Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 9:1-28

9  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sólómọ́nì ti parí kíkọ́ ilé+ Jèhófà àti ilé ọba+ àti gbogbo ohun tí Sólómọ́nì ní ìfẹ́-ọkàn sí, tí ó ní inú dídùn sí láti ṣe,+  nígbà náà ni Jèhófà fara han Sólómọ́nì nígbà kejì, gan-an bí ó ṣe fara hàn án ní Gíbéónì.+  Jèhófà sì ń bá a lọ ní wíwí fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ+ àti ìbéèrè rẹ fún ojú rere, èyí tí o fi béèrè fún ojú rere níwájú mi. Mo ti sọ ilé yìí tí o kọ́ di mímọ́+ nípa fífi orúkọ+ mi síbẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin; dájúdájú, ojú mi+ àti ọkàn-àyà mi yóò sì wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.+  Àti ìwọ, bí ìwọ yóò bá rìn+ níwájú mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì+ baba rẹ ti rìn, pẹ̀lú ìwà títọ́+ ọkàn-àyà àti pẹ̀lú ìdúróṣánṣán+ nípa ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ,+ tí ìwọ yóò sì pa àwọn ìlànà+ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ mi mọ́,  èmi pẹ̀lú yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì ní tòótọ́, fún àkókò tí ó lọ kánrin, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dáfídì baba rẹ pé, ‘Kò sí ọkùnrin rẹ kan tí a óò ké kúrò láti máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+  Bí ẹ̀yin alára àti àwọn ọmọ yín bá lọ yí padà dájúdájú, kúrò nínú títọ̀ mí lẹ́yìn,+ tí ẹ kò sí pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi tí mo fi síwájú yín mọ́, tí ẹ sì lọ sin àwọn ọlọ́run+ mìíràn ní ti tòótọ́, tí ẹ sì tẹrí ba fún wọn,  ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò ké Ísírẹ́lì kúrò ní orí ilẹ̀ tí mo ti fi fún wọn;+ àti ilé tí mo ti sọ di mímọ́ fún orúkọ mi ni èmi yóò gbé sọnù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ọ̀rọ̀ òwe+ àti ìṣáátá ní tòótọ́ láàárín gbogbo ènìyàn.  Ilé yìí gan-an yóò sì di òkìtì àwókù.+ Gbogbo ẹni tí ó bá gba ibẹ̀ kọjá yóò wò sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì,+ yóò sì súfèé dájúdájú, yóò sì wí pé, ‘Nítorí ìdí wo ni Jèhófà fi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+  Dájúdájú, wọn yóò sì sọ pé, ‘Nítorí ìdí náà pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí di àwọn ọlọ́run mìíràn mú,+ wọ́n sì tẹrí ba fún wọn, wọ́n sì sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo ìyọnu àjálù+ yìí wá sórí wọn.’” 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin ogún ọdún, nínú èyí tí Sólómọ́nì kọ́ ilé méjèèjì, ilé Jèhófà+ àti ilé ọba,+ 11  (Hírámù+ ọba Tírè alára ti fi àwọn ẹ̀là gẹdú igi kédárì àti àwọn ẹ̀là gẹdú igi júnípà àti wúrà ṣèrànwọ́ fún Sólómọ́nì,+ ní ìwọn bí ó ti ní inú dídùn tó,)+ pé, ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì Ọba tẹ̀ síwájú láti fún Hírámù ní ogún ìlú ńlá ní ilẹ̀ Gálílì.+ 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Hírámù jáde lọ láti Tírè láti wo àwọn ìlú ńlá tí Sólómọ́nì ti fi fún un, wọn kò sì tọ́ rárá ní ojú rẹ̀.+ 13  Nítorí náà, ó wí pé: “Irú àwọn ìlú ńlá wo nìwọ̀nyí tí o fi fún mi, arákùnrin mi?” A sì wá ń pè wọ́n ní Ilẹ̀ Kábúlù títí di òní yìí. 14  Láàárín àkókò yìí, Hírámù fi ọgọ́fà tálẹ́ńtì wúrà+ ránṣẹ́ sí ọba. 15  Wàyí o, èyí ni ìròyìn nípa àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe+ tí Sólómọ́nì Ọba fi àṣẹ gbé iṣẹ́ fún láti kọ́ ilé Jèhófà+ àti ilé tirẹ̀ àti Òkìtì+ àti ògiri+ Jerúsálẹ́mù àti Hásórì+ àti Mẹ́gídò+ àti Gésérì.+ 16  (Fáráò ọba Íjíbítì alára gòkè wá, ó sì gba Gésérì nígbà náà, ó sì fi iná sun ún, àwọn ọmọ Kénáánì+ tí ń gbé ìlú ńlá náà ni ó pa. Nítorí náà, ó fi í fún ọmọbìnrin rẹ̀,+ aya Sólómọ́nì, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ìdágbére.) 17  Sólómọ́nì sì ń bá a lọ láti kọ́ Gésérì àti Bẹti-hórónì+ Ìsàlẹ̀, 18  àti Báálátì+ àti Támárì ní aginjù, ní ilẹ̀ náà, 19  àti gbogbo ìlú ńlá ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí+ tí ó di ti Sólómọ́nì àti àwọn ìlú ńlá+ kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ìlú ńlá fún àwọn ẹlẹ́ṣin, àti àwọn ohun tí Sólómọ́nì fẹ́,+ èyí tí ó fẹ́ láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù àti sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀. 20  Ní ti gbogbo ènìyàn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn Hífì+ àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ 21  àwọn ọmọ wọn tí ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn wọn ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè yà sọ́tọ̀ fún ìparun,+ Sólómọ́nì ń bá a nìṣó láti fi àṣẹ gbé iṣẹ́ fún wọn fún òpò àfipámúniṣe lọ́nà ìsìnrú títí di òní yìí.+ 22  Kò sì sí ìkankan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Sólómọ́nì sọ di ẹrú;+ nítorí àwọn ni jagunjagun àti ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun àti olórí àwọn oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.+ 23  Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn ajẹ́lẹ̀ tí ó wà lórí iṣẹ́ Sólómọ́nì, àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta, àwọn òléwájú àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́+ náà. 24  Bí ó ti wù kí ó rí, ọmọbìnrin Fáráò+ alára gòkè wá láti Ìlú Ńlá Dáfídì+ sí ilé tirẹ̀ tí ó kọ́ fún un. Nígbà náà ni ó mọ Òkìtì.+ 25  Sólómọ́nì sì ń bá a lọ láti rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ ní ìgbà mẹ́ta+ lọ́dún lórí pẹpẹ tí ó mọ fún Jèhófà,+ a sì ń rú èéfín ẹbọ lórí pẹpẹ+ náà, tí ó wà níwájú Jèhófà; ó sì parí ilé+ náà. 26  Sólómọ́nì Ọba sì ṣe ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ní Esioni-gébérì,+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Élótì,+ tí ń bẹ lórí èbúté Òkun Pupa ní ilẹ̀ Édómù.+ 27  Hírámù sì ń bá a nìṣó ní rírán àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀,+ àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun, tí ó ní ìmọ̀ nípa òkun, sínú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun náà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì. 28  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó okòó-lé-nírínwó tálẹ́ńtì wúrà+ láti ibẹ̀, wọ́n sì kó o wá fún Sólómọ́nì Ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé