Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 4:1-34

4  Sólómọ́nì Ọba sì ń jẹ ọba lọ lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ aládé+ tí ó ní: Asaráyà ọmọkùnrin Sádókù,+ àlùfáà;  Élíhóréfì àti Áhíjà, àwọn ọmọkùnrin Ṣíṣà, akọ̀wé;+ Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin Áhílúdù, akọ̀wé ìrántí;  Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Sádókù àti Ábíátárì+ sì jẹ́ àlùfáà;  Asaráyà ọmọkùnrin Nátánì+ sì wà lórí àwọn ajẹ́lẹ̀, Sábúdù ọmọkùnrin Nátánì sì jẹ́ àlùfáà, ọ̀rẹ́+ ọba;  Áhíṣárì sì wà lórí agbo ilé, àti Ádónírámù+ ọmọkùnrin Ábídà, lórí àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe.+  Sólómọ́nì sì ní ajẹ́lẹ̀ méjìlá lórí gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. A máa já lé ẹnì kọ̀ọ̀kan léjìká láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan nínú ọdún.+  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ wọn: Ọmọkùnrin Húrì, ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù;+  ọmọkùnrin Dékérì, ní Mákásì àti ní Ṣáálíbímù+ àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ àti Eloni-bẹti-hánánì; 10  ọmọkùnrin Hésédì, ní Árúbótì (tirẹ̀ ni Sókóhì àti gbogbo ilẹ̀ Héfà);+ 11  ọmọkùnrin Ábínádábù, gbogbo ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Dórì+ (Táfátì alára, ọmọbìnrin Sólómọ́nì, di aya rẹ̀); 12  Báánà ọmọkùnrin Áhílúdù, ní Táánákì+ àti Mẹ́gídò+ àti ní gbogbo Bẹti-ṣéánì,+ èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì+ nísàlẹ̀ Jésíréélì,+ láti Bẹti-ṣéánì sí Ebẹli-méhólà+ sí ẹkùn ilẹ̀ Jókíméámù;+ 13  ọmọkùnrin Gébérì, ní Ramoti-gílíádì+ (tirẹ̀ ni àwọn abúlé àgọ́ Jáírì+ ọmọkùnrin Mánásè, èyí tí ó wà ní Gílíádì;+ tirẹ̀ ni ẹkùn ilẹ̀ Ágóbù,+ èyí tí ó wà ní Báṣánì:+ ọgọ́ta ìlú ńlá títóbi tí ó ní ògiri àti ọ̀pá ìdábùú bàbà); 14  Áhínádábù ọmọkùnrin Ídò, ní Máhánáímù;+ 15  Áhímáásì, ní Náfútálì+ (òun, pẹ̀lú, fẹ́ Básémátì, ọmọbìnrin Sólómọ́nì, ṣe aya);+ 16  Báánà ọmọkùnrin Húṣáì, ní Áṣérì+ àti Béálótì; 17  Jèhóṣáfátì ọmọkùnrin Párúà, ní Ísákárì;+ 18  Ṣíméì+ ọmọkùnrin Élà, ní Bẹ́ńjámínì;+ 19  Gébérì ọmọkùnrin Úráì, ní ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ Síhónì+ ọba àwọn Ámórì,+ àti ti Ógù+ ọba Báṣánì,+ ajẹ́lẹ̀ kan sì ni ó wà lórí gbogbo ajẹ́lẹ̀ yòókù tí ó wà ní ilẹ̀ náà. 20  Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà lẹ́bàá òkun nítorí tí wọ́n jẹ́ ògìdìgbó,+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.+ 21  Ní ti Sólómọ́nì, ó jẹ́ olùṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti Odò+ dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti dé ààlà Íjíbítì. Wọ́n ń mú àwọn ẹ̀bùn wá, wọ́n sì ń sin Sólómọ́nì ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.+ 22  Oúnjẹ Sólómọ́nì déédéé fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n kọ́ọ̀+ ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun, 23  màlúù mẹ́wàá tí ó sanra àti ogún màlúù láti inú pápá ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín+ mélòó kan àti àwọn àgbàlàǹgbó+ àti àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí a bọ́ sanra. 24  Nítorí tí ó ń jọba lórí ohun gbogbo tí ó wà ní ìhà ìhín Odò,+ láti Tífísà dé Gásà,+ àní gbogbo ọba ìhà ìhín Odò;+ àlàáfíà+ pàápàá sì jẹ́ tirẹ̀ ní gbogbo ẹkùn ilẹ̀ rẹ̀ yí ká. 25  Júdà+ àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò,+ olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́+ tirẹ̀, láti Dánì dé Bíá-ṣébà,+ ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì. 26  Sólómọ́nì sì wá ní ọ̀kẹ́ méjì ibùso ẹṣin+ fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ rẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ẹlẹ́ṣin. 27  Àwọn ajẹ́lẹ̀+ wọ̀nyí sì ń pèsè oúnjẹ fún Sólómọ́nì Ọba àti gbogbo ẹni tí ń wá síbi tábìlì Sólómọ́nì Ọba, olúkúlùkù ní oṣù tirẹ̀. Wọn kò fi ohunkóhun sílẹ̀ láìṣe. 28  Ọkà bálì àti èérún pòròpórò fún àwọn ẹṣin àti fún àgbájọ ọ̀wọ́ ẹṣin+ ni wọ́n sì ń bá a nìṣó ní mímú wá sí ibikíbi tí ibẹ̀ ì báà jẹ́, olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí a gbé lé e lọ́wọ́.+ 29  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n+ àti òye+ ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi àti fífẹ̀ ọkàn-àyà,+ bí iyanrìn tí ó wà ní etíkun.+ 30  Ọgbọ́n Sólómọ́nì sì pọ̀ jaburata+ ju ọgbọ́n gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn+ àti ju gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.+ 31  Ó sì gbọ́n ju ènìyàn èyíkéyìí mìíràn lọ, ju Étánì+ tí í ṣe Ẹ́síráhì àti Hémánì+ àti Kálíkólì+ àti Dáádà àwọn ọmọkùnrin Máhólì; òkìkí rẹ̀ sì wá kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yí ká.+ 32  Ó sì lè pa ẹgbẹ̀ẹ́dógún òwe,+ àwọn orin+ rẹ̀ sì wá jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún. 33  Òun a sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, láti orí kédárì tí ó wà ní Lẹ́bánónì+ dórí hísópù+ tí ń jáde wá lára ògiri; òun a sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko+ àti nípa àwọn ẹ̀dá tí ń fò+ àti nípa àwọn ohun tí ń rìn ká+ àti nípa àwọn ẹja.+ 34  Wọ́n sì ń wá ṣáá láti inú ènìyàn gbogbo láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì,+ àní láti ọ̀dọ̀ gbogbo ọba ilẹ̀ ayé tí ó ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé