Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 3:1-28

3  Sólómọ́nì sì tẹ̀ síwájú láti bá Fáráò ọba Íjíbítì dána,+ ó sì mú ọmọbìnrin Fáráò,+ ó sì mú un wá sí Ìlú Ńlá Dáfídì,+ títí ó fi parí kíkọ́ ilé+ òun tìkára rẹ̀ àti ilé Jèhófà+ àti ògiri tí ó yí Jerúsálẹ́mù ká.+  Kìkì pé àwọn ènìyàn náà ń rúbọ ní àwọn ibi gíga,+ nítorí a kò tíì kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà títí di àwọn ọjọ́ wọnnì.+  Sólómọ́nì sì ń bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́+ Jèhófà nípa rírìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ Dáfídì baba rẹ̀.+ Kìkì pé àwọn ibi gíga+ ni ó ti ń rúbọ déédéé, tí ó sì ń mú àwọn ọrẹ ẹbọ rú èéfín.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba lọ sí Gíbéónì+ láti rúbọ níbẹ̀, nítorí ìyẹn ni ibi gíga ńlá.+ Ẹgbẹ̀rún ẹbọ sísun ni Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí fi rúbọ lórí pẹpẹ náà.+  Ní Gíbéónì, Jèhófà fara han+ Sólómọ́nì lójú àlá+ ní òru; Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò fún ọ.”+  Látàrí èyí, Sólómọ́nì wí pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ ńláǹlà sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì baba mi, ní ìbámu pẹ̀lú bí ó ṣe rìn níwájú rẹ ní òtítọ́ àti ní òdodo+ àti ní ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà pẹ̀lú rẹ; ìwọ sì ń bá a lọ láti pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ńlá yìí mọ́ sí i, tí ìwọ fi fún un ní ọmọkùnrin kan láti jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.+  Àti nísinsìnyí, Jèhófà Ọlọ́run mi, ìwọ fúnra rẹ ni ó fi ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dáfídì baba mi, ọmọdékùnrin kékeré+ sì ni èmi. Èmi kò mọ bí a ti ń jáde lọ àti bí a ti ń wọlé.+  Ìránṣẹ́ rẹ sì wà ní àárín àwọn ènìyàn rẹ tí o ti yàn,+ ògìdìgbó ènìyàn tí kò níye tàbí tí kò ṣe é kà nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.+  Kí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn-àyà ìgbọràn láti máa fi ṣe ìdájọ́+ àwọn ènìyàn rẹ, láti fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú;+ nítorí ta ni ó lè ṣe ìdájọ́+ àwọn ènìyàn rẹ tí ó ṣòro yìí?”+ 10  Ohun náà sì dára ní ojú Jèhófà, nítorí pé Sólómọ́nì béèrè ohun yìí.+ 11  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Nítorí ìdí náà pé o ti béèrè ohun yìí, tí o kò sì béèrè ọjọ́ púpọ̀ fún ara rẹ tàbí béèrè ọrọ̀+ fún ara rẹ tàbí béèrè ọkàn àwọn ọ̀tá rẹ, tí o sì béèrè òye fún ara rẹ láti máa gbọ́ àwọn ẹjọ́,+ 12  wò ó! dájúdájú, èmi yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.+ Wò ó! Dájúdájú, èmi yóò fi ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye fún ọ,+ tí ó fi jẹ́ pé kò tíì sí ẹnì kan bí tìrẹ ṣáájú rẹ, àti lẹ́yìn rẹ kò sí ẹnì kan tí yóò dìde bí tìrẹ.+ 13  Ohun tí o kò sì béèrè pẹ̀lú ni èmi yóò fi fún ọ+ dájúdájú, àti ọrọ̀+ àti ògo, tí ó fi jẹ́ pé kò ní ṣẹlẹ̀ pé èyíkéyìí nínú àwọn ọba yóò dà bí rẹ, ní gbogbo ọjọ́ rẹ.+ 14  Bí ìwọ yóò bá sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, nípa pípa àwọn ìlànà+ àti àṣẹ mi mọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ ti rìn,+ èmi yóò mú àwọn ọjọ́ rẹ gùn sí i pẹ̀lú.”+ 15  Nígbà tí Sólómọ́nì jí,+ họ́wù, kíyè sí i, àlá ni. Nígbà náà ni ó wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì dúró níwájú àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun, ó sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀,+ ó sì se àsè+ fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 16  Ní àkókò yẹn, àwọn obìnrin méjì, kárùwà,+ wọlé wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.+ 17  Ìgbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn obìnrin náà wí pé: “Dákun, olúwa mi,+ èmi àti obìnrin yìí ń gbé ilé kan, tí ó fi jẹ́ pé mo bímọ nítòsí rẹ̀ nínú ilé náà. 18  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí mo bímọ, obìnrin yìí pẹ̀lú bímọ. A sì wà pa pọ̀ ni. Kò sí àjèjì pẹ̀lú wa nínú ilé, kò sí ẹnì kankan àyàfi àwa méjì nínú ilé náà. 19  Nígbà tí ó yá, ọmọ obìnrin yìí kú ní òru, nítorí tí ó sùn lé e lórí. 20  Nítorí náà, ó dìde ní àárín òru, ó sì gbé ọmọ mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí ẹrúbìnrin rẹ ń sùn lọ́wọ́, ó sì tẹ́ ẹ sí oókan àyà tirẹ̀, ọmọ rẹ̀ tí ó ti kú ni ó sì tẹ́ sí oókan àyà mi. 21  Nígbà tí mo dìde ní òwúrọ̀ láti ṣètọ́jú+ ọmọ mi, họ́wù, òun rèé tí ó ti kú. Nítorí náà, mo ṣàyẹ̀wò rẹ̀ fínnífínní ní òwúrọ̀, sì wò ó! kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.” 22  Ṣùgbọ́n obìnrin kejì sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọmọ mi ni èyí tí ó wà láàyè ọmọ tìrẹ sì ni òkú!” Ní gbogbo àkókò náà, obìnrin yìí ń wí pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ ni èyí tí ó jẹ́ òkú, ọmọ tèmi sì ni èyí tí ó wà láàyè.” Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nìṣó níwájú ọba.+ 23  Níkẹyìn, ọba sọ pé: “Ẹni yìí ń wí pé, ‘Èyí ni ọmọ mi, èyí tí ó wà láàyè, ọmọ tìrẹ sì ni èyí tí ó jẹ́ òkú!’ ẹni yẹn sì ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ ni èyí tí ó jẹ́ òkú, ọmọ tèmi sì ni èyí tí ó wà láàyè!’” 24  Ọba sì ń bá a lọ láti wí pé:+ “Ẹ bá mi mú idà kan wá.” Nítorí náà, wọ́n mú idà náà wá síwájú ọba. 25  Ọba sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ẹ la alààyè ọmọ náà sí méjì kí ẹ sì fi ìdajì fún obìnrin kan àti ìdajì fún èkejì.” 26  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin tí ó ni ọmọ tí ó wà láàyè wí fún ọba (nítorí àwọn ìmọ̀lára inú rẹ̀ lọ́hùn-ún+ ru sókè sí ọmọ rẹ̀,+ tí ó fi wí pé): “Dákun,+ olúwa mi! Ẹ fún un ní alààyè ọmọ náà. Ẹ má fi ikú pa á rárá.” Ní gbogbo àkókò náà, obìnrin kejì yìí ń wí pé: “Kò ní di tèmi bẹ́ẹ̀ ni kò ní di tìrẹ. Ẹ là á sí méjì!”+ 27  Látàrí èyí, ọba dáhùn, ó sì sọ pé: “Ẹ fún un ní alààyè ọmọ náà, kí ẹ má sì fi ikú pa á rárá. Òun ni ìyá rẹ̀.” 28  Gbogbo Ísírẹ́lì sì wá gbọ́ ìpinnu ìdájọ́+ tí ọba gbé kalẹ̀; ẹ̀rù sì bà wọ́n nítorí ọba,+ nítorí wọ́n rí i pé ọgbọ́n+ Ọlọ́run wà ní inú rẹ̀ láti mú ìpinnu ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé