Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 13:1-34

13  Sì kíyè sí i, ènìyàn+ Ọlọ́run kan wà tí ó jáde wá láti Júdà nípa ọ̀rọ̀+ Jèhófà, sí Bẹ́tẹ́lì, bí Jèróbóámù ti dúró lẹ́bàá pẹpẹ+ láti rú èéfín ẹbọ.+  Nígbà náà ni ó ké jáde lòdì sí pẹpẹ nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó sì wí pé: “Pẹpẹ, pẹpẹ, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Wò ó! A bí ọmọkùnrin kan ní ilé Dáfídì, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Jòsáyà!+ Dájúdájú, òun yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga, tí ń rú èéfín ẹbọ lórí rẹ, rúbọ lórí rẹ, egungun àwọn ènìyàn ni yóò sì fi iná sun lórí rẹ.’”+  Ó sì fi àmì àgbàyanu+ hàn ní ọjọ́ yẹn, pé: “Èyí ni àmì àgbàyanu tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀: Wò ó! A la pẹpẹ náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, eérú ọlọ́ràá tí ó sì wà lórí rẹ̀ yóò sì dànù dájúdájú.”  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, tí ó ké jáde lòdì sí pẹpẹ tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì, kíákíá ni Jèróbóámù gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára pẹpẹ náà, ó sì nà án, ó wí pé: “Ẹ gbá a mú!”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì gbẹ, kò sì lè fà á padà sọ́dọ̀ ara rẹ̀.+  Pẹpẹ náà sì là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí ó fi jẹ́ pé eérú ọlọ́ràá náà dà kúrò lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí àmì àgbàyanu tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ fi fúnni nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà.+  Ọba wá dáhùn, ó sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Jọ̀wọ́, tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ lójú, kí o sì gbàdúrà nítorí mi kí a lè mú ọwọ́ mi padà bọ̀ sípò fún mi.”+ Látàrí èyí, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tu Jèhófà lójú,+ tí ó fi jẹ́ pé a mú ọwọ́ ọba padà bọ̀ sípò fún un, ó sì wá wà bí ti tẹ́lẹ̀.+  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Bá mi ká lọ sí ilé kí o sì jẹ ohun ìgbẹ́mìíró,+ kí èmi sì fún ọ ní ẹ̀bùn.”+  Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún ọba pé: “Bí o bá fún mi ní ìdajì ilé rẹ,+ èmi kí yóò bá ọ+ lọ kí n sì jẹ oúnjẹ tàbí kí n mu omi ní ibí yìí.  Nítorí bí ó ṣe pàṣẹ fún mi nìyẹn nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà, pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ+ tàbí kí o mu omi, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tí o gbà lọ padà.’” 10  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gba ọ̀nà mìíràn lọ, kò sì gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Bẹ́tẹ́lì padà. 11  Àgbàlagbà wòlíì+ kan sì ń gbé ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ sì wọlé wá wàyí, wọ́n sì ṣèròyìn gbogbo iṣẹ́ tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe ní ọjọ́ náà ní Bẹ́tẹ́lì fún un àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún ọba, wọ́n sì ń bá a lọ láti ṣèròyìn wọn fún baba wọn. 12  Nígbà náà ni baba wọn sọ fún wọn pé: “Ọ̀nà wo wá ni ó bá lọ?” Nítorí náà, àwọn ọmọ rẹ̀ fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, tí ó wá láti Júdà, bá lọ hàn án. 13  Wàyí o, ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gùn ún lọ. 14  Ó sì ń tẹ̀ lé ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, ó sì wá rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi ńlá.+ Nígbà náà ni ó wí fún un pé: “Ṣé ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wá láti Júdà?”+ ó dáhùn pé: “Èmi ni.” 15  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Bá mi lọ sí ilé kí o sì jẹ oúnjẹ.” 16  Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Èmi kò lè bá ọ padà tàbí kí n bá ọ wọlé, èmi kò sì gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí kí n mu omi pẹ̀lú rẹ ní ibí yìí.+ 17  Nítorí a ti sọ fún mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà+ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí kí o mu omi níbẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tún gba ọ̀nà tí o gbà lọ padà.’”+ 18  Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Èmi pẹ̀lú jẹ́ wòlíì bí tìrẹ, áńgẹ́lì+ kan sì bá mi sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà pé, ‘Mú kí ó bá ọ padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ, kí ó sì mu omi.’” (Ó tàn án jẹ.)+ 19  Nítorí náà, ó bá a padà lọ kí ó lè jẹ oúnjẹ ní ilé rẹ̀ kí ó sì mu omi.+ 20  Ó sì ṣẹlẹ̀, bí wọ́n ti jókòó nídìí tábìlì, pé ọ̀rọ̀+ Jèhófà tọ wòlíì tí ó mú un padà wá; 21  ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wá láti Júdà, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nítorí ìdí náà pé o ṣọ̀tẹ̀+ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, tí o kò sì pa àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa fún ọ mọ́,+ 22  ṣùgbọ́n o padà lọ kí o lè jẹ oúnjẹ kí o sì mu omi ní ibi tí ó sọ nípa rẹ̀ fún ọ pé: “Má jẹ oúnjẹ tàbí kí o mu omi,” òkú rẹ kì yóò dé inú ibi ìsìnkú àwọn baba ńlá rẹ.’”+ 23  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti jẹ oúnjẹ àti lẹ́yìn tí ó ti mu omi pé, kíákíá, ó bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì, èyíiní ni, fún wòlíì náà tí ó mú padà wá. 24  Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n. Nígbà tí ó yá, kìnnìún+ kan rí i lójú ọ̀nà ó sì fi ikú pa+ á, a sì wá sọ òkú rẹ̀ sí ojú ọ̀nà. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, kìnnìún náà sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. 25  Sì kíyè sí i, àwọn ènìyàn ń kọjá lọ, wọ́n sì rí òkú náà tí a sọ sí ojú ọ̀nà àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. Nígbà náà ni wọ́n wọlé wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìlú ńlá níbi tí àgbàlagbà wòlíì náà ń gbé. 26  Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà láti ojú ọ̀nà wá gbọ́ nípa rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà+ ni; nítorí bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi í fún kìnnìún, kí ó lè fà á ya kí ó sì fi ikú pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ fún un.”+ 27  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.” Nítorí náà, wọ́n bá a dì í ní gàárì.+ 28  Nígbà náà ni ó mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó sì rí òkú rẹ̀ tí a sọ sí ojú ọ̀nà pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. Kìnnìún náà kò jẹ òkú náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya.+ 29  Wòlíì náà sì gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, ó sì gbé e karí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá. Bí ó ṣe wá sí ìlú ńlá àgbàlagbà wòlíì náà nìyẹn láti pohùn réré ẹkún àti láti sin ín. 30  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó gbé òkú rẹ̀ sínú ibi ìsìnkú tirẹ̀; wọ́n sì ń bá a nìṣó láti pohùn réré ẹkún lórí rẹ̀+ pé: “Ó mà ṣe o, arákùnrin mi!” 31  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti sin ín pé, ó ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo bá kú, kí ẹ sin mí sí ibi ìsìnkú tí a sin ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà sí. Ẹ̀gbẹ́ egungun rẹ̀ ni kí ẹ kó egungun mi sí.+ 32  Nítorí pé, láìkùnà, ọ̀rọ̀ tí ó ké jáde nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà lòdì sí pẹpẹ+ tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti lòdì sí gbogbo ilé àwọn ibi gíga+ tí ó wà ní àwọn ìlú ńlá Samáríà+ yóò ṣẹ.”+ 33  Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jèróbóámù kò yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún ń mú lára àwọn ènìyàn náà ní gbogbo gbòò+ ṣe àlùfáà àwọn ibi gíga. Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá ní inú dídùn sí i, òun a fi agbára kún ọwọ́ rẹ̀,+ pé: “Sì jẹ́ kí ó di ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà àwọn ibi gíga.” 34  Inú nǹkan yìí sì ni okùnfà ẹ̀ṣẹ̀ wá wà níhà agbo ilé Jèróbóámù+ àti ìdí fún mímú wọn kúrò àti pípa wọ́n rẹ́ ráúráú kúrò ní ojú ilẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé