Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 20:1-43

20  Ní ti Bẹni-hádádì+ ọba Síríà, ó kó gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ jọpọ̀, bákan náà, ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì wà pẹ̀lú rẹ̀+ àti àwọn ẹṣin+ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ, ó sì sàga+ ti Samáríà,+ ó sì bá a jà.  Nígbà náà ni ó rán àwọn ońṣẹ́+ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ní ìlú ńlá náà. Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Bẹni-hádádì wí,  ‘Fàdákà rẹ àti wúrà rẹ jẹ́ tèmi, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, tí ó dára jù lọ ní ìrísí, jẹ́ tèmi.’”+  Ọba Ísírẹ́lì fèsì, ó sì wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, olúwa mi ọba, tìrẹ ni èmi pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó jẹ́ tèmi.”+  Nígbà tí ó yá, àwọn ońṣẹ́ náà padà wá, wọ́n sì wí pé: “Èyí ni ohun tí Bẹni-hádádì wí, ‘Mo ránṣẹ́ sí ọ pé: “Fàdákà rẹ àti wúrà rẹ àti àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni kí o fi fún mi.  Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ, wọn yóò sì fẹ̀sọ̀ wá ilé rẹ àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ohun tí ó fani mọ́ra+ lójú rẹ ni wọn yóò kó sí ọwọ́ wọn, wọn yóò sì kó o lọ.”’”  Látàrí ìyẹn, ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà,+ ó sì wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣàkíyèsí, kí ẹ sì rí i pé ìyọnu àjálù ni ẹni yìí ń wá;+ nítorí tí ó ránṣẹ́ sí mi fún àwọn aya mi àti àwọn ọmọ mi àti fàdákà mi àti wúrà mi, èmi kò sì fawọ́ wọn sẹ́yìn fún un.”  Nígbà náà ni gbogbo àgbà ọkùnrin àti gbogbo ènìyàn náà sọ fún un pé: “Má ṣègbọràn, má sì gbà.”  Nítorí náà, ó sọ fún àwọn ońṣẹ́ Bẹni-hádádì pé: “Sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Gbogbo iṣẹ́ tí o kọ́kọ́ rán sí ìránṣẹ́ rẹ ni èmi yóò ṣe; ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò lè ṣe.’” Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ońṣẹ́ náà lọ, wọ́n sì mú ọ̀rọ̀ padà wá fún un. 10  Wàyí o, Bẹni-hádádì ránṣẹ́ sí i, ó sì wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́run+ ṣe sí mi, bẹ́ẹ̀ sì ni kí wọ́n fi kún un,+ bí ekuru Samáríà yóò bá tó ẹ̀kúnwọ́ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀ lé mi!”+ 11  Ẹ̀wẹ̀, ọba Ísírẹ́lì dáhùn, ó sì wí pé: “Ẹ sọ fún un pé, ‘Kí ẹni tí ń di àmùrè+ má ṣògo nípa ara rẹ̀ bí ẹni tí ń tú+ u kúrò.’” 12  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, bí òun fúnra rẹ̀ àti àwọn ọba ti ń mutí+ nínú àwọn àtíbàbà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbára dì!” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbára dì láti gbéjà ko ìlú ńlá náà. 13  Sì wò ó! wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá,+ ó sì wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí,+ ‘Ṣé o rí gbogbo ogunlọ́gọ̀ ńláǹlà yìí? Kíyè sí i, èmi yóò fi í lé ọ lọ́wọ́ lónìí, ìwọ yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.’”+ 14  Nígbà náà ni Áhábù sọ pé: “Nípasẹ̀ ta ni?” ó dáhùn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nípasẹ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ ni.’” Níkẹyìn, ó wí pé: “Ta ni yóò kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìjà ogun náà?” ó dáhùn pé: “Ìwọ ni!” 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ka iye àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ, wọ́n sì wá jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n;+ lẹ́yìn wọn, ó ka iye gbogbo ènìyàn náà, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin. 16  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ ní ọ̀sán gangan nígbà tí Bẹni-hádádì ń fi ọtí rọ ara rẹ̀ yó+ nínú àwọn àtíbàbà, òun àti àwọn ọba, àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n tí ń ràn án lọ́wọ́. 17  Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin+ àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ́kọ́ jáde wá, ní kíá, Bẹni-hádádì ránṣẹ́ jáde; wọ́n sì wá sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin kan wà tí wọ́n jáde wá láti Samáríà.” 18  Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ì báà jẹ́ nítorí àlàáfíà ni wọ́n fi jáde wá, ẹ gbá wọn mú láàyè; ì báà sì jẹ́ nítorí ìjà ogun ni wọ́n fi jáde wá, ààyè ni kí ẹ gbá wọn mú.”+ 19  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìlú ńlá náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ àti àwọn ẹgbẹ́ ológun tí ó wà lẹ́yìn wọn. 20  Olúkúlùkù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá ọkùnrin tirẹ̀ balẹ̀; àwọn ará Síríà+ sì fẹsẹ̀ fẹ,+ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn, ṣùgbọ́n Bẹni-hádádì ọba Síríà sá lọ lórí ẹṣin pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin. 21  Ṣùgbọ́n ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣá àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ balẹ̀, ó sì fi ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣá àwọn ará Síríà balẹ̀. 22  Nígbà tí ó yá, wòlíì+ náà tọ ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì sọ fún un pé: “Lọ, fún ara rẹ lókun+ kí o sì fiyè sí i, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe;+ nítorí nígbà ìyípo ọdún, ọba Síríà yóò gòkè wá gbéjà kò ọ́.”+ 23  Ní ti àwọn ìránṣẹ́ ọba Síríà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọlọ́run wọ́n jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè ńlá.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lágbára jù wá lọ. Nítorí náà, ní ọwọ́ kejì, jẹ́ kí a bá wọn jà lórí ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ kí a sì wò ó bóyá a kì yóò lágbára jù wọ́n lọ. 24  Sì ṣe nǹkan yìí: Mú àwọn ọba kúrò,+ olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi àwọn gómìnà dípò wọn.+ 25  Ní tìrẹ, kí o ka iye ẹgbẹ́ ológun fún ara rẹ, èyí tí ó jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun tí ó ṣubú níhà ọ̀dọ̀ tìrẹ, pẹ̀lú ẹṣin fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin; sì jẹ́ kí a bá wọn jà lórí ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ kí a sì wò ó bóyá a kì yóò lágbára jù wọ́n lọ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fetí sí ohùn wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. 26  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo ọdún pé Bẹni-hádádì bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn ará Síríà+ jọ, ó sì gòkè lọ sí Áfékì+ láti bá Ísírẹ́lì ja ìjà ogun. 27  Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a pè wọ́n jọ, a sì pèsè fún wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ láti pàdé wọn; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó sí iwájú wọn bí agbo ewúrẹ́ táṣẹ́rẹ́ méjì, nígbà tí àwọn ará Síríà, ní tiwọn, kún ilẹ̀.+ 28  Nígbà náà ni ènìyàn Ọlọ́run+ tòótọ́ sún mọ́ tòsí, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni, ó ń bá a lọ láti sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nítorí ìdí náà pé àwọn ará Síríà sọ pé: “Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè ńlá, kì í sì í ṣe Ọlọ́run pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀,” dájúdájú, èmi yóò fi gbogbo ogunlọ́gọ̀ ńláǹlà yìí lé ọ lọ́wọ́,+ ẹ ó sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.’”+ 29  Wọ́n sì ń bá a lọ láti wà ní ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn wọ̀nyí ní iwájú àwọn wọ̀nyẹn.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé ìjà ogun bẹ̀rẹ̀; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ará Síríà balẹ̀, ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn tí ń fẹsẹ̀ rìn, ní ọjọ́ kan. 30  Àwọn tí ó sì ṣẹ́ kù bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí Áfékì,+ sínú ìlú ńlá náà; ògiri sì wó lu ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáàrin ọkùnrin tí ó ṣẹ́ kù.+ Ní ti Bẹni-hádádì, ó sá lọ,+ níkẹyìn, ó sì wá sínú ìlú ńlá sínú ìyẹ̀wù inú pátápátá.+ 31  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé: “Wàyí o, kíyè sí i, àwa ti gbọ́ pé àwọn ọba ilé Ísírẹ́lì jẹ́ ọba tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+ Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a sán aṣọ àpò ìdọ̀họ+ mọ́ abẹ́nú+ wa, kí a sì fi ìjàrá sí orí wa, sí jẹ́ kí a jáde tọ ọba Ísírẹ́lì lọ. Bóyá yóò pa ọkàn rẹ mọ́ láàyè.”+ 32  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ abẹ́nú wọn, pẹ̀lú ìjàrá ní orí wọn, wọ́n sì wọlé tọ ọba Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì wí pé: “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọkàn mi yè.’” Ó fèsì pé: “Ṣé ó ṣì wà láàyè ni? Arákùnrin mi ni.” 33  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin náà+ kà á sí àmì ìṣẹ̀lẹ̀ kan, wọ́n sì yára gbà á gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí ó wá láti inú ìdánúṣe tirẹ̀, wọ́n sì ǹ bá a lọ láti sọ pé: “Arákùnrin rẹ ni Bẹni-hádádì.” Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ẹ wá, ẹ lọ mú un wá.” Nígbà náà ni Bẹni-hádádì jáde tọ̀ ọ́ lọ; lójú ẹsẹ̀, ó sì mú kí ó gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin.+ 34  Bẹni-hádádì wá sọ fún un pé: “Àwọn ìlú ńlá+ tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ ni èmi yóò dá padà; ìwọ yóò sì fún ara rẹ ní ojú pópó ní Damásíkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní Samáríà.” “Ní tèmi, lábẹ́ májẹ̀mú+ ni èmi ó sì fi rán ọ lọ.” Pẹ̀lú ìyẹn, ó bá a dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ. 35  Ọkùnrin kan lára àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀+ Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kọ̀ láti lù ú. 36  Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Nítorí ìdí náà pé o kò fetí sí ohùn Jèhófà, kíyè sí i, ìwọ ń lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, kìnnìún yóò sì ṣá ọ balẹ̀ dájúdájú.” Lẹ́yìn ìyẹn, ó lọ kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, kìnnìún+ sì wá rí i, ó sì ṣá a balẹ̀.+ 37  Ó sì wá rí ọkùnrin mìíràn, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Nítorí náà, ọkùnrin náà lù ú, ní lílù àti gbígbọgbẹ́. 38  Wòlíì náà wá lọ dúró jẹ́ẹ́ de ọba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà, ó sì para dà+ ní fífi ọ̀já tí a fi ń di ọgbẹ́ bo ojú. 39  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ọba ti ń kọjá lọ, ó ké sí ọba, ó sì tẹ̀ síwájú láti wí pé:+ “Ìránṣẹ́ rẹ jáde lọ sí ibi tí ìjà ogun ti kira; sì wò ó! ọkùnrin kan ń fi ojú ìlà ogun sílẹ̀, ó mú ọkùnrin kan tọ̀ mí wá, ó sì wá sọ pé, ‘Máa ṣọ́ ọkùnrin yìí. Bí ó bá di àwátì lọ́nàkọnà, ọkàn+ rẹ yóò ní láti dípò ọkàn+ tirẹ̀ pẹ̀lú, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tálẹ́ńtì fàdákà kan ni ìwọ yóò wọ̀n wá.’+ 40  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ìránṣẹ́ rẹ ti ń ṣe aápọn níhìn-ín àti lọ́hùn-ún, họ́wù, ó ti lọ.” Látàrí èyí, ọba Ísírẹ́lì wí fún un pé: “Bí ìdájọ́ rẹ ṣe jẹ́ nìyẹn. Ìwọ fúnra rẹ ti pinnu rẹ̀.”+ 41  Látàrí ìyẹn, ó mú ọ̀já tí a fi ń di ọgbẹ́ kúrò lójú ara rẹ̀ wéréwéré, ọba Ísírẹ́lì wá dá a mọ̀, pé ó wá láti inú àwọn wòlíì.+ 42  Wàyí o, ó sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nítorí ìdí náà pé o jẹ́ kí ọkùnrin tí a yà sọ́tọ̀ fún mi fún ìparun+ kí ó lọ kúrò lọ́wọ́ rẹ, ọkàn rẹ gbọ́dọ̀ dípò ọkàn+ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn rẹ dípò àwọn ènìyàn rẹ̀.’”+ 43  Látàrí ìyẹn, ọba Ísírẹ́lì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ síhà ilé rẹ̀, ó wúgbọ, ó sì dorí kodò,+ ó sì wá sí Samáríà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé