Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 19:1-21

19  Nígbà náà ni Áhábù+ sọ fún Jésíbẹ́lì+ nípa gbogbo ohun tí Èlíjà ṣe àti gbogbo bí ó ṣe fi idà pa gbogbo wòlíì.+  Látàrí ìyẹn, Jésíbẹ́lì rán ońṣẹ́ sí Èlíjà pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́run ṣe,+ bẹ́ẹ̀ sì ni kí wọ́n fi kún un,+ bí èmi kò bá ni ṣe ọkàn rẹ bí ọkàn olúkúlùkù wọn ní ìwòyí ọ̀la!”  Àyà sì bẹ̀rẹ̀ sí fò ó. Nítorí náà, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ nítorí ọkàn+ rẹ̀, ó sì wá sí Bíá-ṣébà,+ èyí tí ó jẹ́ ti Júdà.+ Ó wá fi ẹmẹ̀wà rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀.  Òun alára sì lọ sí aginjù ní ìrìn àjò ọjọ́ kan, àti níkẹyìn, ó wá, ó sì jókòó sábẹ́ igi wíwẹ́+ kan. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé kí ọkàn òun kú, ó sì wí pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò,+ nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.”  Níkẹyìn, ó dùbúlẹ̀, ó sì sùn lọ lábẹ́ igi wíwẹ́+ náà. Ṣùgbọ́n, wò ó! áńgẹ́lì+ kan ń fọwọ́ kàn+ án nísinsìnyí. Nígbà náà ni ó sọ fún un pé: “Dìde, jẹun.”  Nígbà tí ó wò, họ́wù, ní ibi orí rẹ̀ níbẹ̀ ni àkàrà ribiti+ kan wà lórí àwọn òkúta gbígbóná àti ìdẹ̀ omi. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, ó sì mu, lẹ́yìn èyí tí ó tún dùbúlẹ̀.  Nígbà tí ó yá, áńgẹ́lì+ Jèhófà padà wá nígbà kejì, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì sọ pé: “Dìde, jẹun, nítorí ìrìn àjò náà pọ̀ jù fún ọ.”+  Nítorí náà, ó dìde, ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì ń lọ nípasẹ̀ agbára oúnjẹ yẹn fún ogójì ọ̀sán+ àti ogójì òru, títí dé Hórébù,+ òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.  Ibẹ̀ ni ó ti wọnú hòrò+ kan níkẹyìn, kí ó lè sun ibẹ̀ mọ́jú; sì wò ó! ọ̀rọ̀ Jèhófà wà fún un, ó sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Kí ni iṣẹ́ rẹ níhìn-ín, Èlíjà?”+ 10  Ó fèsì pé: “Ní jíjowú, mo ti ń jowú+ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun; nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi májẹ̀mú+ rẹ sílẹ̀, àwọn pẹpẹ rẹ ni wọ́n ti ya lulẹ̀,+ àwọn wòlíì rẹ sì ni wọ́n ti fi idà pa,+ tí ó fi jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọkàn mi láti gbà á kúrò.”+ 11  Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Jáde, kí o sì dúró lórí òkè ńlá níwájú Jèhófà.”+ Sì wò ó! Jèhófà ń kọjá lọ,+ ẹ̀fúùfù ńláǹlà tí ó sì le ń ya àwọn òkè ńlá, ó sì ń fọ́ àwọn àpáta gàǹgà níwájú Jèhófà.+ (Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù náà.) Àti lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìmìtìtì wáyé.+ (Jèhófà kò sí nínú ìmìtìtì náà.) 12  Àti lẹ́yìn ìmìtìtì náà, iná wáyé.+ (Jèhófà kò sí nínú iná náà.) Àti lẹ́yìn iná náà, ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀ dún.+ 13  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Èlíjà gbọ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó fi ẹ̀wù oyè+ rẹ̀ wé ojú, ó sì jáde, ó sì dúró sí ẹnu ọ̀nà hòrò náà; sì wò ó! ohùn kan wà fún un, ó sì wí fún un pé: “Kí ni iṣẹ́ rẹ níhìn-ín, Èlíjà?”+ 14  Ó fèsì pé: “Ní jíjowú, mo ti ń jowú fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun; nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi májẹ̀mú+ rẹ sílẹ̀, àwọn pẹpẹ rẹ ni wọ́n ti ya lulẹ̀, àwọn wòlíì rẹ ni wọ́n sì ti fi idà pa, tí ó fi jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọkàn mi láti gbà á kúrò.”+ 15  Wàyí o, Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ, bá ọ̀nà rẹ padà sí aginjù Damásíkù;+ kí o sì wọlé, kí o sì fòróró yan+ Hásáélì+ ṣe ọba lórí Síríà. 16  Jéhù+ ọmọ-ọmọ Nímúṣì+ ni kí o sì fòróró yàn ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì; Èlíṣà+ ọmọkùnrin Ṣáfátì láti Ebẹli-méhólà+ ni kí o sì fòróró yàn ṣe wòlíì ní ipò rẹ.+ 17  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ẹni tí ó bá yè bọ́ lọ́wọ́ idà+ Hásáélì, ni Jéhù yóò fi ikú pa;+ ẹni tí ó bá sì yè bọ́ lọ́wọ́ idà Jéhù, ni Èlíṣà yóò fi ikú pa.+ 18  Mo sì ti jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ní Ísírẹ́lì,+ gbogbo eékún tí kò tẹ̀ ba fún Báálì,+ àti olúkúlùkù ẹnu tí kò fi ẹnu kò ó lẹ́nu.”+ 19  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó lọ láti ibẹ̀, ó sì rí Èlíṣà ọmọkùnrin Ṣáfátì bí ó ti ń fi àdìpọ̀ ẹran méjì-méjì lọ́nà méjìlá túlẹ̀+ níwájú rẹ̀, ó sì wà pẹ̀lú ìkejìlá. Nítorí náà, Èlíjà sọdá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ju ẹ̀wù oyè+ rẹ̀ sára rẹ̀. 20  Látàrí ìyẹn, ó fi àwọn akọ màlúù náà sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré tẹ̀ lé Èlíjà, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ń fi ẹnu ko baba àti ìyá mi lẹ́nu.+ Lẹ́yìn náà, èmi yóò máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn dájúdájú.” Látàrí èyí, ó sọ fún un pé: “Máa lọ, padà; nítorí kí ni mo fi ṣe ọ́?” 21  Nítorí náà, ó padà kúrò ní títọ̀ ọ́ lẹ́yìn, lẹ́yìn náà, ó mú àdìpọ̀ akọ màlúù méjì, ó sì fi wọ́n rúbọ,+ ó sì fi àwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́+ àwọn akọ màlúù náà se ẹran wọn, ó sì fi í fún àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ. Lẹ́yìn ìyẹn, ó dìde, ó sì ń tọ Èlíjà lẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́+ fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé