Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 7:1-51

7  Ọdún mẹ́tàlá ni Sólómọ́nì fi kọ́ ilé tirẹ̀,+ tí ó fi jẹ́ pé ó parí gbogbo ilé tirẹ̀.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti kọ́ Ilé Igbó Lẹ́bánónì,+ tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, àti fífẹ̀ rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́, sórí ẹsẹ mẹ́rin ọwọ̀n igi kédárì; àwọn ìtì+ igi kédárì sì wà lórí àwọn ọwọ̀n náà.  A sì fi igi kédárì pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí i+ lókè lórí àwọn ọ̀pá àjà tí ó wà lórí àwọn ọwọ̀n márùn-dín-láàádọ́ta náà. Mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni ó wà ní ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.  Ní ti àwọn fèrèsé oníférémù, ẹsẹ mẹ́ta ni ó wà, ibi tí ìmọ́lẹ̀+ ń gbà wọlé sì dojú kọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ń gbà wọlé ní ipele mẹ́ta.  Gbogbo àwọn ẹnu ọ̀nà àti òpó ilẹ̀kùn sì dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pẹ̀lú férémù,+ àti pẹ̀lú iwájú ibi tí ìmọ́lẹ̀ ń gbà wọlé dojú kọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ń gbà wọlé ní ipele mẹ́ta.  Ó sì ṣe Gọ̀bì Ọlọ́wọ̀n ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ rẹ̀; gọ̀bì mìíràn sì wà ní iwájú wọn pẹ̀lú àwọn ọwọ̀n àti ìbòrí aṣíjiboni kan ní iwájú wọn.  Ní ti Gọ̀bì Ìtẹ́+ náà, níbi tí yóò ti máa ṣe ìdájọ́, ó ṣe gọ̀bì ìdájọ́;+ wọ́n sì fi igi kédárì bò ó láti ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ dé àwọn igi ìrólé.+  Ní ti ilé tirẹ̀ níbi tí yóò máa gbé, ní àgbàlá kejì,+ ó jìnnà sí ilé Gọ̀bì. Iṣẹ́ ọnà rẹ̀ dà bí èyí. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé kan tí ó dà bí Gọ̀bì yìí fún ọmọbìnrin Fáráò,+ ẹni tí Sólómọ́nì fẹ́.  Gbogbo ìwọ̀nyí ni a fi òkúta olówó+ ńlá ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n, tí a gbẹ́, tí a fi ayùn òkúta rẹ́, nínú àti lóde, àti láti ìpìlẹ̀ títí dé ọ̀ṣẹ́ṣẹ́ ògiri, àti lóde títí dé àgbàlá títóbi.+ 10  Àwọn òkúta olówó ńlá tí a sì fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ jẹ́ àwọn òkúta ńláńlá, àwọn òkúta ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àti àwọn òkúta ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. 11  Ní òkè sì ni àwọn òkúta olówó ńlá ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n wà, tí a gbẹ́, àti igi kédárì pẹ̀lú. 12  Ní ti àgbàlá títóbi náà, ẹsẹ+ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ẹsẹ kan ìtì igi kédárì wà yí i ká; àti èyí pẹ̀lú fún àgbàlá inú lọ́hùn-ún+ ilé+ Jèhófà, àti fún gọ̀bì+ ilé náà. 13  Sólómọ́nì Ọba sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́ lọ wá Hírámù+ wá láti Tírè. 14  Ó jẹ́ ọmọkùnrin obìnrin opó kan láti inú ẹ̀yà Náfútálì, baba rẹ̀ sì jẹ́ ọkùnrin ará Tírè,+ oníṣẹ́ bàbà;+ ó sì kún fún ọgbọ́n àti òye+ àti ìmọ̀ fún ṣíṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́ bàbà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wá sọ́dọ̀ Sólómọ́nì Ọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. 15  Ìgbà náà ni ó mọ ọwọ̀n bàbà méjì,+ tí gíga ọwọ̀n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún, okùn tín-ín-rín tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá yóò wọn ọ̀kọ̀ọ̀kan ọwọ̀n+ méjì náà yí ká. 16  Ó sì ṣe ọpọ́n méjì tí a fi bàbà rọ,+ láti fi sí orí àwọn ọwọ̀n náà. Ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni gíga ọpọ́n kìíní, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga ọpọ́n kejì. 17  Àwọn àwọ̀n tí ó so kọ́ra sì ń bẹ, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí a lọ́, tí ó so kọ́ra bí ẹ̀wọ̀n,+ fún àwọn ọpọ́n tí ó wà ní orí àwọn ọwọ̀n+ náà; méje fún ọpọ́n kìíní, àti méje fún ọpọ́n kejì. 18  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe àwọn pómégíránétì, ẹsẹ méjì yíká-yíká sórí àsokọ́ra bí àwọ̀n kìíní láti bo àwọn ọpọ́n tí ó wà ní orí àwọn ọwọ̀n náà; ohun tí ó sì ṣe sí ọpọ́n kejì nìyẹn.+ 19  Àwọn ọpọ́n tí ó sì wà ní orí àwọn ọwọ̀n tí ó wà ní gọ̀bì jẹ́ iṣẹ́ òdòdó lílì,+ ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. 20  Àwọn ọpọ́n náà sì wà lórí ọwọ̀n méjì náà, àti ní òkè, nítòsí ẹ̀gbẹ́ ibi tí ó yọ síta tí kò jìnnà sí àsokọ́ra bí àwọ̀n náà; igba pómégíránétì+ ní àwọn ẹsẹẹsẹ yí ká sì ni ó wà lára ọ̀kọ̀ọ̀kan ọpọ́n náà. 21  Ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé àwọn ọwọ̀n+ gọ̀bì+ tẹ́ńpìlì nà ró. Nípa báyìí, ó gbé ọwọ̀n apá ọ̀tún nà ró, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jákínì, lẹ́yìn náà, ó sì gbé ọwọ̀n apá òsì nà ró, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bóásì. 22  Iṣẹ́ òdòdó lílì sì wà ní orí àwọn ọwọ̀n náà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ àwọn ọwọ̀n náà parí. 23  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe òkun dídà+ náà ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ẹnu rẹ̀ kan dé ẹnu rẹ̀ kejì, ó rí bìrìkìtì yí ká; gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì gba okùn tí ó jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti na gbogbo àyíká rẹ̀+ já. 24  Àwọn ohun ọ̀ṣọ́+ onírìísí akèrègbè+ sì wà nísàlẹ̀ ẹnu rẹ̀ yí po, yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan, wọ́n yí òkun náà po,+ pẹ̀lú ẹsẹ méjì àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí akèrègbè tí a rọ ní rírọ tirẹ̀. 25  Ó dúró lórí akọ màlúù méjìlá,+ mẹ́ta dojú kọ àríwá, mẹ́ta dojú kọ ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta dojú kọ gúúsù, mẹ́ta sì dojú kọ ìlà-oòrùn; òkun náà sì wà lókè lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì wà níhà àárín.+ 26  Ìnípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìbú ọwọ́+ kan; ẹnu rẹ̀ sì dà bí iṣẹ́ ọnà ẹnu ife, ìtànná òdòdó lílì.+ Ẹgbàá òṣùwọ̀n báàfù+ ni ó ń gbà.+ 27  Ó sì ń bá a lọ láti ṣe kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wàá+ tí a fi bàbà ṣe, gígùn kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀ rẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga rẹ̀. 28  Èyí sì ni iṣẹ́ ọnà àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà: wọ́n ní àwọn abala ẹ̀gbẹ́, àwọn abala ẹ̀gbẹ́ náà sì wà láàárín àwọn ọ̀pá ìdábùú. 29  Àwọn kìnnìún,+ akọ màlúù+ àti kérúbù+ sì wà lára àwọn abala ẹ̀gbẹ́ tí ó wà láàárín àwọn ọ̀pá ìdábùú náà, bí ó sì ṣe wà nìyẹn lókè àwọn ọ̀pá ìdábùú náà. Àwọn ọ̀ṣọ́ òdòdó+ ní iṣẹ́ àfikọ́ wà lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún àti akọ màlúù náà. 30  Kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan sì ní àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin tí a fi bàbà ṣe, pẹ̀lú àwọn ọ̀pá àgbá kẹ̀kẹ́ tí a fi bàbà ṣe; àwọn ohun tí ó wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sì jẹ́ agbóhunró fún wọn. Abẹ́ bàsíà ni àwọn agbóhunró náà wà, a fi ọ̀ṣọ́ òdòdó rọ wọ́n ní òdì-kejì ọ̀kọ̀ọ̀kan. 31  Ẹnu rẹ̀ láti inú dé àwọn agbóhunró náà sókè sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ [?]; ẹnu rẹ̀ sì rí rìbìtì, iṣẹ́ ọnà ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, àwọn ohun gbígbẹ́ sì wà ní ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn abala ẹ̀gbẹ́ wọn sì dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, wọn kò rí rìbìtì. 32  Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì wà nísàlẹ̀ àwọn abala ẹ̀gbẹ́ náà, agbóhunró àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹrù náà; gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 33  Iṣẹ́ ọnà àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà sì dà bí iṣẹ́ ọnà àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin.+ Àwọn agbóhunró wọn àti àwọn etí àgbá kẹ̀kẹ́ wọn àti àwọn sípóòkù wọn àti àwọn họ́ọ̀bù wọn, rírọ ni gbogbo wọn. 34  Agbóhunró mẹ́rin ni ó sì wà lára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan; àwọn agbóhunró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. 35  Ibi ìgbé-nǹkan-lé tí ó ga ní ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ sì wà lorí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, ó rí bìrìkìtì yí ká; àti ní orí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn abala ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú rẹ̀. 36  Síwájú sí i, ó fín+ àwọn kérúbù, kìnnìún àti àwòrán igi ọ̀pẹ sára àwọn àwo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti sára àwọn abala ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àyè tí ó ṣófo lára ọ̀kọ̀ọ̀kan, àti àwọn ọ̀ṣọ́ òdòdó yí ká.+ 37  Bí ó ti ṣe kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà nìyí;+ gbogbo wọ́n ní rírọ+ kan náà, ìwọ̀n kan náà, ìrí kan náà. 38  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe bàsíà bàbà mẹ́wàá.+ Ogójì òṣùwọ̀n báàfù ni bàsíà kọ̀ọ̀kan yóò gbà. Bàsíà kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Bàsíà kan wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan fún kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà. 39  Lẹ́yìn náà, ó gbé kẹ̀kẹ́ ẹrù márùn-ún sí ìhà ọ̀tún ilé náà, àti márùn-ún sí ìhà òsì ilé+ náà; òkun náà ní ó sì gbé sí ìhà ọ̀tún ilé náà níhà ìlà-oòrùn, síhà gúúsù.+ 40  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Hírámù+ sì ṣe àwọn bàsíà+ àti àwọn ṣọ́bìrì+ àti àwọn àwokòtò+ náà. Níkẹyìn, Hírámù parí+ ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún Sólómọ́nì Ọba ní ti ilé Jèhófà: 41  Ọwọ̀n méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n+ onírìísí àwokòtò tí ó wà ní orí ọwọ̀n méjèèjì, àti àsokọ́ra bí àwọ̀n+ méjèèjì láti fi bo ọpọ́n rìbìtì méjèèjì tí ó wà ní orí àwọn ọwọ̀n náà, 42  àti irínwó pómégíránétì+ náà fún àsokọ́ra bí àwọ̀n méjèèjì, ẹsẹ pómégíránétì méjì fún àsokọ́ra bí àwọ̀n kọ̀ọ̀kan, láti fi bo ọpọ́n onírìísí àwokòtò méjèèjì tí ó wà lórí ọwọ̀n méjèèjì náà; 43  àti kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ àti bàsíà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ tí ó wà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, 44  àti òkun+ náà àti akọ màlúù méjèèjìlá tí ó wà lábẹ́ òkun+ náà; 45  àti àwọn garawa àti àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn àwokòtò àti gbogbo nǹkan èlò wọ̀nyí,+ tí Hírámù fi bàbà tí a mú dán ṣe fún Sólómọ́nì Ọba fún ilé Jèhófà. 46  Àgbègbè Jọ́dánì+ ni ọba ti rọ wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀, láàárín Súkótù+ àti Sárétánì.+ 47  Sólómọ́nì sì fi gbogbo nǹkan èlò+ náà sílẹ̀ láìwọ̀n nítorí tí ó jẹ́ ìwọ̀n púpọ̀+ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. A kò mọ+ ìwọ̀n bàbà náà dájú. 48  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Sólómọ́nì sì ṣe gbogbo nǹkan èlò tí ó jẹ mọ́ ti ilé Jèhófà, ó fi wúrà ṣe pẹpẹ,+ tábìlì+ tí búrẹ́dì àfihàn wà lórí rẹ̀ ni ó sì fi wúrà ṣe, 49  àti àwọn ọ̀pá fìtílà,+ márùn-ún níhà ọ̀tún àti márùn-ún níhà òsì níwájú yàrá inú pátápátá, ni ó fi ògidì wúrà+ ṣe, àti àwọn ìtànná+ àti àwọn fìtílà+ àti àwọn ẹ̀mú,+ ni ó fi wúrà ṣe, 50  àti àwọn bàsíà àti àwọn àlùmọ́gàjí fìtílà+ àti àwọn àwokòtò+ àti àwọn ife+ àti àwọn ìkóná,+ ni ó fi ògidì wúrà ṣe, àti ojúhò àwọn ilẹ̀kùn+ ilé inú lọ́hùn-ún, èyíinì ni, Ibi Mímọ́ Jù Lọ, àti ti àwọn ilẹ̀kùn+ ilé tẹ́ńpìlì,+ ni ó fi wúrà ṣe. 51  Níkẹyìn, gbogbo iṣẹ́ tí Sólómọ́nì Ọba ní í ṣe ní ti ilé Jèhófà dé ìparí+ rẹ̀; Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ohun tí Dáfídì baba+ rẹ̀ sọ di mímọ́ wọlé; fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò náà ni ó kó sínú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé