Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 12:1-33

12  Rèhóbóámù+ sì tẹ̀ síwájú láti lọ sí Ṣékémù, nítorí Ṣékémù+ ni gbogbo Ísírẹ́lì wá láti fi í jẹ ọba.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì gbọ́ nípa èyí, nígbà tí ó ṣì wà ní Íjíbítì (nítorí pé ó sá lọ ní tìtorí Sólómọ́nì Ọba, pé kí Jèróbóámù lè máa gbé ní Íjíbítì),+  nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ pè é. Lẹ́yìn náà, Jèróbóámù àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Rèhóbóámù sọ̀rọ̀ pé:+  “Baba rẹ, ní tirẹ̀, mú kí àjàgà wa nira, wàyí o, ní tìrẹ, mú kí iṣẹ́ ìsìn nínira ti baba rẹ àti àjàgà+ rẹ̀ wíwúwo tí ó fi bọ̀ wá lọ́rùn fúyẹ́,+ àwa yóò sì máa sìn ọ́.”+  Látàrí èyí, ó wí fún wọn pé: “Ẹ lọ fún ọjọ́ mẹ́ta kí ẹ sì padà wá sọ́dọ̀ mi.”+ Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà lọ.  Rèhóbóámù Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀ràn lọ àwọn àgbà ọkùnrin+ tí ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́ fún Sólómọ́nì baba rẹ̀ nígbà tí ó ṣì wà láàyè, pé: “Àmọ̀ràn wó ni ẹ óò fúnni láti fi fèsì fún àwọn ènìyàn yìí?”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n bá a sọ̀rọ̀ pé: “Bí ìwọ yóò bá fi ara rẹ hàn bí ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn yìí lónìí, tí o sì sìn wọ́n+ ní ti gidi, kí o sì dá wọn lóhùn, kí o sì fi ọ̀rọ̀+ rere bá wọn sọ̀rọ̀; dájúdájú wọn yóò sì di ìránṣẹ́ rẹ títí lọ.”+  Àmọ́ ṣá o, ó fi ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin gbà á sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀ràn lọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀,+ àwọn ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Kí ni ìmọ̀ràn+ tí ẹ ó gbani, kí a lè fèsì fún àwọn ènìyàn yìí tí ó bá mi sọ̀rọ̀ pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ fi bọ̀ wá lọ́rùn fúyẹ́’?”+ 10  Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀ bá a sọ̀rọ̀ pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ+ fún àwọn ènìyàn yìí tí ó bá ọ sọ̀rọ̀ pé, ‘Baba rẹ, ní tirẹ̀, mú kí àjàgà wa wúwo, ṣùgbọ́n, ní tìrẹ, mú kí ó fúyẹ́ lọ́rùn wa’; èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún wọn, ‘Dájúdájú, ọmọńdinrín mi gan-an yóò nípọn ju ìgbáròkó baba mi.+ 11  Wàyí o, baba mi, ní tirẹ̀, gbé ẹrù àjàgà wíwúwo bọ̀ yín lọ́rùn; ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò fi kún àjàgà+ yín. Baba mi, ní tirẹ̀, fi pàṣán nà yín, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò fi bílálà oníkókó nà yín.’”+ 12  Jèróbóámù àti gbogbo ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ Rèhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, pé: “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.”+ 13  Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn ènìyàn náà lóhùn lọ́nà líle koko,+ ó sì fi ìmọ̀ràn àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n gbà á sílẹ̀.+ 14  Ó sì ń bá a lọ láti bá wọn sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́kùnrin,+ pé: “Baba mi, ní tirẹ̀, mú kí àjàgà yín wúwo, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò fi kún àjàgà yín. Baba mi, ní tirẹ̀, fi pàṣán nà yín, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò fi bílálà oníkókó nà yín.”+ 15  Ọba kò sì fetí sí àwọn ènìyàn+ náà, nítorí pé Jèhófà+ ni ó mú kí ìyípadà àwọn àlámọ̀rí náà ṣẹlẹ̀, kí ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ+ ní ti tòótọ́, èyí tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò fún Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì. 16  Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì wá rí i pé ọba kò fetí sí wọn, nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà fún ọba lésì pé: “Ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì?+ Kò sì sí ogún kankan nínú ọmọkùnrin Jésè. Lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run+ rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì. Wàyí o, máa bójú tó ilé tìrẹ, ìwọ Dáfídì!”+ Látàrí ìyẹn, Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àgọ́ wọn. 17  Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní àwọn ìlú ńlá Júdà, Rèhóbóámù ń bá a lọ láti jọba lé wọn lórí.+ 18  Lẹ́yìn náà, Rèhóbóámù Ọba rán Ádórámù,+ ẹni tí ó wà lórí àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe,+ ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta,+ bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Agbára káká sì ni Rèhóbóámù Ọba alára fi ṣàṣeyọrí láti gòkè wọnú kẹ̀kẹ́ ẹṣin kí ó lè sá lọ sí Jerúsálẹ́mù. 19  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá ìdìtẹ̀+ wọn sí ilé Dáfídì nìṣó títí di òní yìí.+ 20  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ pé Jèróbóámù ti padà dé, kíákíá ni wọ́n ránṣẹ́ pè é wá sí àpéjọ, wọ́n sì fi í jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ Kò sí ìkankan tí ó di ọmọlẹ́yìn ilé Dáfídì àyàfi ẹ̀yà Júdà nìkan ṣoṣo gíro.+ 21  Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pe gbogbo ilé Júdà àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jọpọ̀,+ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ààyò abarapá ọkùnrin fún ogun, láti bá ilé Ísírẹ́lì jà, láti lè mú ipò ọba padà wá fún Rèhóbóámù ọmọkùnrin Sólómọ́nì. 22  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tọ Ṣemáyà+ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́+ wá, pé: 23  “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọkùnrin Sólómọ́nì ọba Júdà àti fún gbogbo ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ìyókù àwọn ènìyàn náà pé, 24  ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ gòkè lọ bá àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, jà.+ Kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀, nítorí èmi ni ó mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ wọ́n sì padà sí ilé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 25  Jèróbóámù sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Ṣékémù+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ láti ibẹ̀, ó sì kọ́ Pénúélì.+ 26  Jèróbóámù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí nínú ọkàn-àyà+ rẹ̀ pé: “Wàyí o, ìjọba yóò padà sí ilé Dáfídì.+ 27  Bí àwọn ènìyàn yìí bá ń bá a lọ láti gòkè lọ rú ẹbọ ní ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ dájúdájú, ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí yóò padà sọ́dọ̀ olúwa wọn, Rèhóbóámù ọba Júdà; dájúdájú, wọn yóò sì pa mí,+ wọn yóò sì padà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù ọba Júdà.” 28  Nítorí náà, ọba gbìmọ̀,+ ó sì ṣe ọmọ màlúù wúrà méjì,+ ó sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ó ti pọ̀ jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé,+ ìwọ Ísírẹ́lì, tí ó mú ọ gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 29  Nígbà náà, ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì gbé ìkejì sí Dánì.+ 30  Nǹkan yìí sì wá di okùnfà ẹ̀ṣẹ̀,+ àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí iwájú èyí tí ó wà ní Dánì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. 31  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé àwọn ibi gíga,+ ó sì ṣe àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn náà ní gbogbo gbòò, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Léfì.+ 32  Jèróbóámù sì ń bá a lọ láti ṣe àjọyọ̀ ní oṣù kẹjọ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ tí ó wà ní Júdà,+ kí ó lè rú àwọn ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, láti rúbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe; ó sì fi àwọn àlùfáà àwọn ibi gíga tí ó ṣe sẹ́nu iṣẹ́ àbójútó ní Bẹ́tẹ́lì.+ 33  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún ní oṣù kẹjọ, ní oṣù tí ó fúnra rẹ̀ hùmọ̀;+ ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe àjọyọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì rú àwọn ẹbọ lórí pẹpẹ náà láti rú èéfín ẹbọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé