Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 10:1-14

10  Àwọn Filísínì,+ ní tiwọn, sì bá Ísírẹ́lì jagun; àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì ń sá lọ kúrò níwájú àwọn Filísínì, wọ́n sì ń ṣubú sílẹ̀ ní òkú ní Òkè Ńlá Gíbóà.+  Àwọn Filísínì sì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí; àwọn Filísínì sì ṣá Jónátánì+ àti Ábínádábù+ àti Maliki-ṣúà,+ àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù+ balẹ̀.  Ìjà náà sì le kú fún Sọ́ọ̀lù; níkẹyìn, ọwọ́ àwọn tí ń ta ọrun sì bà á, ó sì gbọgbẹ́ láti ọwọ́ àwọn ọ̀tafà.+  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún arùhámọ́ra+ rẹ̀ pé: “Fa idà rẹ yọ+ kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́+ wọ̀nyí má bàa wá hùwà ìkà+ sí mi dájúdájú.” Arùhámọ́ra rẹ̀ kò sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀,+ nítorí tí àyà fò ó gidigidi. Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà náà, ó sì ṣubú lé e.+  Nígbà tí arùhámọ́ra rẹ̀ rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú, nígbà náà ni òun pẹ̀lú ṣubú lé idà, ó sì kú.+  Bí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta ṣe kú nìyẹn,+ gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ sì kú pa pọ̀.  Nígbà tí gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ rí i pé wọ́n ti sá lọ àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ìlú ńlá wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ;+ lẹ́yìn èyí tí àwọn Filísínì wọlé wá tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú wọn.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára+ àwọn tí a pa, wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ṣubú sórí Òkè Ńlá Gíbóà.+  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára rẹ̀, wọ́n sì mú orí+ rẹ̀ kúrò àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ sí ilẹ̀ àwọn Filísínì tí ó wà ní gbogbo àyíká pé kí wọ́n sọ+ fún àwọn òrìṣà+ wọn àti àwọn ènìyàn náà. 10  Níkẹyìn, wọ́n fi ìhámọ́ra rẹ̀ sínú ilé ọlọ́run wọn,+ wọ́n sì de agbárí rẹ̀ mọ́ ilé Dágónì.+ 11  Gbogbo àwọn ará Jábẹ́ṣì+ ní Gílíádì sì wá gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù.+ 12  Nítorí náà, gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin dìde, wọ́n sì gbé òkú Sọ́ọ̀lù lọ àti òkú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì gbé wọn wá sí Jábẹ́ṣì, wọ́n sì sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá+ ní Jábẹ́ṣì;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbààwẹ̀+ fún ọjọ́ méje. 13  Bí Sọ́ọ̀lù ṣe kú nìyẹn nítorí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ èyí tí ó fi hùwà lọ́nà àìnígbàgbọ́+ sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà tí kò pa mọ́ àti pẹ̀lú fún bíbéèrè lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ pé kí ó ṣe ìwádìí. 14  Kò sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Nítorí náà ni ó ṣe fi ikú pa á, tí ó sì fi ipò ọba lé Dáfídì ọmọkùnrin Jésè lọ́wọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé