Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 5:1-18

5  Hírámù+ ọba Tírè+ sì tẹ̀ síwájú láti rán àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀ sí Sólómọ́nì, nítorí tí ó ti gbọ́ pé òun ni wọ́n fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba rẹ̀; nítorí Hírámù fi ìgbà gbogbo jẹ́ olùfẹ́ Dáfídì.+  Ẹ̀wẹ̀, Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù, pé:+  “Ìwọ alára mọ̀ dunjú pé Dáfídì baba mi kò lè kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nítorí ogun+ tí wọ́n fi yí i ká, títí Jèhófà fi fi wọ́n sí abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.  Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi yí ká.+ Kò sí alátakò kankan, nǹkan búburú kankan kò sì ṣẹlẹ̀.+  Sì kíyè sí i, mo ń ronú nípa kíkọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí fún Dáfídì baba mi pé, ‘Ọmọkùnrin rẹ tí èmi yóò fi sórí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ, òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+  Wàyí o, pàṣẹ pé kí wọ́n gé kédárì fún mi láti Lẹ́bánónì;+ àwọn ìránṣẹ́ mi pàápàá yóò sì wà pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì fi owó ọ̀yà àwọn ìránṣẹ́ rẹ fún ọ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí o bá sọ, nítorí ìwọ alára mọ̀ pé láàárín wa kò sí ẹni tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ọmọ Sídónì.”+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Hírámù+ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì, ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ gidigidi, ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìbùkún+ ni fún Jèhófà lónìí, ní ti pé ó ti fún Dáfídì ní ọmọkùnrin tí ó gbọ́n+ lórí àwọn ènìyàn yìí tí ó pọ̀ níye!”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Hírámù ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Mo ti gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi. Ní tèmi, èmi yóò ṣe gbogbo èyí tí o ní inú dídùn sí nínú ọ̀ràn ti àwọn ẹ̀là gẹdú igi kédárì àti àwọn ẹ̀là gẹdú igi júnípà.+  Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò fúnra wọn kó wọn sọ̀ kalẹ̀ wá láti Lẹ́bánónì+ sí òkun; èmi, ní tèmi, yóò sì dì wọ́n ní àwọn àdìlù gẹdú àmúléfòó kí wọ́n lè lọ lórí òkun títí lọ dé ibi tí ìwọ bá ránṣẹ́ sọ fún mi;+ dájúdájú, èmi yóò sì mú kí a yà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ níbẹ̀, ìwọ, ní tìrẹ, yóò sì gbé wọn; ìwọ, ní tìrẹ, yóò sì ṣe èyí tí èmi ní inú dídùn sí nípa pípèsè oúnjẹ fún agbo ilé mi.”+ 10  Nítorí náà, Hírámù di olùfún Sólómọ́nì ní àwọn ẹ̀là gẹdú igi kédárì àti àwọn ẹ̀là gẹdú igi júnípà ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo èyí tí ó ní inú dídùn sí. 11  Sólómọ́nì, ní tirẹ̀, sì fún Hírámù ní ọ̀kẹ́ kan òṣùwọ̀n kọ́ọ̀+ àlìkámà gẹ́gẹ́ bí ìpèsè oúnjẹ fún agbo ilé rẹ̀ àti ogún òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ òróró tí a fún.+ Ohun tí Sólómọ́nì ń bá a nìṣó láti fún Hírámù nìyẹn lọ́dọọdún.+ 12  Jèhófà, ní tirẹ̀, fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un;+ àlàáfíà sì wá wà láàárín Hírámù àti Sólómọ́nì, àwọn méjèèjì sì tẹ̀ síwájú láti dá májẹ̀mú. 13  Sólómọ́nì Ọba sì ń bá a nìṣó ní mímú àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe gòkè wá láti inú gbogbo Ísírẹ́lì; àwọn tí a sì ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe+ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ọkùnrin. 14  Òun a sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Lẹ́bánónì ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oṣù kan. Wọn a máa wà ní Lẹ́bánónì fún oṣù kan, wọn a sì máa wà ní ilé wọn fún oṣù méjì;+ Ádónírámù+ sì ni ó wà lórí àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn+ nínú òpò àfipámúniṣe.+ 15  Sólómọ́nì sì wá ní+ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ arẹrù+ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin agékùúta+ ní òkè ńlá,+ 16  yàtọ̀ sí àwọn olórí ajẹ́lẹ̀+ tí ó jẹ́ ti Sólómọ́nì tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ náà, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàdínlógún òléwájú+ lórí àwọn ènìyàn náà tí wọ́n jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ náà. 17  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbẹ́ àwọn òkúta ńláńlá, àwọn òkúta olówó ńlá,+ láti fi òkúta gbígbẹ́+ ṣe ìpìlẹ̀+ ilé náà. 18  Nítorí náà, àwọn akọ́lé ti Sólómọ́nì àti àwọn akọ́lé ti Hírámù àti àwọn ará Gébálì+ gé e, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní pípèsè àwọn ẹ̀là gẹdú àti àwọn òkúta sílẹ̀ láti fi kọ́ ilé náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé