Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 17:1-24

17  Èlíjà+ ará Tíṣíbè láti inú àwọn olùgbé Gílíádì+ sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Áhábù pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti ń bẹ,+ níwájú ẹni tí èmi dúró,+ kì yóò sí ìrì tàbí òjò+ ní ọdún wọ̀nyí, bí kò ṣe nípa àṣẹ ọ̀rọ̀ mi!”+  Wàyí o, ọ̀rọ̀+ Jèhófà tọ̀ ọ́ wá, pé:  “Kúrò níhìn-ín, kí ó sì gba ọ̀nà ìhà ìlà-oòrùn lọ, kí o sì fi ara rẹ pa mọ́+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kẹ́rítì tí ó wà ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì.  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé láti inú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ni kí ìwọ ti máa mu omi,+ dájúdájú, àwọn ẹyẹ ìwò+ ni èmi yóò sì pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa pèsè oúnjẹ fún ọ níbẹ̀.”+  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ bẹ́ẹ̀ ni ó lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kẹ́rítì tí ó wà ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì.  Àwọn ẹyẹ ìwò sì ń mú búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀ àti búrẹ́dì àti ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu+ omi láti inú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá.  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ ní òpin ọjọ́ mélòó kan pé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá náà di èyí tí ó gbẹ,+ nítorí pé eji wọwọ kò tíì dé sórí ilẹ̀.  Wàyí o, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ ọ́ wá, pé:+  “Dìde, lọ sí Sáréfátì,+ èyí tí ó jẹ́ ti Sídónì, kí o sì máa gbé níbẹ̀. Wò ó! Dájúdájú, èmi yóò pàṣẹ fún obìnrin kan níbẹ̀, tí ó jẹ́ opó, pé kí ó máa pèsè oúnjẹ fún ọ.” 10  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó dìde, ó sì lọ sí Sáréfátì, ó sì dé ẹnu ọ̀nà ìlú ńlá náà; sì wò ó! obìnrin kan, tí ó jẹ́ opó, ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Nítorí náà, ó pè é, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, fi ohun èlò bu òfèrè omi kan wá fún mi kí n lè mu.”+ 11  Nígbà tí ó sì ń lọ bù ú wá, ó ń bá a lọ láti pè é, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, bá mi mú oúnjẹ+ díẹ̀ lọ́wọ́.” 12  Látàrí èyí, ó sọ pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ,+ èmi kò ní àkàrà ribiti kankan,+ bí kò ṣe ẹ̀kúnwọ́+ ìyẹ̀fun nínú ìṣà títóbi àti òróró+ díẹ̀ nínú ìṣà kékeré; sì kíyè sí i, èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ, èmi yóò sì wọlé lọ ṣe nǹkan kan fún ara mi àti ọmọkùnrin mi, àwa yóò sì jẹ ẹ́, a ó sì kú.”+ 13  Nígbà náà, Èlíjà sọ fún un pé: “Má fòyà.+ Wọlé lọ, ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Kìkì pé kí o kọ́kọ́ ṣe àkàrà ribiti kékeré kan fún mi+ lára ohun tí ó wà níbẹ̀, kí o sì mú un jáde tọ̀ mí wá, lẹ́yìn ìgbà náà, o lè ṣe nǹkan kan fún ara rẹ àti ọmọkùnrin rẹ. 14  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun kì yóò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró kì yóò sì gbẹ, títí di ọjọ́ tí Jèhófà yóò mú kí eji wọwọ dé sórí ilẹ̀.’”+ 15  Nítorí náà, ó lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Èlíjà; obìnrin náà sì ń jẹun lọ, òun pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ àti agbo ilé obìnrin náà, fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.+ 16  Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró náà kò sì gbẹ,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ Èlíjà. 17  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí pé ọmọkùnrin obìnrin náà, ìyá ilé náà, dùbúlẹ̀ àìsàn, àìsàn rẹ̀ sì wá lé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi ṣẹ́ ku èémí kankan nínú rẹ̀+ mọ́. 18  Látàrí èyí, ó wí fún Èlíjà pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀,+ ìwọ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́? Ṣe ni o tọ̀ mí wá láti mú ìṣìnà mi wá sí ìrántí+ àti láti fi ikú pa ọmọkùnrin mi.” 19  Ṣùgbọ́n ó sọ fún un pé: “Gbé ọmọkùnrin rẹ fún mi.” Nígbà náà ni ó gbé e ní oókan àyà rẹ̀, ó sì gbé e gòkè lọ sí ìyẹ̀wù òrùlé,+ níbi tí ó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú+ tirẹ̀. 20  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi,+ ṣé opó tí mo ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìwọ yóò tún mú èṣe wá bá, nípa fífi ikú pa ọmọkùnrin rẹ̀?” 21  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí na ara rẹ̀ sórí ọmọ náà+ ní ìgbà mẹ́ta, ó sì ké pe Jèhófà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ọkàn+ ọmọ yìí padà wá sínú rẹ̀.” 22  Níkẹyìn, Jèhófà fetí sí ohùn+ Èlíjà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ náà padà sínú rẹ̀, ó sì wá sí ìyè.+ 23  Èlíjà gbé ọmọ náà wàyí, ó sì gbé e sọ̀ kalẹ̀ láti ìyẹ̀wù òrùlé wá sínú ilé, ó sì gbé e fún ìyá rẹ̀; Èlíjà sì wá sọ pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè.”+ 24  Látàrí ìyẹn, obìnrin náà sọ fún Èlíjà pé: “Mo mọ̀ wàyí, ní tòótọ́, pé ìwọ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run+ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ní ẹnu rẹ jẹ́ òótọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé