Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Jòhánù 2:1-29

2  Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mo ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín kí ẹ má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀.+ Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́+ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo.+  Òun sì ni ẹbọ+ ìpẹ̀tù+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa+ nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.+  Nípa èyí ni àwa sì ní ìmọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, èyíinì ni, bí a bá ń bá a lọ ní pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+  Ẹni tí ó bá wí pé: “Mo ti wá mọ̀ ọ́n,”+ síbẹ̀ tí kì í pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ òpùrọ́ ni, òtítọ́ kò sì sí nínú ẹni yìí.+  Ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́,+ lótìítọ́ nínú ẹni yìí ni a ti sọ ìfẹ́ fún Ọlọ́run di pípé.+ Nípasẹ̀ èyí ni a ní ìmọ̀ pé a wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+  Ẹni tí ó bá sọ pé òun dúró ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀ wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe pẹ̀lú láti máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn ti rìn.+  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo ń kọ̀wé sí yín, kì í ṣe àṣẹ tuntun, bí kò ṣe àṣẹ ti láéláé,+ èyí tí ẹ ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.+ Àṣẹ ti láéláé yìí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ gbọ́.  Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo ń kọ̀wé àṣẹ tuntun sí yín, òtítọ́ tí ó jẹ́ òótọ́ nínú ọ̀ràn tirẹ̀ àti nínú tiyín, nítorí òkùnkùn+ ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀+ tòótọ́ sì ti wà ní títàn báyìí.  Ẹni tí ó bá sọ pé òun wà nínú ìmọ́lẹ̀, síbẹ̀ tí ó kórìíra+ arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn títí di ìsinsìnyí gan-an.+ 10  Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ dúró nínú ìmọ́lẹ̀,+ kò sì sí okùnfà kankan fún ìkọ̀sẹ̀ nínú ọ̀ràn tirẹ̀.+ 11  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn,+ ó sì ń rìn nínú òkùnkùn, kò sì mọ ibi tí òun ń lọ,+ nítorí òkùnkùn ti fọ́ ọ lójú. 12  Mo ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, nítorí a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.+ 13  Mo ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí ẹ ti wá mọ ẹni tí ó wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.+ Mo ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin,+ nítorí ẹ ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.+ Mo kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọdé,+ nítorí ẹ ti wá mọ Baba.+ 14  Mo kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,+ nítorí ẹ ti wá mọ ẹni tí ó wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.+ Mo kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, nítorí ẹ jẹ́ alágbára+ àti pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró nínú yín,+ ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.+ 15  Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.+ Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀;+ 16  nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé+—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara+ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú+ àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími+—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.+ 17  Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́+ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.+ 18  Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọdé, wákàtí ìkẹyìn nìyí,+ àti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀,+ nísinsìnyí pàápàá ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi+ ni ó ti wà; láti inú òtítọ́ tí àwa ti jèrè ìmọ̀ pé wákàtí ìkẹyìn nìyí. 19  Wọ́n jáde lọ láti ọ̀dọ̀ wa, ṣùgbọ́n wọn kò sí ní ìsọ̀wọ́ wa;+ nítorí ká ní wọ́n wà ní ìsọ̀wọ́ wa ni, wọn ì bá dúró pẹ̀lú wa.+ Ṣùgbọ́n wọ́n jáde lọ kí a lè fi í hàn pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó wà ní ìsọ̀wọ́ wa.+ 20  Ẹ sì ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́ náà;+ gbogbo yín ní ìmọ̀.+ 21  Mo kọ̀wé sí yín, kì í ṣe nítorí pé ẹ kò mọ òtítọ́,+ ṣùgbọ́n nítorí pé ẹ mọ̀ ọ́n,+ àti nítorí pé irọ́ kankan kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́.+ 22  Ta ni òpùrọ́ bí kì í bá ṣe ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù ni Kristi?+ Èyí ni aṣòdì sí Kristi,+ ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ.+ 23  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sẹ́ Ọmọ kò ní Baba pẹ̀lú.+ Ẹni tí ó bá jẹ́wọ́+ Ọmọ ní Baba pẹ̀lú.+ 24  Ní tiyín, kí èyíinì tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ dúró nínú yín.+ Bí èyíinì tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ bá dúró nínú yín, ẹ̀yin pẹ̀lú yóò wà ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Ọmọ àti ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba.+ 25  Síwájú sí i, èyí ni ohun ìlérí tí òun fúnra rẹ̀ ṣèlérí fún wa, ìyè àìnípẹ̀kun.+ 26  Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé sí yín nípa àwọn tí ń gbìyànjú láti ṣì yín lọ́nà.+ 27  Àti ní tiyín, ìfòróróyàn+ tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ dúró nínú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ́ yín;+ ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìfòróróyàn náà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti ń kọ́ yín nípa ohun gbogbo,+ tí ó sì jẹ́ òótọ́,+ tí kì í sì í ṣe irọ́, àti pé gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ yín, ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀. 28  Nítorí náà, nísinsìnyí, ẹ̀yin ọmọ kéékèèké,+ ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀, kí a lè ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ+ nígbà tí a bá fi í hàn kedere,+ kí ojú má sì tì wá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.+ 29  Bí ẹ bá mọ̀ pé òun jẹ́ olódodo,+ ẹ jèrè ìmọ̀ náà pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń fi òdodo ṣe ìwà hù ni a ti bí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé