Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 14:1-17

14  Hírámù+ ọba Tírè+ sì tẹ̀ síwájú láti rán àwọn ońṣẹ́ sí Dáfídì àti àwọn ẹ̀là gẹdú+ kédárì àti àwọn tí ń mọ ògiri àti àwọn oníṣẹ́ igi láti kọ́ ilé fún un.+  Dáfídì sì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí òun múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in+ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì, nítorí pé ipò ọba rẹ̀ ní a gbé ga fíofío ní tìtorí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.+  Dáfídì sì ń bá a lọ láti fẹ́ aya púpọ̀ sí i+ ní Jerúsálẹ́mù, Dáfídì sì wá bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i.+  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù: Ṣámúà+ àti Ṣóbábù,+ Nátánì+ àti Sólómọ́nì,+  àti Íbárì+ àti Élíṣúà àti Élípélétì,+  àti Nógà àti Néfégì+ àti Jáfíà,  àti Élíṣámà+ àti Béélíádà àti Élífélétì.+  Àwọn Filísínì sì wá gbọ́ pé a ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ Látàrí ìyẹn, gbogbo àwọn Filísínì gòkè wá láti wá Dáfídì.+ Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa rẹ̀, nígbà náà ni ó jáde lọ láti gbéjà kò wọ́n.  Àwọn Filísínì, ní tiwọn, sì wọlé wá, wọ́n sì ń gbé sùnmọ̀mí wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+ 10  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run,+ pé: “Ṣé kí n gòkè lọ gbéjà ko àwọn Filísínì, ìwọ yóò ha sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ dájúdájú?” Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún un pé: “Gòkè lọ, èmi yóò sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú.” 11  Nítorí náà, Dáfídì gòkè lọ sí Baali-pérásímù,+ ó sì ṣá wọn balẹ̀ níbẹ̀. Látàrí ìyẹn, Dáfídì wí pé: “Ọlọ́run tòótọ́ ti ya lu àwọn ọ̀tá mi nípa ọwọ́ mi bí àlàfo tí omi ṣe.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe orúkọ ibẹ̀+ ní Baali-pérásímù. 12  Nítorí náà, wọ́n fi àwọn ọlọ́run wọn sílẹ̀ níbẹ̀.+ Nígbà náà ni Dáfídì sọ̀rọ̀, nítorí náà, a sì fi iná sun wọ́n.+ 13  Lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì tún gbé sùnmọ̀mí wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ náà.+ 14  Látàrí ìyẹn, Dáfídì tún wádìí+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Ọlọ́run tòótọ́ sì sọ fún un wàyí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gòkè tọ̀ wọ́n lọ. Lọ yí ká láti má dojú kọ wọ́n ní tààràtà, kí o sì já lù wọ́n ní iwájú àwọn igi bákà.+ 15  Sì jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí o bá gbọ́ ìró ìrìn lórí àwọn igi bákà,+ nígbà náà ni kí o jáde lọ sínú ìjà náà,+ nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò ti jáde lọ ṣáájú rẹ+ láti ṣá ibùdó àwọn Filísínì balẹ̀.” 16  Nítorí náà, Dáfídì ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́ ti pàṣẹ fún un gan-an,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá ibùdó àwọn Filísínì balẹ̀ láti Gíbéónì+ dé Gésérì.+ 17  Òkìkí+ Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì fi ìbẹ̀rùbojo rẹ̀ sára gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé