Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Jòhánù 4:1-21

4  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí+ gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.+  Ẹ jèrè ìmọ̀ nípa àgbéjáde onímìísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ nípa èyí: Gbogbo àgbéjáde onímìísí tí ó bá jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+  ṣùgbọ́n gbogbo àgbéjáde onímìísí tí kò bá jẹ́wọ́ Jésù kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Síwájú sí i, èyí ni àgbéjáde onímìísí ti aṣòdì sí Kristi èyí tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀,+ nísinsìnyí ó ti wà ní ayé ná.+  Ẹ pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ sì ti ṣẹ́gun àwọn ènìyàn wọnnì,+ nítorí ẹni tí ó wà ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú yín tóbi ju+ ẹni tí ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ayé.+  Wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé;+ ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ohun tí ó jáde wá láti ọ̀dọ̀ ayé, ayé sì ń fetí sí wọn.+  Àwa pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Ẹni tí ó bá jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ń fetí sí wa;+ ẹni tí kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í fetí sí wa.+ Báyìí ni a ṣe fiyè sí àgbéjáde onímìísí ti òtítọ́ àti àgbéjáde onímìísí ti ìṣìnà.+  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,+ nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́+ ti wá, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì nífẹ̀ẹ́ ni a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ ó sì jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.+  Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.+  Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa,+ nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo+ jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.+ 10  Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ+ ìpẹ̀tù+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ 11  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.+ 12  Kò tíì sí ìgbà kan rí tí ẹnikẹ́ni rí Ọlọ́run.+ Bí a bá ń bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, Ọlọ́run dúró nínú wa, ìfẹ́ rẹ̀ ni a sì sọ di pípé nínú wa.+ 13  Nípa èyí ni àwa jèrè ìmọ̀ pé a dúró ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀ àti òun ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa,+ nítorí ó ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú wa.+ 14  Ní àfikún, àwa fúnra wa ti rí,+ a sì ń jẹ́rìí+ pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ayé.+ 15  Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jésù Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run,+ Ọlọ́run dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ àti òun ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.+ 16  Àwa fúnra wa sì ti wá mọ̀, a sì ti gba ìfẹ́+ tí Ọlọ́run ní nínú ọ̀ràn tiwa gbọ́. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,+ ẹni tí ó bá sì dúró nínú ìfẹ́+ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dúró ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀. 17  Báyìí ni a ṣe sọ ìfẹ́ di pípé lọ́dọ̀ wa, kí a lè ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ+ ní ọjọ́ ìdájọ́,+ nítorí pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn ti jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwa fúnra wa jẹ́ nínú ayé yìí.+ 18  Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́,+ ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde,+ nítorí ìbẹ̀rù a máa ṣèdíwọ́ fúnni. Ní tòótọ́, ẹni tí ó bá wà lábẹ́ ìbẹ̀rù ni a kò tíì sọ di pípé nínú ìfẹ́.+ 19  Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.+ 20  Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,” síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni.+ Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀,+ tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.+ 21  Àṣẹ yìí ni a sì gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ pé ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní láti máa nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé