Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 2:1-46

2  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ tí Dáfídì yóò kú sún mọ́lé;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pàṣẹ fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ pé:  “Èmi ń lọ ní ọ̀nà gbogbo ilẹ̀ ayé,+ kí o jẹ́ alágbára,+ kí o sì fi ara rẹ hàn ní ọkùnrin.+  Kí o sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,+ nípa pípa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀, àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ àti àwọn gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a kọ sínú òfin Mósè,+ kí o bàa lè hùwà lọ́nà ìmòyemèrò nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe àti níbi gbogbo tí o bá yíjú sí;  kí Jèhófà bàa lè mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sọ nípa mi+ ṣẹ, pé, ‘Bí àwọn ọmọ+ rẹ yóò bá kíyè sí ọ̀nà wọn, nípa rírìn+ níwájú mi ní òtítọ́+ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà+ wọn àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, a kì yóò ké ọkùnrin rẹ kan kúrò láti máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+  “Ìwọ fúnra rẹ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà ṣe sí mi+ ní àmọ̀dunjú, ní ti ohun tí ó ṣe sí olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì méjì, sí Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì àti Ámásà+ ọmọkùnrin Jétà,+ nígbà tí ó pa wọ́n, tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀+ ogun sílẹ̀ nígbà àlàáfíà, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ogun sára ìgbànú rẹ̀ tí ó yí ìgbáròkó rẹ̀ ká àti sínú sálúbàtà rẹ̀ tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀.  Kí o sì gbé ìgbésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ,+ má sì ṣe jẹ́ kí ewú rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù+ ní àlàáfíà.+  “Àwọn ọmọ Básíláì+ ọmọ Gílíádì sì ni kí o ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí, kí wọ́n sì jẹ́ ara àwọn tí ń jẹun lórí tábìlì rẹ;+ nítorí bí wọ́n ṣe sún mọ́+ mi nìyẹn nígbà tí mo fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú Ábúsálómù arákùnrin rẹ.+  “Ṣíméì+ ọmọkùnrin Gérà ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Báhúrímù+ sì wà pẹ̀lú rẹ níhìn-ín, òun sì ni ó pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí mi pẹ̀lú ìfiré+ ríroni lára ní ọjọ́ tí mo ń lọ sí Máhánáímù;+ òun sì ni ó sọ̀ kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jọ́dánì,+ tí mo fi fi Jèhófà búra fún un pé, ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’+  Wàyí o, má ṣàìfi ìyà jẹ+ ẹ́, nítorí ọlọ́gbọ́n+ ọkùnrin ni ọ́, o sì mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe sí i ní àmọ̀dunjú, kí o sì mú kí ewú+ rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”+ 10  Lẹ́yìn náà, Dáfídì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì.+ 11  Àwọn ọjọ́ tí Dáfídì sì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì ọdún.+ Ní Hébúrónì,+ ó jọba fún ọdún méje,+ àti ní Jerúsálẹ́mù, ó jọba fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.+ 12  Ní ti Sólómọ́nì, ó jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀;+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ipò ọba rẹ̀ sì di èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọ-in+ gan-an. 13  Nígbà tí ó ṣe, Ádóníjà ọmọkùnrin Hágítì tọ Bátí-ṣébà,+ ìyá Sólómọ́nì wá. Látàrí èyí, ó sọ pé: “Ṣé ti ẹ̀mí àlàáfíà ní o bá wá o?”+ ó dáhùn pé: “Ti ẹ̀mí àlàáfíà ni.” 14  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ọ̀ràn kan wà tí mo ní láti bá ọ sọ.” Nítorí náà, ó wí pé: “Sọ ọ́.”+ 15  Ó sì ń bá a lọ pé: “Ìwọ alára mọ̀ dunjú pé ipò ọba ì bá ti jẹ́ tèmi, ìhà ọ̀dọ̀ mi sì ni gbogbo Ísírẹ́lì fi ojú wọn sí pé kí n di ọba;+ ṣùgbọ́n ipò ọba yí padà, ó sì wá jẹ́ ti arákùnrin mi, nítorí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ó ti di tirẹ̀.+ 16  Wàyí o, ìbéèrè kan wà tí mo fẹ́ ṣe ní ọ̀dọ̀ rẹ. Má ṣe yí ojú mi kúrò.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí fún un pé: “Sọ ọ́.” 17  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún Sólómọ́nì ọba (nítorí òun kì yóò yí ojú rẹ kúrò) pé kí ó fi Ábíṣágì+ ará Ṣúnẹ́mù+ fún mi gẹ́gẹ́ bí aya.” 18  Bátí-ṣébà fèsì pé: “Ó dára! Èmi fúnra mi yóò bá ọ sọ fún ọba.” 19  Nítorí náà, Bátí-ṣébà wọlé lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì Ọba láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Ádóníjà.+ Kíákíá ni ọba dìde+ láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹrí ba fún un.+ Lẹ́yìn náà, ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì mú kí a gbé ìtẹ́ kan kalẹ̀ fún ìyá ọba, kí ó lè jókòó sí ọ̀tún rẹ̀.+ 20  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ìbéèrè kékeré kan wà tí mo fẹ́ ṣe ní ọ̀dọ̀ rẹ. Má ṣe yí ojú mi kúrò.” Nítorí náà, ọba wí fún un pé: “Béèrè, ìyá mi; nítorí èmi kì yóò yí ojú rẹ kúrò.” 21  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Jẹ́ kí a fi Ábíṣágì ará Ṣúnẹ́mù fún Ádóníjà arákùnrin rẹ gẹ́gẹ́ bí aya.” 22  Látàrí èyí, Sólómọ́nì Ọba dáhùn, ó sì wí fún ìyá rẹ̀ pé: “Èé sì ti ṣe tí o fi ń béèrè Ábíṣágì ará Ṣúnẹ́mù fún Ádóníjà? Béèrè ipò ọba+ fún un pẹ̀lú (nítorí pé arákùnrin mi tí ó dàgbà jù mí lọ ni),+ àní fún un àti fún Ábíátárì+ àlùfáà àti Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà.”+ 23  Látàrí ìyẹn, Sólómọ́nì Ọba fi Jèhófà búra, pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ṣe sí mi, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ó fi kún un,+ bí kì í bá ṣe ní ìlòdìsí ọkàn ara rẹ̀ ni Ádóníjà sọ ohun yìí.+ 24  Wàyí o, bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ẹni tí ó fìdí mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,+ tí ó sì mú mi jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì baba mi,+ ẹni tí ó sì ṣe ilé+ kan fún mi gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ,+ òní ni a ó fi ikú pa+ Ádóníjà.” 25  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Sólómọ́nì Ọba ránṣẹ́ nípasẹ̀ Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà; ó sì rọ́ lù ú, tí ó sì kú.+ 26  Àti fún Ábíátárì+ àlùfáà, ọba wí pé: “Máa lọ sí Ánátótì,+ sí pápá rẹ! Nítorí ikú tọ́ sí ọ;+ ṣùgbọ́n èmi kì yóò fi ikú pa ọ́ ní òní yìí, nítorí tí ìwọ ru àpótí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ+ níwájú Dáfídì baba mi,+ àti nítorí tí ìwọ rí ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ ní gbogbo àkókò tí baba mi rí ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́.”+ 27  Nítorí náà, Sólómọ́nì lé Ábíátárì kúrò nínú ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Jèhófà, láti mú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó ti sọ lòdì sí ilé Élì+ ní Ṣílò+ ṣẹ. 28  Ìròyìn náà sì lọ títí dé ọ̀dọ Jóábù+—nítorí Jóábù alára tẹ̀ síhà títọ Ádóníjà+ lẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tẹ̀ síhà títọ Ábúsálómù lẹ́yìn+—Jóábù sì sá lọ sínú àgọ́+ Jèhófà, ó sì wá di àwọn ìwo pẹpẹ mú ṣinṣin.+ 29  Nígbà náà ni a sọ fún Sólómọ́nì Ọba pé: “Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Jèhófà, ó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ níbẹ̀.” Nítorí náà, Sólómọ́nì rán Bẹnáyà ọmọkùnrin Jéhóádà, pé: “Lọ, rọ́ lù ú!”+ 30  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bẹnáyà wá sínú àgọ́ Jèhófà, ó sí wí fún un pé: “Báyìí ni ọba wí, ‘Jáde wá!’” Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Rárá! Nítorí ìhín+ ni ibi tí èmi yóò kú sí.” Látàrí ìyẹn, Bẹnáyà mú ọ̀rọ̀ padà wá fún ọba, pé: “Ohun tí Jóábù sọ rèé, ohun tí ó sì fi dá mi lóhùn rèé.” 31  Nígbà náà ni ọba sọ fún un pé: “Ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, kí o sì rọ́ lù ú; kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀+ tí a ta sílẹ̀ láìyẹ, èyí tí Jóábù ta sílẹ̀,+ kúrò lọ́rùn mi àti kúrò lọ́rùn ilé baba mi. 32  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ padà wá sórí òun fúnra rẹ̀,+ nítorí tí ó rọ́ lu ọkùnrin méjì tí ó ṣe olódodo tí ó sì sàn jù ú lọ,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti fi idà pa wọ́n, nígbà tí Dáfídì baba mi alára kò mọ̀ nípa rẹ̀,+ èyíinì ni, Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì+ àti Ámásà+ ọmọkùnrin Jétà, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Júdà.+ 33  Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì padà wá sí orí Jóábù àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ ṣùgbọ́n fún Dáfídì+ àti fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún ilé rẹ̀ àti fún ìtẹ́ rẹ̀, àlàáfíà yóò wà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 34  Nígbà náà ni Bẹnáyà ọmọkùnrin Jéhóádà gòkè lọ,+ ó sì rọ́ lù ú, ó sì fi ikú pa á;+ a sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní aginjù. 35  Látàrí ìyẹn, ọba fi Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà sórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ ní ipò rẹ̀; Sádókù àlùfáà ni ọba sì fi sí ipò Ábíátárì.+ 36  Níkẹyìn, ọba ránṣẹ́ pe Ṣíméì,+ ó sì sọ fún un pé: “Kọ́ ilé kan fún ara rẹ ní Jerúsálẹ́mù, ibẹ̀ sì ni kí o máa gbé, kí o má sì jáde kúrò níbẹ̀ sí ìhín tàbí ọ̀hún. 37  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ tí o bá jáde lọ, nígbà tí o bá sì ré kọjá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì,+ kí o mọ̀ láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, pé ìwọ yóò kú dájúdájú.+ Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wá wà ni orí ìwọ fúnra rẹ.”+ 38  Látàrí èyí, Ṣíméì sọ fún ọba pé: “Ọ̀rọ̀ náà dára. Gan-an gẹ́gẹ́ bí olúwa mi ọba ṣe sọ, bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe.” Ṣíméì sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ púpọ̀. 39  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin ọdún mẹ́ta pé ẹrú+ Ṣíméì méjì fẹsẹ̀ fẹ lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì+ ọmọkùnrin Máákà ọba Gátì;+ àwọn ènìyàn sì wá sọ fún Ṣíméì pé: “Wò ó! Àwọn ẹrú rẹ wà ní Gátì.” 40  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ṣíméì dìde, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sí Gátì sọ́dọ̀ Ákíṣì láti wá àwọn ẹrú rẹ̀; lẹ́yìn èyí tí Ṣíméì lọ mú àwọn ẹrú rẹ̀ wá láti Gátì. 41  Nígbà náà ni a sọ fún Sólómọ́nì pé: “Ṣíméì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Gátì ó sì ti padà.” 42  Látàrí ìyẹn, ọba ránṣẹ́ pe+ Ṣíméì, ó sì sọ fún un pé: “Èmi kò ha fi Jèhófà mú kí o wá sábẹ́ ìbúra, kí n lè kìlọ̀ fún ọ,+ pé, ‘Ọjọ́ tí o bá jáde síta, tí o bá sì lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún, kí o mọ̀ láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, pé ìwọ yóò kú dájúdájú,’ ìwọ kò ha sì wí fún mi pé, ‘Ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ dára’?+ 43  Kí wá ni ìdí rẹ̀ tí ìwọ kò fi pa ìbúra Jèhófà+ mọ́ àti àṣẹ tí mo fi ìrònújinlẹ̀ gbé kalẹ̀ fún ọ?”+ 44  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún Ṣíméì pé: “Dájúdájú, ìwọ fúnra rẹ mọ gbogbo ìṣeléṣe tí ọkàn-àyà rẹ mọ̀ dunjú pé o ṣe sí Dáfídì baba mi;+ dájúdájú, Jèhófà yóò sì dá ìṣeléṣe tí o ṣe padà sórí ìwọ fúnra rẹ.+ 45  Ṣùgbọ́n Sólómọ́nì Ọba ni a ó bù kún,+ ìtẹ́ Dáfídì alára yóò sì jẹ́ èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú Jèhófà títí láé.”+ 46  Pẹ̀lú ìyẹn, ọba pàṣẹ fún Bẹnáyà ọmọkùnrin Jéhóádà, ẹni tí ó wá jáde lọ tí ó sì rọ́ lù ú, tí ó fi kú.+ A sì fìdí ìjọba náà múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọwọ́ Sólómọ́nì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé