Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 8:1-66

8  Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì+ tẹ̀ síwájú láti pe àwọn àgbà+ ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ,+ gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà,+ àwọn ìjòyè ti àwọn baba,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Sólómọ́nì Ọba ní Jerúsálẹ́mù, láti gbé àpótí májẹ̀mú+ Jèhófà gòkè wá láti Ìlú Ńlá Dáfídì,+ èyíinì ni, Síónì.+  Nítorí náà, gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì péjọ pọ̀ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì Ọba ní oṣù òṣùpá náà, Étánímù, nínú àjọyọ̀,+ èyíinì ni, oṣù keje.+  Nítorí náà, gbogbo àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì wá, àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru+ Àpótí+ náà.  Wọ́n sì ń gbé àpótí Jèhófà gòkè bọ̀ àti àgọ́+ ìpàdé+ àti gbogbo nǹkan èlò mímọ́ tí ń bẹ nínú àgọ́; àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì+ sì ń gbé wọn gòkè bọ̀.+  Sólómọ́nì Ọba àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí wọ́n pa àdéhùn wọn mọ́ pẹ̀lú rẹ̀, sì wà níwájú Àpótí, wọ́n ń fi àgùntàn àti màlúù tí kò ṣe é kà tàbí tí kò níye rúbọ+ nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.+  Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà wá sí àyè+ rẹ̀, sínú yàrá inú pátápátá nínú ilé náà, Ibi Mímọ́ Jù Lọ, sí abẹ́ ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà.  Nítorí tí àwọn kérúbù náà na ìyẹ́ apá wọn jáde sórí ibi tí Àpótí wà, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà bo Àpótí àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ láti òkè wá.+  Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀pá+ náà gùn, tí ó fi jẹ́ pé orí àwọn ọ̀pá náà ni a lè rí ní Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú pátápátá, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn lóde. Wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.+  Kò sí nǹkan mìíràn nínú Àpótí náà ju wàláà+ òkúta méjì tí Mósè kó+ síbẹ̀ ní Hórébù, nígbà tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ nígbà tí wọ́n ń jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́, àwọsánmà+ kún ilé Jèhófà. 11  Àwọn àlùfáà+ kò sì lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́+ wọn nítorí àwọsánmà náà, nítorí ògo+ Jèhófà kún ilé Jèhófà.+ 12  Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì wí pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé òun yóò máa gbé inú ìṣúdùdù+ nínípọn. 13  Mo ti ṣe àṣeyọrí kíkọ́ ilé tí ó jẹ́ ibùjókòó gíga fíofío fún ọ,+ ibi àfìdímúlẹ̀+ fún ọ láti máa gbé fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 14  Nígbà náà ni ọba yí ojú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre+ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ti wà ní ìdúró. 15  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó fi ẹnu ara rẹ̀ bá Dáfídì+ baba mi sọ̀rọ̀, tí ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ,+ pé, 16  ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, èmi kò yan+ ìlú ńlá kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé+ fún orúkọ mi,+ kí ó lè máa wà níbẹ̀; ṣùgbọ́n èmi yóò yan Dáfídì láti wá wà lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 17  Ó sì wà ní góńgó ọkàn-àyà Dáfídì baba mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 18  Ṣùgbọ́n Jèhófà wí fún Dáfídì baba mi pé, ‘Nítorí ìdí náà pé ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ láti kọ́ ilé fún orúkọ mi, o ṣe dáadáa, nítorí pé ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ.+ 19  Kìkì pé kì í ṣe ìwọ fúnra rẹ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọkùnrin rẹ tí yóò jáde láti abẹ́nú rẹ wá ni ẹni tí yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’+ 20  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọ̀rọ̀+ rẹ̀ tí ó ti sọ ṣẹ, kí èmi lè dìde ní ipò Dáfídì baba mi, kí n sì jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ, kí n sì lè kọ́ ilé náà fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ 21  kí n sì lè wá àyè kan níbẹ̀ fún Àpótí, níbi tí májẹ̀mú+ Jèhófà wà, èyí tí ó bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” 22  Sólómọ́nì sì dúró níwájú pẹpẹ+ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run+ wàyí; 23  ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ+ ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, tí ń pa májẹ̀mú àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ mọ́ sí àwọn ìránṣẹ́+ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn-àyà wọn rìn níwájú rẹ,+ 24  ìwọ tí o ti pa èyí tí o ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́ sí i, tí ó fi jẹ́ pé o fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.+ 25  Wàyí o, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pa èyí tí o ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́ sí i, pé, ‘A kì yóò ké ọkùnrin tìrẹ kankan kúrò níwájú mi láti máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì,+ kìkì bí àwọn ọmọ rẹ yóò bá kíyè sí ọ̀nà wọn nípa rírìn níwájú mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rìn níwájú mi.’ 26  Wàyí o, ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́, kí ìlérí+ rẹ tí o ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi já sí aṣeégbẹ́kẹ̀lé. 27  “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ha máa gbé lórí ilẹ̀ ayé+ ní tòótọ́ bí? Wò ó! Àwọn ọ̀run,+ bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run,+ kò lè gbà ọ́;+ nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí, ilé yìí+ tí mo kọ́! 28  Kí o sì yíjú sí àdúrà+ ìránṣẹ́ rẹ àti sí ìbéèrè rẹ̀ fún ojú rere,+ ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti fetí sí igbe ìpàrọwà àti sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà níwájú rẹ lónìí;+ 29  kí ojú rẹ lè là+ sí ilé yìí tọ̀sán-tòru, sí ibi tí o sọ pé, ‘Orúkọ mi yóò wà níbẹ̀,’+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà síhà ibí yìí.+ 30  Kí o sì fetí sí ìbéèrè fún ojú rere+ níhà ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń gbà ní àdúrà síhà ibí yìí; ǹjẹ́ kí ìwọ fúnra rẹ gbọ́ ní ibi tí o ń gbé, ní ọ̀run,+ kí o sì gbọ́, kí o sì dárí jì.+ 31  “Nígbà tí ènìyàn kan bá ṣẹ̀ sí ọmọnìkejì rẹ̀,+ tí ó sì gbé ègún lé e lórí ní tòótọ́, láti mú un wá sínú ipò ìdáhùn fún ègún+ náà, tí ó sì wá ní tòótọ́ síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí, nígbà tí ó wà nínú ègún náà, 32  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ nípa pípe ẹni burúkú ní burúkú, nípa fífi ọ̀nà rẹ̀ sí orí òun fúnra rẹ̀,+ àti nípa pípe olódodo ní olódodo,+ nípa fífi fún un ní ìbámu pẹ̀lú òdodo+ tirẹ̀. 33  “Nígbà tí a bá ṣẹ́gun àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì níwájú ọ̀tá,+ nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó ní dídẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ rẹ+ ní tòótọ́, tí wọ́n sì gbé orúkọ rẹ lárugẹ,+ tí wọ́n sì gbàdúrà,+ tí wọ́n sì béèrè fún ojú rere lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí,+ 34  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì+ jì kí o sì mú wọn padà+ wá sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá+ wọn. 35  “Nígbà tí a bá sé ọ̀run pa, tí òjò kò fi rọ̀,+ nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó ní dídẹ́ṣẹ̀+ sí ọ, tí wọ́n sì gbàdúrà ní tòótọ́ síhà ibí yìí,+ tí wọ́n sì gbé orúkọ rẹ lárugẹ, tí wọ́n sì yí padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó ní ṣíṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́,+ 36  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì, àní ti àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé o kọ́+ wọn ní ọ̀nà rere tí ó yẹ kí wọ́n máa rìn;+ kí o sì rọ̀jò+ sórí ilẹ̀ rẹ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní àjogúnbá. 37  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìyàn+ mú ní ilẹ̀ náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn+ jà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjógbẹ ṣẹlẹ̀, èbíbu,+ eéṣú+ àti aáyán;+ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀tá wọn sàga tì wọ́n ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè wọn—irú ìyọnu àjàkálẹ̀ èyíkéyìí, irú àrùn èyíkéyìí— 38  àdúrà yòówù,+ ìbéèrè fún ojú rere+ yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì,+ nítorí pé olúkúlùkù wọ́n mọ ìyọnu àjàkálẹ̀ ọkàn-àyà+ tirẹ̀, tí wọ́n sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ wọn ní tòótọ́ síhà ilé yìí,+ 39  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run,+ ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé,+ kí o sì dárí jì,+ kí o sì gbé ìgbésẹ̀,+ kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà+ rẹ̀, nítorí pé o mọ ọkàn-àyà+ rẹ̀ (nítorí ìwọ fúnra rẹ nìkan ṣoṣo ní o mọ ọkàn-àyà gbogbo ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú);+ 40  kí wọ́n lè máa bẹ̀rù+ rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà láàyè ní orí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá+ wa. 41  “Pẹ̀lúpẹ̀lú, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+ tí kì í ṣe ara àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí ó sì ti ilẹ̀ jíjìnnà wá ní tòótọ́ nítorí orúkọ rẹ+ 42  (nítorí wọn yóò gbọ́ nípa orúkọ ńlá rẹ+ àti nípa ọwọ́ líle rẹ+ àti nípa apá rẹ nínà jáde), tí ó sì wá ní ti gidi, tí ó sì gbàdúrà síhà ilé yìí,+ 43  kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé,+ kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí;+ kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè wá mọ orúkọ rẹ,+ kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé yìí tí mo kọ́.+ 44  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ènìyàn rẹ jáde lọ sí ogun+ láti gbéjà ko ọ̀tá wọn ní ọ̀nà tí o rán wọn,+ tí wọ́n sì gbàdúrà+ sí Jèhófà ní tòótọ́, síhà ìlú ńlá tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 45  kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ìbéèrè wọn fún ojú rere pẹ̀lú láti ọ̀run, kí o sì mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún wọn.+ 46  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ+ (nítorí kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí ìbínú rẹ sì ru sókè sí wọn, tí o sì jọ̀wọ́ wọn fún ọ̀tá, tí àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè sì kó wọn lọ ní òǹdè ní ti tòótọ́ sí ilẹ̀ ọ̀tá tí ó jìnnà tàbí tí ó wà nítòsí;+ 47  tí orí wọ́n sì wálé ní tòótọ́ ní ilẹ̀ tí a kó wọn lọ ní òǹdè,+ tí wọ́n sì padà+ ní ti tòótọ́, tí wọ́n sì béèrè+ fún ojú rere lọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè,+ pé, ‘A ti dẹ́ṣẹ̀,+ a sì ti ṣìnà,+ a ti ṣe burúkú’;+ 48  tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn-àyà+ wọn àti gbogbo ọkàn wọn padà sọ́dọ̀ rẹ ní tòótọ́ ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lọ ní òǹdè, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ ní tòótọ́ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ìlú ńlá tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ+ rẹ; 49  kí o sì gbọ́ àdúrà wọn àti ìbéèrè wọn fún ojú rere láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé,+ kí o sì mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún wọn,+ 50  kí o sì dárí ji+ àwọn ènìyàn rẹ tí ó ti dẹ́ṣẹ̀+ sí ọ àti gbogbo ìrélànàkọjá+ wọn, èyí tí wọ́n fi ré ìlànà rẹ kọjá;+ kí o sì ṣe wọ́n ní ẹni ìṣojú-àánú-sí+ níwájú àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè, kí wọ́n sì ṣe ojú àánú sí wọn 51  (nítorí ènìyàn rẹ ni wọ́n àti ogún ìní+ rẹ, àwọn tí o mú jáde wá láti Íjíbítì,+ láti inú ìléru irin),+ 52  kí ojú rẹ lè là sí ìbéèrè ìránṣẹ́ rẹ fún ojú rere àti sí ìbéèrè ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì fún ojú rere,+ nípa fífetísí wọn nínú gbogbo èyí tí wọ́n bá ké pè ọ́+ fún. 53  Nítorí ìwọ fúnra rẹ ni ó yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún ìní rẹ nínú gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti sọ nípasẹ̀ Mósè+ ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí o ń mú àwọn baba ńlá wa jáde kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 54  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sólómọ́nì parí gbígbàdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ìbéèrè fún ojú rere yìí, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ Jèhófà, kúrò ní títẹ̀ba lórí eékún+ rẹ̀ pẹ̀lú àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ tí ó tẹ́ sí ọ̀run;+ 55  ó sì dúró,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn rara súre+ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, pé: 56  “Ìbùkún ni fún Jèhófà,+ tí ó ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì ní ibi ìsinmi gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó ṣèlérí.+ Ọ̀rọ̀ kan kò kùnà+ nínú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 57  Kí Jèhófà Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa.+ Kí ó má ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kí ó ṣá wa tì,+ 58  kí ó lè tẹ ọkàn-àyà wa+ síhà ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀+ àti láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀+ àti àwọn ìlànà rẹ̀+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀+ mọ́, èyí tí ó pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa. 59  Kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí tí mo fi ṣe ìbéèrè fún ojú rere níwájú Jèhófà kí ó wà nítòsí+ Jèhófà Ọlọ́run wa lọ́sàn-án àti lóru, kí ó lè mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì bí ó ti yẹ ní ọjọ́+ dé ọjọ́; 60  kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè mọ̀+ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+ Kò sí òmíràn.+ 61  Kí ọkàn-àyà yín sì wà ní pípé pérépéré+ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run wa nípa rírìn nínú àwọn ìlànà rẹ̀ àti nípa pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.” 62  Ọba àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ sì ń rú ẹbọ títóbi lọ́lá níwájú Jèhófà.+ 63  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ tí ó ní láti rú sí Jèhófà, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà àgùntàn,+ kí ọba àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lè ṣe ayẹyẹ ṣíṣí+ ilé Jèhófà. 64  Ní ọjọ́ yẹn, ọba ní láti sọ àárín àgbàlá tí ó wà níwájú ilé Jèhófà+ di mímọ́, nítorí pé ibẹ̀ ni ó ti ní láti rú ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ọkà àti àwọn apá ọlọ́ràá ti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀; nítorí pé pẹpẹ bàbà+ tí ó wà níwájú Jèhófà ti kéré jù láti gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ọkà àti àwọn apá ọlọ́ràá+ ti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀. 65  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àjọyọ̀+ náà lọ ní àkókò yẹn, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, ìjọ+ títóbi láti àtiwọ Hámátì+ títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì,+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa fún ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje+ mìíràn sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá. 66  Ní ọjọ́ kẹjọ, ó rán àwọn ènìyàn náà lọ;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, wọ́n ń yọ̀,+ wọ́n sì ń ṣàríyá nínú ọkàn-àyà+ wọn lórí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé