Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 15:1-34

15  Àti ní ọdún kejìdínlógún Jèróbóámù+ Ọba ọmọkùnrin Nébátì,+ Ábíjámú di ọba lórí Júdà.+  Ọdún mẹ́ta ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù; orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Máákà,+ ọmọ-ọmọ Ábíṣálómù.+  Ó sì ń bá a lọ láti rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ ṣáájú rẹ̀; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì wà ní pípé pérépéré+ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba ńlá rẹ̀.+  Nítorí pé, ní tìtorí Dáfídì,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní fìtílà+ ní Jerúsálẹ́mù, nípa gbígbé ọmọkùnrin rẹ̀ dìde lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì mú kí Jerúsálẹ́mù máa wà nìṣó,+  nítorí pé Dáfídì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, kò sì yà kúrò nínú ohunkóhun tí Ó ti pa láṣẹ fún un ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé+ rẹ̀, àfi nínú ọ̀ràn Ùráyà ọmọ Hétì.+  Ogun sì ń ṣẹlẹ̀ láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.+  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Ábíjámú àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ogun ṣẹlẹ̀ láàárín Ábíjámú àti Jèróbóámù+ pẹ̀lú.  Níkẹyìn, Ábíjámú dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì;+ Ásà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.  Ní ọdún ogún Jèróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásà jẹ ọba Júdà. 10  Ọdún mọ́kànlélógójì ni ó sì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù; orúkọ ìyá rẹ̀ àgbà sì ni Máákà+ ọmọ-ọmọ Ábíṣálómù.+ 11  Ásà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀.+ 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó mú kí àwọn kárùwà ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì kúrò ní ilẹ̀+ náà, ó sì mú gbogbo òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe kúrò.+ 13  Ní ti Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá, ó tẹ̀ síwájú láti mú un kúrò ní jíjẹ́ ìyáàfin,+ nítorí tí ó ṣe òrìṣà bíbanilẹ́rù kan fún òpó ọlọ́wọ̀; lẹ́yìn èyí tí Ásà gé òrìṣà rẹ̀ bíbanilẹ́rù lulẹ̀,+ ó sì sun ún+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì.+ 14  Àwọn ibi gíga+ ni kò sì mú kúrò.+ Àmọ́ ṣá o, ọkàn-àyà Ásà wà ní pípé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ohun tí baba rẹ̀ sọ di mímọ́ àti àwọn ohun tí òun fúnra rẹ̀ sọ di mímọ́ wá sínú ilé Jèhófà, fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò.+ 16  Ogun sì ń ṣẹlẹ̀ láàárín Ásà àti Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ wọn. 17  Nítorí náà, Bááṣà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá gbéjà ko Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Rámà,+ láti má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde lọ tàbí kí ó wọlé wá sọ́dọ̀ Ásà ọba Júdà.+ 18  Látàrí ìyẹn, Ásà kó gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ilé ọba, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀; Ásà Ọba sì wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì+ ọmọkùnrin Tábúrímónì ọmọkùnrin Hésíónì, ọba Síríà,+ ẹni tí ń gbé ní Damásíkù+ pé: 19  “Májẹ̀mú kan wà láàárín èmi àti ìwọ, láàárín baba mi àti baba rẹ. Kíyè sí i, mo fi ẹ̀bùn+ fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wá, ba májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà ọba Ísírẹ́lì jẹ́, kí ó lè fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.”+ 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bẹni-hádádì fetí sí Ásà Ọba, ó sì rán àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lọ gbéjà ko àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Íjónì+ àti Dánì+ àti Ebẹli-bẹti-máákà+ àti gbogbo Kínérétì balẹ̀, títí dé gbogbo ilẹ̀ Náfútálì.+ 21  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Bááṣà gbọ́ nípa èyí, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó jáwọ́ nínú kíkọ́ Rámà,+ ó sì ń bá a lọ láti gbé ní Tírísà.+ 22  Ásà Ọba, ní tirẹ̀, sì fi ọlá àṣẹ pe gbogbo Júdà+—láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀—wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn òkúta Rámà àti ẹ̀là gẹdú rẹ̀, èyí tí Bááṣà fi ń kọ́lé; Ásà Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n kọ́ Gébà+ ní Bẹ́ńjámínì, àti Mísípà.+ 23  Ní ti gbogbo ìyókù àlámọ̀rí Ásà àti gbogbo agbára ńlá rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti àwọn ìlú ńlá tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Kìkì pé ní ìgbà tí ó ń darúgbó,+ ó di olókùnrùn ní ẹsẹ̀.+ 24  Níkẹyìn, Ásà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì baba ńlá+ rẹ̀; Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 25  Ní ti Nádábù+ ọmọkùnrin Jèróbóámù, ó di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Ásà ọba Júdà; ó sì ń bá a lọ láti jọba lórí Ísírẹ́lì fún ọdún méjì. 26  Ó sì ń ṣe ohun tí ó burú+ ṣáá ní ojú Jèhófà, ó sì ń bá a lọ ní rírìn ní ọ̀nà baba rẹ̀+ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ 27  Bááṣà+ ọmọkùnrin Áhíjà ti ilé Ísákárì sì bẹ̀rẹ̀ sí di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí i; Bááṣà sì wá ṣá a balẹ̀ ní Gíbétónì,+ èyí tí ó jẹ́ ti àwọn Filísínì, bí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì ti ń sàga ti Gíbétónì. 28  Bẹ́ẹ̀ ni Bááṣà fi ikú pa á ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.+ 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó di ọba, ó ṣá gbogbo ilé Jèróbóámù balẹ̀. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ń mí ṣẹ́ kù lára ẹni tí í ṣe ti Jèróbóámù títí ó fi pa wọ́n rẹ́ ráúráú, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, Áhíjà ọmọ Ṣílò,+ 30  ní tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù, èyí tí ó ṣẹ̀,+ àti èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀, àti nítorí ìmúnibínú rẹ̀, èyí tí ó fi mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.+ 31  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Nádábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì? 32  Ogun sì ń ṣẹlẹ̀ láàárín Ásà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ wọn.+ 33  Ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, Bááṣà ọmọkùnrin Áhíjà di ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà fún ọdún mẹ́rìnlélógún.+ 34  Ó sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú Jèhófà,+ ó sì ń rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù+ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé