Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 12:1-40

12  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Síkílágì+ nígbà tí ó ṣì wà lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò nítorí Sọ́ọ̀lù+ ọmọkùnrin Kíṣì; wọ́n sì wà lára àwọn ọkùnrin alágbára ńlá,+ àwọn olùrànlọ́wọ́ nínú ogun,  tí wọ́n fi ọrun dìhámọ́ra, àwọn tí ń lo ọwọ́ ọ̀tún tí wọ́n sì ń lo ọwọ́ òsì+ láti fi ta òkúta+ tàbí ọfà+ nínú ọrun.+ Wọ́n jẹ́ arákùnrin Sọ́ọ̀lù, ti Bẹ́ńjámínì.  Olórí ni Áhíésérì àti Jóáṣì àwọn ọmọkùnrin Ṣémáà ará Gíbíà,+ àti Jésíélì àti Pélétì àwọn ọmọkùnrin Ásímáfẹ́tì,+ àti Bérákà àti Jéhù ọmọ Ánátótì,+  àti Iṣimáyà ará Gíbéónì,+ ọkùnrin alágbára ńlá láàárín ọgbọ̀n+ àti lórí ọgbọ̀n; àti Jeremáyà àti Jahasíẹ́lì àti Jóhánánì àti Jósábádì ará Gédérà,+  Élúsáì àti Jérímótì àti Bealáyà àti Ṣemaráyà àti Ṣẹfatáyà ọmọ Hárífù,  Ẹlikénà àti Isiṣáyà àti Ásárẹ́lì àti Jóésà àti Jáṣóbéámù, àwọn ọmọ Kórà,+  àti Jóélà àti Sebadáyà àwọn ọmọkùnrin Jéróhámù ti Gédórì.  Àwọn kan sì wà lára àwọn ọmọ Gádì tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ sí ìhà ọ̀dọ̀ Dáfídì ní ibi tí ó ṣòro láti dé ní aginjù,+ àwọn akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin, àwọn ọkùnrin ẹgbẹ́ ọmọ ogun fún ogun, àwọn tí ń pèsè apata ńlá àti aṣóró sílẹ̀,+ àwọn tí ojú wọ́n jẹ́ ojú kìnnìún,+ wọ́n sì dà bí àgbàlàǹgbó lórí àwọn òkè ńlá ní ti ìyára kánkán.+  Ésérì ni olórí, Ọbadáyà ìkejì, Élíábù ìkẹta, 10  Míṣímánà ìkẹrin, Jeremáyà ìkarùn-ún, 11  Átáì ìkẹfà, Élíélì ìkeje, 12  Jóhánánì ìkẹjọ, Élísábádì ìkẹsàn-án, 13  Jeremáyà ìkẹwàá, Makibánáì ìkọkànlá. 14  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gádì,+ àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ẹni tí ó kéré jù lọ tó fún ọgọ́rùn-ún, ẹni tí ó tóbi jù lọ sì tó fún ẹgbẹ̀rún.+ 15  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó sọdá Jọ́dánì+ ní oṣù kìíní nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,+ nígbà náà ni wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó wà ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ lọ, níhà ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn. 16  Àwọn kan lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì àti Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí wá títí dé ibi tí ó ṣòro láti dé,+ sọ́dọ̀ Dáfídì. 17  Nígbà náà ni Dáfídì jáde lọ síwájú wọn, ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ àlàáfíà+ ni ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi láti ràn mí lọ́wọ́, ọkàn-àyà tèmi yóò di èyí tí ó ṣọ̀kan pẹ̀lú yín.+ Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ láti fi mí lé elénìní mi lọ́wọ́ nígbà tí kò sí àìtọ́ kankan ní àtẹ́lẹwọ́ mi,+ kí Ọlọ́run+ àwọn baba ńlá wa rí sí i kí ó sì mú un tọ́.”+ 18  Ẹ̀mí+ tìkára rẹ̀ sì bo Ámásáì, olórí àwọn ọgbọ̀n náà, ó wí pé: “Tìrẹ ni àwa, Dáfídì, ọ̀dọ̀ rẹ sì ni a wà,+ ìwọ ọmọkùnrin Jésè. Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, àti àlàáfíà fún ẹni tí ń ràn ọ́ lọ́wọ́, Nítorí Ọlọ́run rẹ ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”+ Nítorí náà, Dáfídì gbà wọ́n, ó sì fi wọ́n sára àwọn olórí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun.+ 19  Àwọn kan sì wà lára Mánásè tí ó ya lọ bá Dáfídì nígbà tí ó bá àwọn Filísínì+ wá láti dojú kọ Sọ́ọ̀lù nínú ìjà ogun; ṣùgbọ́n òun kò ràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí lórí ìmọ̀ràn, àwọn olúwa+ alájùmọ̀ṣepọ̀ ti àwọn Filísínì rán an lọ, pé: “Fífi orí tiwa wewu ni òun yóò fi sá lọ bá olúwa rẹ̀ Sọ́ọ̀lù.”+ 20  Nígbà tí ó dé Síkílágì,+ Ádínáhì àti Jósábádì àti Jédáélì àti Máíkẹ́lì àti Jósábádì àti Élíhù àti Sílétáì láti inú Mánásè ya lọ bá a, àwọn olórí+ ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí ó jẹ́ ti Mánásè. 21  Àwọn, ní tiwọn, sì jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún Dáfídì ní ìdojú-ìjà-kọ ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí,+ nítorí gbogbo wọ́n jẹ́ ògbójú ọkùnrin alágbára ńlá,+ wọ́n sì wá jẹ́ olórí nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun; 22  nítorí ní ọjọ́ dé ọjọ́, àwọn ènìyàn ń wá ṣáá+ sọ́dọ̀ Dáfídì láti ràn án lọ́wọ́, títí ó fi di ibùdó ńlá,+ bí ibùdó Ọlọ́run.+ 23  Ìwọ̀nyí sì ni iye olórí àwọn tí a mú gbára dì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì+ láti fi ipò ọba+ Sọ́ọ̀lù lé e lọ́wọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà.+ 24  Àwọn ọmọ Júdà tí ń gbé apata ńlá àti aṣóró jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n, àwọn tí a mú gbára dì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 25  Lára àwọn ọmọ Síméónì, àwọn ògbójú ọkùnrin alágbára ńlá nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìndínlógójì. 26  Lára àwọn ọmọ Léfì, ẹgbẹ̀tàlélógún. 27  Jèhóádà sì ni aṣáájú+ àwọn ọmọ Áárónì,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbọ̀kàndínlógún sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 28  Àti Sádókù+ ọ̀dọ́kùnrin kan, ògbójú alágbára ńlá, àti ní ilé àwọn baba ńlá rẹ̀, olórí méjìlélógún. 29  Lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ àwọn arákùnrin Sọ́ọ̀lù,+ ẹgbẹ̀ẹ́dógún sì ń bẹ, títí di ìgbà yẹn iye tí ó pọ̀ jù nínú wọ́n sì ń ṣọ́ ilé Sọ́ọ̀lù lójú méjèèjì. 30  Lára àwọn ọmọ Éfúráímù, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀rin sì ń bẹ, àwọn ògbójú ọkùnrin alágbára ńlá,+ àwọn ọkùnrin olókìkí, ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá wọn. 31  Lára ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè,+ ẹgbàásàn-án sì ń bẹ tí a yàn sọ́tọ̀ nípa orúkọ pé kí wọ́n wá fi Dáfídì jẹ ọba. 32  Lára àwọn ọmọ Ísákárì+ tí ó ní ìmọ̀ bí a ṣe ń fi òye mọ àwọn àkókò+ láti mọ ohun tí ó yẹ kí Ísírẹ́lì ṣe,+ igba àwọn olórí wọ́n sì ń bẹ, gbogbo àwọn arákùnrin wọ́n sì wà lábẹ́ àṣẹ ìtọ́ni wọn. 33  Lára Sébúlúnì,+ àwọn tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àwọn tí ń fi gbogbo àwọn ohun ìjà ogun tẹ́ ìtẹ́gun, ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sì ń bẹ, àti ní ti bíbá Dáfídì kẹ́gbẹ́ rìn, wọn kò ní ọkàn-àyà méjì. 34  Lára Náfútálì,+ ẹgbẹ̀rún olórí sì ń bẹ, pẹ̀lú wọn sì ni ẹgbàá méjìdínlógún ó lé ẹgbẹ̀rún pẹ̀lú apata ńlá àti ọ̀kọ̀. 35  Lára àwọn ọmọ Dánì, àwọn tí ń tẹ́ ìtẹ́gun sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé ẹgbẹ̀ta. 36  Lára Áṣérì,+ àwọn tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun fún títẹ́ ìtẹ́gun sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì. 37  Láti òdì-kejì Jọ́dánì+ lára àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun ìjà ẹgbẹ́ ológun, ọ̀kẹ́ mẹ́fà sì ń bẹ. 38  Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọkùnrin ogun, àwọn tí ń kẹ́gbẹ́ rìn nínú ìlà ogun; ọkàn-àyà pípé pérépéré+ ni wọ́n fi wá sí Hébúrónì láti fi Dáfídì jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì; pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo ìyókù Ísírẹ́lì ní ọkàn-àyà kan náà ní ti fífi Dáfídì jẹ ọba.+ 39  Wọ́n sì ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì fún ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu,+ nítorí àwọn arákùnrin wọ́n ti pèsè sílẹ̀ fún wọn. 40  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí ó wà nítòsí wọn, títí kan Ísákárì+ àti Sébúlúnì+ àti Náfútálì,+ ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ àti ràkúnmí àti ìbaaka àti màlúù gbé oúnjẹ wá, àwọn ohun jíjẹ tí a fi ìyẹ̀fun ṣe,+ ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́+ àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ+ àti wáìnì+ àti òróró+ àti màlúù+ àti àgùntàn+ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, nítorí pé ayọ̀ yíyọ̀+ wà ní Ísírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé