hémánì+ ọmọkùnrin Jóẹ́lì sípò àti, lára àwọn arákùnrin rẹ̀, Ásáfù+ ọmọkùnrin Berekáyà; àti, lára àwọn ọmọ Mérárì arákùnrin wọn, Étánì+ ọmọkùnrin Kuṣáyà; 18  àti pẹ̀lú wọn, àwọn arákùnrin wọn ti ìpín kejì,+ Sekaráyà,+ Bẹ́nì àti Jáásíẹ́lì àti Ṣẹ́mírámótì àti Jéhíélì àti Únì, Élíábù àti Bẹnáyà àti Maaseáyà àti Matitáyà àti Élíféléhù àti Mikinéáyà, àti Obedi-édómù+ àti Jéélì àwọn aṣọ́bodè, 19  àti àwọn akọrin Hémánì+ náà, Ásáfù+ àti Étánì, pẹ̀lú aro bàbà láti fi kọrin sókè;+ 20  àti Sekaráyà àti Ásíẹ́lì+ àti Ṣẹ́mírámótì àti Jéhíélì àti Únì àti Élíábù àti Maaseáyà àti Bẹnáyà pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín tí a yí sí Álámótì,+ 21  àti Matitáyà+ àti Élíféléhù àti Mikinéáyà àti Obedi-édómù àti Jéélì àti Asasáyà pẹ̀lú àwọn háàpù+ tí a yí sí Ṣẹ́mínítì,+ láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn olùdarí; 22  àti Kenanáyà+ olórí àwọn ọmọ Léfì nínú ẹrù rírù, òun a máa fúnni ní ìtọ́ni nínú ẹrù rírù, nítorí ó jẹ́ ògbógi;+ 23  àti Berekáyà àti Ẹlikénà àwọn aṣọ́bodè+ fún Àpótí; 24  àti Ṣebanáyà àti Jóṣáfátì àti Nétánélì àti Ámásáì àti Sekaráyà àti Bẹnáyà àti Élíésérì àlùfáà tí ń fun kàkàkí+ kíkankíkan níwájú àpótí Ọlọ́run tòótọ́, àti Obedi-édómù àti Jeháyà àwọn aṣọ́bodè fún Àpótí. 25  Dáfídì+ àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì+ àti àwọn olórí+ ẹgbẹẹgbẹ̀rún sì ni àwọn tí ó jọ ń rìn lọ láti gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà gòkè wá láti ilé Obedi-édómù+ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.+ 26  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ ran àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́+ bí wọ́n ti ń ru àpótí májẹ̀mú Jèhófà, wọ́n tẹ̀ síwájú láti fi ẹgbọrọ akọ màlúù méje àti àgbò méje rúbọ.+ 27  Dáfídì sì wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí a fi aṣọ híhun àtàtà ṣe, àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó ru Àpótí pẹ̀lú àti àwọn akọrin àti Kenanáyà+ olórí ẹ̀rù rírù lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn akọrin;+ ṣùgbọ́n éfódì+ aṣọ ọ̀gbọ̀ wà lára Dáfídì. 28  Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà gòkè bọ̀ pẹ̀lú igbe ìdùnnú+ àti pẹ̀lú ìró ìwo+ àti pẹ̀lú kàkàkí+ àti pẹ̀lú aro,+ tí wọ́n ń fi àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ kọrin sókè. 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àpótí májẹ̀mú+ Jèhófà ń bọ̀ títí dé Ìlú Ńlá Dáfídì, Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, bojú wolẹ̀ lójú fèrèsé, ó sì wá rí Dáfídì Ọba tí ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri, tí ó sì ń ṣe ayẹyẹ;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú+ rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé