Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 16:1-34

16  Wàyí o, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jéhù+ ọmọkùnrin Hánáánì+ wá lòdì sí Bááṣà, pé:  “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé mo gbé ọ dìde láti inú ekuru+ kí n lè sọ ọ́ di aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì,+ ṣùgbọ́n o bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù,+ tí o sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì ṣẹ̀, nípa fífi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mú mi bínú,+  kíyè sí i, èmi yóò gbá Bááṣà àti ilé rẹ̀ kúrò tefétefé, dájúdájú, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì.+  Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ti Bááṣà tí ó bá kú ní ìlú ńlá, ajá yóò jẹ ẹ́; ẹnikẹ́ni tí ó sì jẹ́ tirẹ̀ tí ó bá kú ní pápá, àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run yóò jẹ+ ẹ́.”  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Bááṣà àti ohun tí ó ṣe àti agbára ńlá rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?  Níkẹyìn, Bááṣà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín sí Tírísà;+ Éláhì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, nípasẹ̀ Jéhù ọmọkùnrin Hánáánì wòlíì, ọ̀rọ̀ Jèhófà ti wá lòdì sí Bááṣà àti ilé rẹ̀,+ ní tìtorí gbogbo ìwà búburú tí ó hù ní ojú Jèhófà nípa fífi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀+ mú un bínú,+ pé kí ó lè dà bí ilé Jèróbóámù, àti nítorí pé ó ṣá a balẹ̀.+  Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Éláhì ọmọkùnrin Bááṣà di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Tírísà fún ọdún méjì.  Ìránṣẹ́ rẹ̀ Símírì,+ olórí ìdajì àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin, sì bẹ̀rẹ̀ sí di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí i, bí ó ti wà ní Tírísà tí ó ń fi ọtí rọ+ ara rẹ̀ yó ní ilé Ásáhì, ẹni tí ó wà lórí agbo ilé+ ní Tírísà. 10  Símírì sì tẹ̀ síwájú láti wọlé wá, ó sì ṣá a balẹ̀,+ ó sì fi ikú pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, gbàrà tí ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ṣá gbogbo ilé Bááṣà balẹ̀. Kò jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tirẹ̀ tí ń tọ̀ sára ògiri+ tàbí àwọn olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ tí ó jẹ́ tirẹ̀ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. 12  Bí Símírì ṣe pa gbogbo ilé Bááṣà+ rẹ́ ráúráú nìyẹn, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà+ tí ó sọ lòdì sí Bááṣà nípasẹ̀ Jéhù wòlíì,+ 13  ní tìtorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Bááṣà àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Éláhì+ ọmọkùnrin rẹ̀, èyí tí wọ́n ṣẹ̀, àti èyí tí wọ́n fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀, nípa fífi àwọn òrìṣà asán+ wọn mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú. 14  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Éláhì àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 15  Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Símírì di ọba fún ọjọ́ méje+ ní Tírísà, bí àwọn ènìyàn náà ti dó ti Gíbétónì,+ èyí tí ó jẹ́ ti àwọn Filísínì. 16  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibùdó gbọ́ tí a sọ pé: “Símírì ti di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun, ó sì ti ṣá ọba balẹ̀ pẹ̀lú.” Nítorí náà, gbogbo Ísírẹ́lì fi Ómírì,+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun, jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn ní ibùdó. 17  Ómírì àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ wá gòkè lọ láti Gíbétónì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sàga+ ti Tírísà. 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Símírì rí i pé a ti gba ìlú ńlá náà, nígbà náà ni ó wá sínú ilé gogoro ibùgbé tí ó wà ní ilé ọba, ó sì fi iná sun ilé ọba mọ́ ara rẹ̀ lórí, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú,+ 19  nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀, èyí tí ó dá, nípa ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ nípa rírìn ní ọ̀nà Jèróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ èyí tí ó dá nípa mímú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ 20  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Símírì, àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun rẹ̀, èyí tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 21  Ìgbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí pín ara wọn sí apá méjì.+ Apá kan wà lára àwọn ènìyàn náà tí ó di ọmọlẹ́yìn Tíbínì ọmọkùnrin Gínátì, láti fi í jẹ ọba, apá kejì sì jẹ́ ọmọlẹ́yìn Ómírì. 22  Níkẹyìn, àwọn ènìyàn tí ń tọ Ómírì lẹ́yìn ṣẹ́pá àwọn ènìyàn tí ń tọ Tíbínì ọmọkùnrin Gínátì lẹ́yìn; tí ó fi jẹ́ pé Tíbínì ko ikú, Ómírì sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba. 23  Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì fún ọdún méjìlá. Ó jọba fún ọdún mẹ́fà ní Tírísà. 24  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ra òkè ńlá Samáríà lọ́wọ́ Ṣémérì ní tálẹ́ńtì fàdákà méjì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé sórí òkè ńlá náà, ó sì pe orúkọ ìlú ńlá tí ó tẹ̀ dó ní Samáríà,+ nípa orúkọ Ṣémérì ọ̀gá òkè ńlá náà. 25  Ómírì sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú Jèhófà, ó sì wá ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+ 26  Ó sì ń rìn nínú gbogbo ọ̀nà Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì+ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀ nípa fífi àwọn òrìṣà asán+ wọn mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú. 27  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Ómírì, ohun tí ó ṣe àti agbára ńlá rẹ̀ tí ó fi gbé ìgbésẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 28  Níkẹyìn, Ómírì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín sí Samáríà; Áhábù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 29  Àti ní ti Áhábù ọmọkùnrin Ómírì, ó di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejìdínlógójì Ásà ọba Júdà; Áhábù ọmọkùnrin Ómírì sì ń bá a lọ láti jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà+ fún ọdún méjìlélógún. 30  Áhábù ọmọkùnrin Ómírì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+ 31  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ẹni pé ó jẹ́ ohun tí kò tó nǹkan+ rárá lójú rẹ̀ láti rìn nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, ó wá fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì ọba àwọn ọmọ Sídónì+ ṣe aya,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sin Báálì,+ ó sì ń tẹrí ba fún un. 32  Síwájú sí i, ó gbé pẹpẹ kan kalẹ̀ fún Báálì ní ilé+ Báálì tí ó kọ́ sí Samáríà. 33  Áhábù sí ń bá a lọ láti ṣe òpó ọlọ́wọ̀;+ Áhábù sì wá ṣe ohun púpọ̀ láti mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú+ ju gbogbo ọba Ísírẹ́lì tí ó ṣẹlẹ̀ pé ó wà ṣáájú rẹ̀. 34  Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, Híélì ará Bẹ́tẹ́lì kọ́ Jẹ́ríkò. Pẹ̀lú ìpàdánù Ábírámù àkọ́bí rẹ̀ ni ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, àti pẹ̀lú ìpàdánù Ségúbù àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni ó gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé