Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 11:1-47

11  Nígbà tí ó ṣe, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì,+ wọ́n wí pé: “Wò ó! Egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa jẹ́.+  Àti ní àná àti tẹ́lẹ̀ rí, àní nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba, ìwọ ni ẹni tí ń mú Ísírẹ́lì jáde, tí ó sì ń mú un wọlé;+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, ìwọ sì ni yóò di aṣáájú+ lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.’”  Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú ní Hébúrónì níwájú Jèhófà; lẹ́yìn èyí tí wọ́n fòróró yan+ Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀+ Jèhófà nípasẹ̀ Sámúẹ́lì.+  Lẹ́yìn náà, Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Jerúsálẹ́mù,+ èyíinì ni, Jébúsì,+ níbi tí àwọn ará Jébúsì+ ti jẹ́ olùgbé ilẹ̀ náà.  Àwọn olùgbé Jébúsì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ kì yóò wọ ìhín.”+ Síbẹ̀síbẹ̀, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti gba ibi odi agbára Síónì,+ èyíinì ni, Ìlú Ńlá Dáfídì.+  Nítorí náà, Dáfídì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kọlu+ àwọn ará Jébúsì, òun ni yóò di olórí àti ọmọ aládé.” Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà sì ni ó kọ́kọ́ gòkè lọ, ó sì wá di olórí.  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ibi tí ó ṣòro láti dé.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pè é ní Ìlú Ńlá Dáfídì.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ìlú ńlá náà yíká-yíká, láti Òkìtì àní dé àwọn apá tí wọ́n wà yí ká, ṣùgbọ́n Jóábù fúnra rẹ̀ ni ó mú ìyókù ìlú ńlá náà kún fún ìgbòkègbodò.+  Dáfídì sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá,+ nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 10  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni olórí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá+ tí ó jẹ́ ti Dáfídì, tí wọ́n dúró tì í gbágbá nínú ipò ọba rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, láti fi í jẹ ọba ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà+ nípa Ísírẹ́lì. 11  Èyí sì ni àkójọ orúkọ àwọn ọkùnrin alágbára ńlá tí ó jẹ́ ti Dáfídì: Jáṣóbéámù+ ọmọkùnrin ẹnì kan tí í ṣe ọmọ Hákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà. Ó ń ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ fìrìfìrì lórí ọ̀ọ́dúnrún tí a pa lẹ́ẹ̀kan náà.+ 12  Àti lẹ́yìn rẹ̀ ni Élíásárì+ ọmọkùnrin Dódò ọmọ Áhóhì.+ Ó wà lára àwọn alágbára ńlá mẹ́ta náà.+ 13  Òun ni ó wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pasi-dámímù,+ níbi tí àwọn Filísínì ti kó ara wọn jọpọ̀ sí fún ogun. Wàyí o, abá pápá kan wà tí ó kún fún ọkà bálì, àwọn ènìyàn náà, ní tiwọn, sì ti sá lọ nítorí àwọn Filísínì.+ 14  Ṣùgbọ́n ó mú ìdúró rẹ̀ ní àárín abá náà, ó sì dá a nídè, ó sì ń ṣá àwọn Filísínì balẹ̀ nìṣó, tí ó fi jẹ́ pé Jèhófà fi ìgbàlà ńlá+ gbà wọ́n là.+ 15  Mẹ́ta lára àwọn ọgbọ̀n+ olórí sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi àpáta, sọ́dọ̀ Dáfídì ní hòrò Ádúlámù,+ nígbà tí ibùdó àwọn Filísínì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+ 16  Nígbà yẹn, Dáfídì sì wà ní ibi tí ó nira láti dé;+ ẹgbẹ́ ogun Filísínì+ sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà yẹn. 17  Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Dáfídì fi ìfàsí-ọkàn rẹ̀ hàn, ó sì wí pé: “Ì bá ṣe pé mo lè rí omi mu+ láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ èyí tí ó wà ní ẹnubodè!” 18  Látàrí ìyẹn, àwọn mẹ́ta náà fi ipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n sì fa omi láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, èyí tí ó wà ní ẹnubodè, wọ́n sì ń gbé e bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dáfídì.+ Dáfídì kò sì gbà láti mu ún, ṣùgbọ́n ó dà á jáde fún Jèhófà.+ 19  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ti Ọlọ́run mi, láti ṣe èyí! Ṣé ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni kí n mu ní fífi ọkàn wọn wewu? Nítorí ní fífi ọkàn wọn wewu ni wọ́n fi gbé e wá.” Kò sì gbà láti mu ún.+ Ìwọ̀nyí ni ohun tí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà ṣe. 20  Ní ti Ábíṣáì+ arákùnrin Jóábù,+ òun fúnra rẹ̀ di olórí àwọn mẹ́ta; ó sì ń ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ fìrìfìrì lórí ọ̀ọ́dúnrún tí a pa, ó sì ní ìfùsì bí àwọn mẹ́ta náà. 21  Lára àwọn mẹ́ta náà, ó jẹ́ ẹni sàràkí ju àwọn méjì yòókù, ó sì wá jẹ́ olórí wọn; síbẹ̀síbẹ̀, kò tó+ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́. 22  Ní ti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà,+ ọmọ akíkanjú kan, ẹni tí ó ṣe ohun púpọ̀ ní Kábúséélì,+ òun fúnra rẹ̀ ni ó ṣá àwọn ọmọkùnrin méjì ti Áríélì ará Móábù balẹ̀; òun fúnra rẹ̀ sì ni ó sọ̀ kalẹ̀ tí ó sì ṣá kìnnìún+ kan balẹ̀ nínú kòtò omi kan ní ọjọ́ tí ìrì dídì ń sẹ̀. 23  Òun sì ni ó ṣá ọkùnrin ará Íjíbítì náà balẹ̀, ọkùnrin kan tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+ Ọ̀kọ̀+ kan tí ó dà bí ìtì igi àwọn olófì sì wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà; síbẹ̀ ó sọ̀ kalẹ̀ lọ bá a pẹ̀lú ọ̀pá, ó sì já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+ 24  Nǹkan wọ̀nyí ni Bẹnáyà ọmọkùnrin Jèhóádà ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà. 25  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ẹni sàràkí ju ọgbọ̀n náà, síbẹ̀ kò wọ+ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì fi í sórí ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.+ 26  Ní ti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá ti ẹgbẹ́ ológun, àwọn ni Ásáhélì+ arákùnrin Jóábù, Élíhánánì+ ọmọkùnrin Dódò ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, 27  Ṣámótì+ ará Hárórù, Hélésì tí í ṣe Pélónì,+ 28  Írà+ ọmọkùnrin Íkéṣì ará Tékóà, Abi-ésérì ọmọ Ánátótì,+ 29  Síbékáì+ ọmọ Húṣà, Íláì ọmọ Áhóhì,+ 30  Máháráì+ ará Nétófà,+ Hélédì+ ọmọkùnrin Báánáhì ará Nétófà, 31  Ítáì ọmọkùnrin Ríbáì+ ti Gíbíà+ ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ Bẹnáyà ará Pírátónì,+ 32  Húráì láti àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Gááṣì,+ Ábíélì tí í ṣe Ábátì, 33  Ásímáfẹ́tì ará Báhúrímù,+ Élíábà tí í ṣe Ṣáálíbónì, 34  àwọn ọmọ Háṣémù tí í ṣe Gísónì, Jónátánì+ ọmọkùnrin Ṣágéè tí í ṣe Hárárì, 35  Áhíámù ọmọkùnrin Sákárì+ tí í ṣe Hárárì, Élífálì+ ọmọkùnrin Úrì, 36  Héfà ọmọ Mékérà, Áhíjà tí í ṣe Pélónì, 37  Hésírò ará Kámẹ́lì,+ Nááráì ọmọkùnrin Ésíbáì, 38  Jóẹ́lì arákùnrin Nátánì,+ Míbúhárì ọmọkùnrin Hágírì, 39  Sélékì ọmọ Ámónì, Náháráì ará Bérótì, arùhámọ́ra Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà, 40  Írà tí í ṣe Ítírì, Gárébù+ tí í ṣe Ítírì, 41  Ùráyà+ ọmọ Hétì,+ Sábádì ọmọkùnrin Áláì, 42  Ádínà ọmọkùnrin Ṣísà ọmọ Rúbẹ́nì, ọ̀kan lára olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, ẹni tí ọgbọ̀n ènìyàn wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; 43  Hánánì ọmọkùnrin Máákà, àti Jóṣáfátì tí í ṣe Mítínì, 44  Úsíà ará Áṣítárótì, Ṣámà àti Jéélì, àwọn ọmọkùnrin Hótámù ará Áróérì, 45  Jédáélì ọmọkùnrin Ṣímúrì, àti Jóhà arákùnrin rẹ̀ tí í ṣe Tísì, 46  Élíélì tí í ṣe Máháfì, àti Jéríbáì àti Joṣafáyà àwọn ọmọkùnrin Élínáámù, àti Ítímà ọmọ Móábù. 47  Élíélì àti Óbédì àti Jáásíélì ará Sóbà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé