Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 22:1-53

22  Wọ́n sì ń bá a lọ ní gbígbé fún ọdún mẹ́ta láìsí ogun láàárín Síríà àti Ísírẹ́lì.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹta pé Jèhóṣáfátì+ ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì.  Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ ní ti gidi pé tiwa ni Ramoti-gílíádì+ jẹ́? Síbẹ̀, àwa ń lọ́ tìkọ̀ láti gbà á lọ́wọ́ ọba Síríà.”  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ìwọ yóò ha bá mi lọ síbi ìjà ní Ramoti-gílíádì+ bí?” Látàrí èyí, Jèhóṣáfátì wí fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Èmi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Àwọn ènìyàn mi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ.+ Àwọn ẹṣin mi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹṣin rẹ.”  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhóṣáfátì ń bá a lọ láti sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, kọ́kọ́ wádìí+ nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà.”  Nítorí náà, ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọpọ̀,+ nǹkan bí irínwó ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé: “Ṣé kí n lọ bá Ramoti-gílíádì ja ogun, tàbí kí n fà sẹ́yìn?” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Gòkè lọ,+ Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”  Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì wí pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí mọ́ ni? Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a tipasẹ̀ rẹ̀ wádìí.”+  Látàrí ìyẹn, ọba Ísírẹ́lì wí fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà;+ ṣùgbọ́n èmi tìkára mi kórìíra rẹ̀+ dájúdájú, nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere nípa mi bí kò ṣe búburú+—Mikáyà ọmọkùnrin Ímílà ni.” Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhóṣáfátì wí pé: “Kí ọba má sọ ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba Ísírẹ́lì pe òṣìṣẹ́ kan láàfin,+ ó sì wí pé: “Mú Mikáyà ọmọkùnrin Ímílà wá kíákíá.”+ 10  Wàyí o, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà jókòó, olúkúlùkù lórí ìtẹ́ tirẹ̀, wọ́n wọ ẹ̀wù,+ ní ilẹ̀ ìpakà tí ó wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè Samáríà; gbogbo àwọn wòlíì sì ń ṣe bí wòlíì níwájú wọn.+ 11  Nígbà náà ni Sedekáyà ọmọkùnrin Kénáánà ṣe àwọn ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí,+ ‘Ìwọ̀nyí ni ìwọ yóò fi ti àwọn ará Síríà títí ìwọ yóò fi pa wọ́n run pátápátá.’”+ 12  Gbogbo àwọn wòlíì yòókù sì ń sọ tẹ́lẹ̀ bákan náà, pé: “Gòkè lọ sí Ramoti-gílíádì kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere; dájúdájú, Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”+ 13  Ońṣẹ́ tí ó lọ pe Mikáyà sì bá a sọ̀rọ̀ pé: “Wàyí o, wò ó! Ohun rere ni àwọn wòlíì ń sọ ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan fún ọba. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dà bí ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára tiwọn kí o sì sọ ohun rere.”+ 14  Ṣùgbọ́n Mikáyà wí pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ohun tí Jèhófà bá wí fún mi, ìyẹn ni ohun tí èmi yóò sọ.”+ 15  Nígbà náà ni ó wọlé tọ ọba lọ, ọba sì tẹ̀ síwájú láti wí fún un pé: “Mikáyà, ṣé kí a lọ sí Ramoti-gílíádì láti jagun tàbí kí a fà sẹ́yìn?” Lójú ẹsẹ̀, ó wí fún un pé: “Gòkè lọ kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere; dájúdájú, Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”+ 16  Látàrí ìyẹn, ọba wí fún un pé: “Ìgbà mélòó ni èmi yóò mú kí o wá sábẹ́ ìbúra pé kí o má sọ ohunkóhun fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Jèhófà?”+ 17  Nítorí náà, ó wí pé: “Dájúdájú, mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká+ lórí àwọn òkè ńlá, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ pé: ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá. Kí wọ́n padà, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”+ 18  Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì wí fún Jèhóṣáfátì pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé, ‘Kò ní sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere nípa mi, bí kò ṣe búburú’?”+ 19  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà:+ Dájúdájú, mo rí i tí Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, síhà ọ̀tún rẹ̀ àti òsì rẹ̀.+ 20  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù, kí ó lè gòkè lọ kí ó sì ṣubú ní Ramoti-gílíádì?’ Ẹni yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ báyìí, nígbà tí ẹni yẹn ń sọ báyẹn.+ 21  Níkẹyìn, ẹ̀mí+ kan jáde wá, ó sì dúró níwájú Jèhófà, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’ Látàrí ìyẹn, Jèhófà wí fún un pé, ‘Nípasẹ̀ kí ni?’+ 22  Ó fèsì pé, ‘Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí ìtannijẹ ní ẹnu gbogbo wòlíì rẹ̀ dájúdájú.’+ Nítorí náà, ó wí pé, ‘Ìwọ yóò tàn án, àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ yóò mókè.+ Jáde lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’+ 23  Wàyí o, kíyè sí i, Jèhófà ti fi ẹ̀mí ìtannijẹ sí ẹnu gbogbo wòlíì rẹ wọ̀nyí;+ ṣùgbọ́n Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ìyọnu àjálù nípa rẹ.”+ 24  Sedekáyà ọmọkùnrin Kénáánà sún mọ́ tòsí wàyí, ó sì gbá Mikáyà ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,+ ó sì wí pé: “Ọ̀nà wo gan-an ni ẹ̀mí Jèhófà gbà kọjá lọ lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”+ 25  Látàrí ìyẹn, Mikáyà wí pé: “Wò ó! Ìwọ yóò rí ọ̀nà náà ní ọjọ́ yẹn nígbà tí ìwọ yóò wọ ìyẹ̀wù inú pátápátá+ láti fi ara rẹ pa mọ́.”+ 26  Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì wí pé: “Mú Mikáyà kí o sì mú un padà lọ sọ́dọ̀ Ámọ́nì olórí ìlú ńlá àti sọ́dọ̀ Jóáṣì ọmọkùnrin ọba.+ 27  Kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba wí:+ “Ẹ fi àwé yìí sí àtìmọ́lé+ kí ẹ sì máa fi ìwọ̀n oúnjẹ+ tí a dín kù àti ìwọ̀n omi tí a dín kù bọ́ ọ, títí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.”’”+ 28  Látàrí èyíinì, Mikáyà wí pé: “Bí o bá padà dé rárá ní àlàáfíà, a jẹ́ pé Jèhófà kò bá mi sọ̀rọ̀.”+ Ó sì fi kún un pé: “Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.”+ 29  Ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 30  Wàyí o, ọba Ísírẹ́lì wí fún Jèhóṣáfátì pé: “Píparadà àti wíwọnú ìjà ogun+ yóò wà fún mi, ṣùgbọ́n ìwọ, ní tìrẹ, gbé ẹ̀wù+ rẹ wọ̀.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba Ísírẹ́lì para dà,+ ó sì wọnú ìjà ogun.+ 31  Ní ti ọba Síríà, ó ti pàṣẹ fún méjìlélọ́gbọ̀n olórí+ kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ó jẹ́ tirẹ̀, pé: “Kí ẹ má ṣe bá ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá jà, bí kò ṣe ọba Ísírẹ́lì nìkan.”+ 32  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, àwọn, ní tiwọn, wí fún ara wọn pé: “Dájúdájú, ọba Ísírẹ́lì+ ni.” Nítorí náà, wọ́n yíjú sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún ìrànlọ́wọ́.+ 33  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n padà lẹ́yìn rẹ̀.+ 34  Ọkùnrin kan sì wà tí ó fa ọrun ní àìpète, ṣùgbọ́n ó wá ba ọba Ísírẹ́lì láàárín àwọn àsokọ́ àti ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé:+ “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì gbé mi jáde kúrò nínú ibùdó, nítorí tí mo ti gbọgbẹ́ burúkú-burúkú.” 35  Ìjà ogun náà sì ń gbóná janjan sí i ní ọjọ́ yẹn, ṣe ni a sì mú kí ọba fúnra rẹ̀ wà ní ipò ìdúró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ní ìdojúkọ àwọn ará Síríà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú+ ní ìrọ̀lẹ́; ẹ̀jẹ̀ ọgbẹ́ náà sì ń dà jáde sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun náà.+ 36  Igbe ríró gbọnmọ-gbọnmọ sì bẹ̀rẹ̀ sí la ibùdó náà kọjá ní nǹkan bí ìgbà wíwọ̀ oòrùn, pé: “Kí olúkúlùkù lọ sí ìlú ńlá rẹ̀, àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!”+ 37  Bí ọba ṣe kú nìyẹn. Nígbà tí a gbé e wá sí Samáríà, wọ́n wá sin ọba sí Samáríà.+ 38  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun náà lẹ́bàá odò adágún Samáríà, àwọn ajá sì bẹ̀rẹ̀ sí lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀+ (àwọn kárùwà sì wẹ̀ níbẹ̀), gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó ti sọ.+ 39  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Áhábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti ilé eyín erin+ tí ó kọ́ àti gbogbo ìlú ńlá tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 40  Níkẹyìn, Áhábù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Ahasáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 41  Ní ti Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin Ásà, ó di ọba lórí Júdà ní ọdún kẹrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì. 42  Jèhóṣáfátì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù; orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà ọmọbìnrin Ṣílíháì. 43  Ó sì ń bá a nìṣó ní rírìn nínú gbogbo ọ̀nà Ásà baba rẹ̀. Kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, nípa ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.+ Kìkì pé àwọn ibi gíga kò di àwátì. Àwọn ènìyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ síbẹ̀ lórí àwọn ibi gíga.+ 44  Jèhóṣáfátì sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ọba Ísírẹ́lì.+ 45  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóṣáfátì àti agbára ńlá tí ó fi gbé ìgbésẹ̀ àti bí ó ṣe jagun, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? 46  Ìyókù àwọn kárùwà+ ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì tí a ṣẹ́ kù ní àwọn ọjọ́ Ásà baba rẹ̀ ni ó mú kúrò ní ilẹ̀ náà.+ 47  Ní ti ọba, kò sí ìkankan ní Édómù;+ ajẹ́lẹ̀ ni ọba.+ 48  Jèhóṣáfátì, ní tirẹ̀, ṣe àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ láti máa lọ sí Ófírì fún wúrà; ṣùgbọ́n wọn kò lọ, nítorí pé àwọn ọkọ̀ òkun náà fọ́ bàjẹ́ ní Esioni-gébérì.+ 49  Ìgbà náà ni Ahasáyà ọmọkùnrin Áhábù wí fún Jèhóṣáfátì pé: “Jẹ́ kì àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú àwọn ọkọ̀ òkun náà,” ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì kò gbà.+ 50  Níkẹyìn, Jèhóṣáfátì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ sí Ìlú Ńlá Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀; Jèhórámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 51  Ní ti Ahasáyà+ ọmọkùnrin Áhábù, ó di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún kẹtàdínlógún Jèhóṣáfátì ọba Júdà, ó sì ń bá a lọ láti jọba lórí Ísírẹ́lì fún ọdún méjì. 52  Ó sì ń ṣe ohun tí ó burú+ ṣáá ní ojú Jèhófà, ó sì ń rìn ní ọ̀nà baba rẹ̀+ àti ní ọ̀nà ìyá rẹ̀+ àti ní ọ̀nà Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, ẹni tí ó mú kí Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀.+ 53  Ó sì ń sin Báálì+ nìṣó, ó sì ń tẹrí ba fún un, ó sì ń bá a lọ láti mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti ṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé