Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 18:1-46

18  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́+ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Èlíjà wá ní ọdún kẹta, pé: “Lọ, fi ara rẹ han Áhábù, níwọ̀n bí mo ti pinnu láti rọ òjò sórí ilẹ̀.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Èlíjà lọ fi ara rẹ̀ han Áhábù, nígbà tí ìyàn náà ṣì mú gidigidi+ ní Samáríà.  Láàárín àkókò náà, Áhábù pe Ọbadáyà, ẹni tí ó wà lórí agbo ilé.+ (Wàyí o, Ọbadáyà alára jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù+ Jèhófà gidigidi.  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jésíbẹ́lì+ ké àwọn wòlíì Jèhófà+ kúrò, Ọbadáyà bẹ̀rẹ̀ sí kó ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pa mọ́ ní àádọ́ta-àádọ́ta nínú hòrò kan, ó sì ń pèsè oúnjẹ àti omi fún wọn.)+  Áhábù sì ń bá a lọ láti sọ fún Ọbadáyà pé: “Rin ilẹ̀ yìí já, sí gbogbo ìsun omi àti sí gbogbo àfonífojì olójú ọ̀gbàrá. Bóyá a lè rí koríko tútù,+ kí a lè pa àwọn ẹṣin àti ìbaaka mọ́ láàyè kí èyíkéyìí lára àwọn ẹranko náà má sì di èyí tí a ké kúrò+ mọ́.”  Nítorí náà, wọ́n pín ilẹ̀ tí wọn yóò là kọjá láàárín ara wọn. Áhábù nìkan gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadáyà sì nìkan gba ọ̀nà mìíràn lọ.+  Bí Ọbadáyà ti ń lọ lójú ọ̀nà, họ́wù, Èlíjà rèé tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀.+ Kíákíá ni ó dá a mọ̀, ó sì dojú bolẹ̀,+ ó sì wí pé: “Ṣé ìwọ rèé, olúwa+ mi Èlíjà?”  Látàrí èyí, ó sọ fún un pé: “Èmi ni. Lọ, sọ fún olúwa+ rẹ pé, ‘Èlíjà wà níhìn-ín.’”  Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀+ wo ni mo dá tí ìwọ yóò fi fi ìránṣẹ́ rẹ lé ọwọ́ Áhábù láti fi ikú pa mí? 10  Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ,+ kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba tí olúwa mi kò tíì ránṣẹ́ wá ọ dé. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sọ pé, ‘Kò sí níhìn-ín,’ òun a mú kí ìjọba náà àti orílẹ̀-èdè náà búra pé wọn kò rí ọ.+ 11  Wàyí o, o ń sọ pé, ‘Lọ, sọ fún olúwa rẹ pé: “Èlíjà wà níhìn-ín.”’ 12  Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí mo bá lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà náà ni ẹ̀mí+ Jèhófà yóò gbé ọ lọ sí ibi tí èmi kò ní mọ̀; èmi yóò sì ti wá sọ fún Áhábù, kò sì ní rí ọ, yóò sì pa+ mí dájúdájú, níwọ̀n bí ìránṣẹ́ rẹ ti bẹ̀rù Jèhófà láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.+ 13  Ṣé a kò tíì sọ ohun tí mo ṣe fún olúwa mi ni, nígbà tí Jésíbẹ́lì pa àwọn wòlíì Jèhófà, bí mo ṣe kó lára àwọn wòlíì Jèhófà pa mọ́, ọgọ́rùn-ún ọkùnrin, ní àádọ́ta-àádọ́ta nínú hòrò kan,+ tí mo sì ń pèsè oúnjẹ àti omi+ fún wọn? 14  Wàyí o, ìwọ ń wí pé, ‘Lọ, sọ fún olúwa rẹ pé: “Èlíjà wà níhìn-ín.”’ Yóò sì pa+ mí dájúdájú.” 15  Bí ó ti wù kí ó rí, Èlíjà sọ pé: “Bí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ níwájú ẹni tí mo dúró sí, ti ń bẹ,+ òní ni èmi yóò fi ara mi hàn án.” 16  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọbadáyà lọ pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un; nítorí náà, Áhábù lọ pàdé Èlíjà. 17  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Áhábù rí Èlíjà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áhábù sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ rèé, ẹni tí ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí Ísírẹ́lì?”+ 18  Ó fèsì pé: “Èmi kò mú ìtanùlẹ́gbẹ́+ wá sórí Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé baba rẹ ni ó ṣe bẹ́ẹ̀,+ nítorí tí ẹ ti fi àwọn àṣẹ Jèhófà+ sílẹ̀, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ àwọn Báálì lẹ́yìn.+ 19  Wàyí o, ránṣẹ́, kí o sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọpọ̀ sọ́dọ̀ mi lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì,+ àti àádọ́ta-lé-nírínwó wòlíì Báálì+ pẹ̀lú, àti irínwó wòlíì òpó ọlọ́wọ̀,+ tí ń jẹun lórí tábìlì Jésíbẹ́lì.”+ 20  Áhábù sì ránṣẹ́ sí àárín gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì+ jọpọ̀ sórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì. 21  Nígbà náà ni Èlíjà tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà wá, ó sì wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì+ tí ó yàtọ̀ síra? Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn;+ ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Àwọn ènìyàn náà kò sì sọ ọ̀rọ̀ kankan láti fi dá a lóhùn. 22  Èlíjà sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Èmi ni a ṣẹ́ kù nínú wòlíì Jèhófà,+ èmi nìkan ṣoṣo, nígbà tí àwọn wòlíì Báálì jẹ́ àádọ́ta-lé-nírínwó ọkùnrin. 23  Wàyí o, kí wọ́n fún wa ní ẹgbọrọ akọ màlúù méjì, kí wọ́n sì yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọ́n sì gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọ́n sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi alára yóò sì ṣètò ẹgbọrọ akọ màlúù kejì, èmi yóò sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n èmi kì yóò fi iná sí i. 24  Kí ẹ sì ké pe orúkọ ọlọ́run yín,+ èmi, ní tèmi, yóò sì ké pe orúkọ Jèhófà; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ tí ó bá fi iná+ dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.”+ Gbogbo àwọn ènìyàn náà fèsì, wọ́n sì wí pé: “Ìyẹn dára.” 25  Èlíjà wá sọ fún àwọn wòlíì Báálì pé: “Ẹ yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara yín kí ẹ sì kọ́kọ́ ṣètò rẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin ni ó pọ̀ jù; kí ẹ sì ké pe orúkọ ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n kí ẹ má fi iná sí i.” 26  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n mú ẹgbọrọ akọ màlúù tí ó fún wọn. Nígbà náà ni wọ́n ṣètò rẹ̀, wọ́n sì ń ké pe orúkọ Báálì ṣáá láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan, pé: “Báálì, dá wa lóhùn!” Ṣùgbọ́n kò sí ohùn kankan,+ kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn.+ Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní títiro yí ká pẹpẹ tí wọ́n ṣe. 27  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọ̀sán gangan pé Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà+ pé: “Ẹ ké ní bí ohùn yín ṣe lè ròkè tó, nítorí ọlọ́run+ ni; nítorí, ó ní láti jẹ́ pé ó ń dàníyàn nípa ọ̀ràn kan ni, ó sì fẹ́ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀+ tí ó fi ní láti lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀.+ Tàbí kẹ̀, bóyá ó ń sùn ni, ó sì yẹ kí ó jí!”+ 28  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké ní bí ohùn wọn ṣe lè ròkè tó, wọ́n sì ń fi ọ̀bẹ aláṣóró àti aṣóró gé ara wọn+ gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, títí wọ́n fi mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn jáde lára wọn. 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọ̀sán gangan ti kọjá, tí wọ́n sì ń bá a lọ ní híhùwà bí wòlíì+ títí di ìgbà ìgòkè lọ ọrẹ ẹbọ ọkà, kò sí ohùn kankan, kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn, kò sì sí fífetísílẹ̀.+ 30  Níkẹyìn, Èlíjà sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ sún mọ́ mi.” Nítorí náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà sún mọ́ ọn. Nígbà náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àtúnṣe pẹpẹ Jèhófà tí a ya lulẹ̀.+ 31  Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà kó òkúta méjìlá, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Jékọ́bù, ẹni tí ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ wá+ pé: “Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ yóò dà.”+ 32  Ó sì ń bá a lọ láti fi àwọn òkúta náà mọ pẹpẹ+ kan ní orúkọ Jèhófà,+ ó sì wa yàrà kan, èyí tí ó tó àgbègbè tí a máa fún irúgbìn òṣùwọ̀n séà méjì sí, yí pẹpẹ náà ká. 33  Lẹ́yìn ìyẹn, ó to àwọn igi,+ ó sì gé ẹgbọrọ akọ màlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì kó o sórí àwọn igi náà. Ó wá sọ pé: “Ẹ pọn omi kún ìṣà títóbi mẹ́rin, kí ẹ sì dà á sórí ọrẹ ẹbọ sísun náà àti sórí àwọn igi náà.” 34  Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ẹ ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.” Nítorí náà, wọ́n ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ẹ ṣe é nígbà kẹta.” Nítorí náà, wọ́n ṣe é nígbà kẹta. 35  Bí omi ṣe yí pẹpẹ náà ká nìyẹn, ó sì pọn omi kún yàrà náà pẹ̀lú. 36  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ìgbà+ tí ọrẹ ẹbọ ọkà máa ń lọ sókè pé, Èlíjà wòlíì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ tòsí, ó sì sọ pé: “Ìwọ Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ísáákì+ àti Ísírẹ́lì,+ jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì,+ àti pé èmi jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ, àti pé nípa ọ̀rọ̀+ rẹ ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 37  Dá mi lóhùn, Jèhófà, dá mi lóhùn, kí àwọn ènìyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà,+ ni Ọlọ́run tòótọ́, àti pé ìwọ fúnra rẹ ti yí ọkàn-àyà wọn padà.”+ 38  Látàrí ìyẹn, iná+ Jèhófà já bọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọrẹ ẹbọ sísun+ náà àti àwọn igi àti àwọn òkúta àti ekuru náà ní àjẹtán, ó sì lá omi tí ó wà nínú yàrà náà láú.+ 39  Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn náà rí i, wọ́n dojú bolẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,+ wọ́n sì wí pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” 40  Nígbà náà ni Èlíjà sọ fún wọn pé: “Ẹ gbá àwọn wòlíì Báálì mú! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹyọ kan lára wọn sá lọ!” Ní kíá, wọ́n gbá wọn mú, Èlíjà wá mú wọn sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀.+ 41  Wàyí o, Èlíjà sọ fún Áhábù pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu;+ nítorí ìró ìkùrìrì eji wọwọ+ ń bẹ.” 42  Áhábù sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ní ti Èlíjà, ó gòkè lọ sí orí Kámẹ́lì, ó sì ń bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀,+ ó sì ń gbé ojú sáàárín eékún rẹ̀.+ 43  Nígbà náà ni ó sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gòkè lọ. Wo ìhà òkun.” Nítorí náà, ó gòkè lọ, ó sì wò ó, ó sì wá sọ pé: “Kò sí nǹkan kan rárá.” Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé, “Padà lọ,” fún ìgbà méje.+ 44  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ìgbà keje pé, ó sọ pé: “Wò ó! Àwọsánmà kékeré kan bí àtẹ́lẹwọ́ ènìyàn ń gòkè bọ̀ láti inú òkun.”+ Wàyí o, ó sọ pé: “Gòkè lọ, sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ̀kẹ́!+ Kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ kí eji wọwọ má bàa dá ọ dúró!’” 45  Ó sì ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò náà pé àwọsánmà àti ẹ̀fúùfù+ mú ojú ọ̀run ṣókùnkùn, eji wọwọ ńláǹlà sì bẹ̀rẹ̀.+ Áhábù sì ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, ó sì wá sí Jésíréélì.+ 46  Ọwọ́ Jèhófà sì wà lára Èlíjà,+ bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìgbáròkó rẹ̀ lámùrè,+ ó sì ń sáré lọ níwájú Áhábù dé iyàn-níyàn Jésíréélì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé