Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 6:1-38

6  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún ọ̀rìn-lé-nírínwó lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní ọdún kẹrin,+ ní oṣù Sífì,+ èyíinì ni, oṣù kejì,+ lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba lórí Ísírẹ́lì, pé ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé fún Jèhófà.+  Ilé tí Sólómọ́nì Ọba sì kọ́+ fún Jèhófà jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́+ ní gígùn rẹ̀, àti ogún ní fífẹ̀ rẹ̀, àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga+ rẹ̀.  Gọ̀bì+ iwájú tẹ́ńpìlì ilé náà sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ní iwájú fífẹ̀ ilé náà. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni ó jẹ́ ní jíjìn rẹ̀, ní iwájú ilé náà.  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe àwọn fèrèsé oníférémù tóóró+ fún ilé náà.  Síwájú sí i, ó mọ ìgbékalẹ̀ ẹ̀gbẹ́ sí ògiri ilé náà yí ká, sí àwọn ògiri ilé náà yí tẹ́ńpìlì náà àti yàrá inú pátápátá+ ká, ó sì ṣe àwọn ìyẹ̀wù+ ẹ̀gbẹ́ yí ká.  Ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀ rẹ̀, ti àárín sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní fífẹ̀ rẹ̀, ìkẹta sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ní fífẹ̀ rẹ̀; nítorí àwọn ìgékùsẹ́yìn+ ń bẹ tí ó ṣe sí ilé náà yí ká ní òde, kí ó má bàa ní agbóhunró lára ògiri ilé+ náà.  Ní ti ilé náà, nígbà tí a ń kọ́ ọ, òkúta gbígbẹ́+ tí a ti ṣe parí ni a fi kọ́ ọ; àti ní ti òòlù àti àáké tàbí irinṣẹ́ irin èyíkéyìí, a kò gbúròó wọn nínú ilé+ náà nígbà tí a ń kọ́ ọ.  Ẹnu ọ̀nà+ ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá wà ní ìhà ọ̀tún ilé náà, àtẹ̀gùn aláyìíkọrọyí ni wọ́n sì ń gbà gòkè lọ sí ti àárín, àti láti ti àárín dé ìkẹta.  Síwájú sí i, ó ń bá a lọ ní kíkọ́ ilé náà kí ó bàa lè parí rẹ̀,+ ó sì fi àwọn ìtì igi àti ọ̀wọ́ igi kédárì+ bo ilé náà. 10  Jú bẹ́ẹ̀ lọ, ó kọ́ àwọn ìyẹ̀wù+ ẹ̀gbẹ́ tí ó ga ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ti gbogbo ilé náà, àwọn ẹ̀là gẹdú+ igi kédárì sì ni ó gbé wọn ró sára ilé náà. 11  Láàárín àkókò náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Sólómọ́nì+ wá pé:+ 12  “Ní ti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́, bí ìwọ yóò bá rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀+ mi, tí ìwọ yóò sì ṣe àwọn ìpinnu ìdájọ́+ mi, tí ìwọ yóò sì pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ ní ti tòótọ́ nípa rírìn nínú wọn,+ dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò mú ọ̀rọ̀ mi nípa rẹ èyí tí mo sọ fún Dáfídì baba rẹ+ ṣẹ; 13  èmi yóò sì máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ní ti tòótọ́, èmi kì yóò sì fi àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì sílẹ̀.”+ 14  Sólómọ́nì sì ń bá a lọ ní kíkọ́ ilé náà kí ó bàa lè parí rẹ̀.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn pátákó kédárì pẹlẹbẹ kọ́ àwọn ògiri ilé tí ó wà nínú rẹ̀. Láti ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé àjà ni ó fi àwọn ẹ̀là gẹdú bò nínú; ó sì ń bá a lọ láti fi àwọn pátákó júnípà+ pẹlẹbẹ bo ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilé náà. 16  Síwájú sí i, ó fi àwọn pátákó kédárì pẹlẹbẹ kọ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ sí àwọn ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ títí dé àwọn igi ìrólé, ó sì kọ́ Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ sí i, nínú yàrá inú pátápátá.+ 17  Ogójì ìgbọ̀nwọ́ sì ni ilé náà jẹ́, èyíinì ni, tẹ́ńpìlì+ tí ó wà ní iwájú rẹ̀.+ 18  Igi kédárì tí ó wà lára ilé náà nínú sì ní àwọn ohun ọ̀ṣọ́ gbígbẹ́ onírìísí akèrègbè+ àti àwọn òdòdó ẹ̀yẹ+ lára. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ igi kédárì; kò sí òkúta kankan tí a rí. 19  Inú yàrá inú pátápátá+ ní inú lọ́hùn-ún ilé náà ni ó sì pèsè sílẹ̀, láti gbé àpótí+ májẹ̀mú+ Jèhófà síbẹ̀. 20  Yàrá inú pátápátá sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀,+ àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ògidì wúrà+ bò ó, ó sì fi igi kédárì bo pẹpẹ+ náà. 21  Sólómọ́nì sì ń bá a lọ láti fi ògidì wúrà+ bo+ inú ilé náà, ó sì mú kí àsokọ́ra bí ẹ̀wọ̀n+ tí a fi wúrà ṣe gba iwájú yàrá inú pátápátá+ kọjá, ó sì fi wúrà bò ó. 22  Gbogbo ilé náà ni ó sì fi wúrà+ bò, títí a fi parí gbogbo ilé náà; gbogbo pẹpẹ+ tí ó wà ní ìhà yàrá inú pátápátá ni ó sì fi wúrà bò.+ 23  Síwájú sí i, ó fi igi olóròóró ṣe kérúbù méjì+ sí yàrá inú pátápátá, tí gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan+ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. 24  Ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá kérúbù náà, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni ìkejì ìyẹ́ apá kérúbù náà. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni ó jẹ́ láti ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá rẹ̀ dé ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá+ rẹ̀. 25  Kérúbù kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. Kérúbù méjèèjì ní ìwọ̀n kan náà àti ìrí kan náà. 26  Gíga kérúbù kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, bẹ́ẹ̀ sì ni ti kérúbù kejì jẹ́. 27  Nígbà náà ni ó gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn-ún, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n na àwọn ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà jáde. Nípa báyìí, ìyẹ́ apá ọ̀kan kan ògiri, ìyẹ́ apá kérúbù kejì sì kan ògiri kejì; ìyẹ́ apá wọn sì nà síhà àárín ilé náà, tí ìyẹ́ apá ń kan ìyẹ́ apá.+ 28  Jú bẹ́ẹ̀ lọ, ó fi wúrà bo+ àwọn kérúbù náà. 29  Gbogbo ògiri ilé náà yíká-yíká ni ó sì gbẹ́ àwọn ohun gbígbẹ́ kérúbù+ fífín àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ+ àti àwọn iṣẹ́ ọnà fífín ti ìtànná+ sí, nínú àti lóde; 30  ilẹ̀pẹ̀pẹ̀+ ilé náà ni ó sì fi wúrà bò, nínú àti lóde. 31  Ẹnu ọ̀nà yàrá inú pátápátá ni ó sì fi àwọn ilẹ̀kùn+ igi olóròóró+ ṣe: àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́, àwọn òpó ilẹ̀kùn àti ìkarùn-ún. 32  Àwọn ilẹ̀kùn méjèèjì sì jẹ́ igi olóròóró, ó sì gbẹ́ àwọn ohun gbígbẹ́ ti kérúbù àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ àti àwọn iṣẹ́ ọnà fífín ti ìtànná sára wọn, ó sì fi wúrà bò wọ́n; ó sì tẹ̀ síwájú láti na wúrà náà bo àwọn kérúbù àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ náà. 33  Bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣe sí ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì, ó fi igi olóròóró ṣe àwọn òpó ilẹ̀kùn, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba. 34  Àwọn ilẹ̀kùn méjèèjì sì jẹ́ igi júnípà.+ Awẹ́ méjèèjì ilẹ̀kùn kan ń yí lóri àwọn ìkọ́ olóyìípo,+ awẹ́ méjèèjì ilẹ̀kùn kejì sì ń yí lórí àwọn ìkọ́ olóyìípo. 35  Ó sì gbẹ́ àwọn kérúbù àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ àti àwọn iṣẹ́ ọnà fífín ti ìtànná, ó sì fi wúrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo àwọn àwòrán náà.+ 36  Ó sì ń bá a lọ láti fi ẹsẹ+ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ẹsẹ kan ìtì igi kédárì kọ́ àgbàlá inú lọ́hùn-ún.+ 37  Ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀+ ilé Jèhófà lélẹ̀, ní oṣù òṣùpá náà Sífì;+ 38  àti ní ọdún kọkànlá, ní oṣù òṣùpá náà Búlì, èyíinì ni, oṣù kẹjọ, a parí+ ilé náà ní ti gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo àwòrán ilé kíkọ́ rẹ̀;+ tí ó fi jẹ́ pé ọdún méje ni ó fi kọ́ ọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé