Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 21:1-29

21  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí pé ọgbà àjàrà kan wà tí ó ṣẹlẹ̀ pé ó jẹ́ ti Nábótì ará Jésíréélì,+ tí ó wà ní Jésíréélì, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà.  Nítorí náà, Áhábù bá Nábótì sọ̀rọ̀ pé: “Fún+ mi ní ọgbà àjàrà+ rẹ, kí n lè fi í ṣe ọgbà+ ọ̀gbìn,+ nítorí pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé mi; sì jẹ́ kí n fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀. Tàbí, bí ó bá dára ní ojú+ rẹ, èmi yóò fún ọ ní owó gẹ́gẹ́ bí iye èyí.”  Ṣùgbọ́n Nábótì sọ fún Áhábù pé: “Kò ṣeé ronú kàn+ níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà,+ pé kí n fi ohun ìní àjogúnbá àwọn baba ńlá mi fún ọ.”+  Nítorí náà, Áhábù wá sínú ilé rẹ̀, ó wúgbọ, ó sì dorí kodò nítorí ọ̀rọ̀ tí Nábótì ará Jésíréélì bá a sọ, nígbà tí ó sọ pé: “Èmi kì yóò fún ọ ní ohun ìní àjogúnbá àwọn baba ńlá mi.” Ó wá dùbúlẹ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀, ó sì yí ojú padà,+ kò sì jẹ oúnjẹ.  Níkẹyìn, Jésíbẹ́lì+ aya rẹ̀ wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bá a sọ̀rọ̀ pé: “Èé ṣe tí ìbànújẹ́+ fi dé bá ẹ̀mí rẹ tí ìwọ kò sì jẹ oúnjẹ?”  Látàrí ìyẹn, ó bá a sọ̀rọ̀ pé: “Nítorí pé mo bẹ̀rẹ̀ sí bá Nábótì ará Jésíréélì sọ̀rọ̀, mo sì sọ fún un pé, ‘Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ fún owó. Tàbí, bí ó bá wù ọ́, jẹ́ kí n fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn dípò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó sọ pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’”+  Nígbà náà ni Jésíbẹ́lì aya rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ ní ń lo ipò ọba lórí Ísírẹ́lì+ nísinsìnyí? Dìde, jẹ oúnjẹ kí o sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣàríyá. Èmi fúnra mi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésíréélì.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó kọ àwọn lẹ́tà+ ní orúkọ Áhábù, ó sì fi èdìdì+ rẹ̀ dì wọ́n, ó sì fi àwọn lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbà ọkùnrin+ àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú tí wọ́n wà ní ìlú ńlá rẹ̀, tí wọ́n ń bá Nábótì gbé.  Ṣùgbọ́n ó kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé:+ “Ẹ pòkìkí ààwẹ̀, kí ẹ sì mú kí Nábótì jókòó sí ipò orí láàárín àwọn ènìyàn náà. 10  Kí ẹ sì mú kí ọkùnrin méjì,+ àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun,+ jókòó ní iwájú rẹ̀, ẹ sì jẹ́ kí wọ́n jẹ́rìí sí i+ pé, ‘O ti bú Ọlọ́run àti ọba!’+ Kí ẹ sì mú un jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta kí ó lè kú.”+ 11  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀, àwọn àgbà àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú tí ń gbé ìlú ńlá rẹ̀, ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésíbẹ́lì ti ránṣẹ́ sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí a tí kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà tí ó fi ránṣẹ́ sí wọn.+ 12  Wọ́n pòkìkí ààwẹ̀,+ wọ́n sì mú kí Nábótì jókòó sí ipò orí láàárín àwọn ènìyàn náà. 13  Nígbà náà ni méjì lára àwọn ọkùnrin náà, àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun, wọlé wá, wọ́n sì jókòó ní iwájú rẹ̀; àwọn ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí lòdì sí i, èyíinì ni, Nábótì, ní iwájú àwọn ènìyàn náà, pé: “Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba!”+ Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú ńlá náà, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú.+ 14  Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jésíbẹ́lì pé: “A ti sọ Nábótì lókùúta, ó sì ti kú.”+ 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé a ti sọ Nábótì lókùúta, tí ó sì ti kú, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésíbẹ́lì sọ fún Áhábù pé: “Dìde, gba ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésíréélì,+ tí ó kọ̀ láti fi fún ọ fún owó; nítorí Nábótì kò tún sí láàyè mọ́, ṣùgbọ́n ó ti kú.” 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Áhábù gbọ́ pé Nábótì ti kú, kíákíá, Áhábù dìde láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésíréélì, láti gbà á.+ 17  Ọ̀rọ̀ Jèhófà+ sì tọ Èlíjà+ ará Tíṣíbè wá pé: 18  “Dìde, sọ̀ kalẹ̀ lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó wà ní Samáríà.+ Òun nìyẹn níbi ọgbà àjàrà Nábótì, níbi tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ láti gbà á. 19  Kí o sì bá a sọ̀rọ̀ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ìwọ ha ti ṣìkà pànìyàn+ tí o sì ti gba ohun ìní+ pẹ̀lú?”’ Kí o sì bá a sọ̀rọ̀ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ibi tí+ àwọn ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá yóò ti lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ.”’”+ 20  Áhábù sì sọ fún Èlíjà pé: “O ha ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi?”+ ó dáhùn pé: “Mo ti wá ọ kàn. ‘Nítorí ìdí náà pé o ti ta ara rẹ láti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ 21  kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí rẹ;+ èmi yóò sì gbá ọ kúrò tefétefé,+ èmi yóò sì ké ẹnikẹ́ni tí ń tọ̀ sára ògiri+ àti aláìní olùrànlọ́wọ́ àti aláìníláárí ní Ísírẹ́lì kúrò lọ́dọ̀ Áhábù. 22  Dájúdájú, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọkùnrin Áhíjà, nítorí ohun ìbínú tí o fi fa ìbínú tí o sì wá mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’+ 23  Àti ní ti Jésíbẹ́lì pẹ̀lú, Jèhófà sọ̀rọ̀ pé, ‘Àwọn ajá ni yóò jẹ Jésíbẹ́lì ní abá ilẹ̀ Jésíréélì.+ 24  Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ti Áhábù tí ó bá kú ní ìlú ńlá, ni àwọn ajá yóò jẹ; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kú ní pápá, ni àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run yóò jẹ.+ 25  Láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí Áhábù,+ ẹni tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, ẹni tí Jésíbẹ́lì+ aya rẹ̀ ń kì láyà.+ 26  Ó sì ń hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí gidigidi nípa títọ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ lẹ́yìn,+ bákan náà bí gbogbo èyí tí àwọn Ámórì ṣe, àwọn tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+ 27  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Áhábù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbọn àwọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbààwẹ̀, ó sì ń dùbúlẹ̀ nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìsọ̀rètínù.+ 28  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ Èlíjà ará Tíṣíbè wá pé: 29  “Ìwọ ha ti rí bí Áhábù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ní tìtorí mi?+ Nítorí ìdí náà pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi, èmi kì yóò mú ìyọnu àjálù náà wá ní àwọn ọjọ́ rẹ̀.+ Àwọn ọjọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ ni èmi yóò mú ìyọnu àjálù náà wá sórí ilé rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé