Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Jòhánù 3:1-24

3  Ẹ wo irú ìfẹ́+ tí Baba ti fi fún wa, kí a lè pè wá ní ọmọ Ọlọ́run;+ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa jẹ́. Ìdí nìyẹn tí ayé+ kò fi ní ìmọ̀ nípa wa, nítorí kò tíì wá mọ̀ ọ́n.+  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nísinsìnyí ọmọ Ọlọ́run ni wá,+ ṣùgbọ́n síbẹ̀ a kò tíì fi hàn kedere ohun tí àwa yóò jẹ́.+ A mọ̀ pé nígbàkigbà tí a bá fi í hàn kedere+ a ó dà bí rẹ̀,+ nítorí a óò rí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí.+  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ní ìrètí yìí tí a fi sórí rẹ̀, a wẹ ara rẹ̀ mọ́ gaara+ gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn ti mọ́ gaara.+  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń sọ ẹ̀ṣẹ̀+ dídá dàṣà ń sọ ìwà àìlófin+ dàṣà pẹ̀lú, nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀+ jẹ́ ìwà àìlófin.  Ẹ mọ̀ pẹ̀lú pé ẹni yẹn ni a fi hàn kedere láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò,+ kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀+ kankan nínú rẹ̀.  Olúkúlùkù ẹni tí ó dúró ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀ kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà;+ kò sí ẹni tí ó sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà tí ó ti rí i tàbí tí ó ti wá mọ̀ ọ́n.+  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà; ẹni tí ń bá a lọ ní ṣíṣe òdodo jẹ́ olódodo, gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn ti jẹ́ olódodo.+  Ẹni tí ń bá a lọ ní dídá ẹ̀ṣẹ̀ pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èṣù, nítorí Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.+ Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere,+ èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.+  Olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í bá a lọ ní dídá ẹ̀ṣẹ̀,+ nítorí irú-ọmọ Rẹ̀ ṣì wà nínú irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, kò sì lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti bí i.+ 10  Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo+ kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀.+ 11  Nítorí èyí ni ìhìn iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,+ pé a ní láti ní ìfẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì;+ 12  kì í ṣe bí Kéènì, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa+ arákùnrin rẹ̀. Nítorí kí ni ó sì ṣe fikú pa á? Nítorí pé àwọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú,+ ṣùgbọ́n àwọn ti arákùnrin rẹ̀ jẹ́ òdodo.+ 13  Kí ẹnu má yà yín, ẹ̀yin ará, pé ayé kórìíra yín.+ 14  Àwa mọ̀ pé a ti ré kọjá láti inú ikú sí ìyè,+ nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará.+ Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ dúró nínú ikú.+ 15  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra+ arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn,+ ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn+ kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.+ 16  Nípa èyí ni àwa fi wá mọ ìfẹ́,+ nítorí ẹni yẹn fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa;+ a sì wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi ọkàn wa lélẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa.+ 17  Ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé,+ tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní,+ síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn,+ lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀?+ 18  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́,+ kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n,+ bí kò ṣe ní ìṣe+ àti òtítọ́.+ 19  Nípa èyí ni àwa yóò mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́,+ a ó sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ 20  ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi,+ nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.+ 21  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ọkàn-àyà wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run;+ 22  ohun yòówù tí a bá sì béèrè ni a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ nítorí a ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.+ 23  Ní tòótọ́, èyí ni àṣẹ rẹ̀, pé kí a ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi,+ kí a sì máa nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pa àṣẹ fún wa. 24  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti òun ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀;+ nípa èyí ni àwa sì jèrè ìmọ̀ náà pé ó dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa,+ ní tìtorí ẹ̀mí+ tí ó fi fún wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé