Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Àwọn Ọba 11:1-43

11  Sólómọ́nì Ọba alára sì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya ilẹ̀ òkèèrè,+ pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Fáráò,+ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù,+ ọmọ Sídónì+ àti àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hétì,+  láti inú àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà wí nípa wọn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ wọlé lọ sí àárín wọn,+ kí àwọn náà má sì ṣe wọlé wá sí àárín yín; lóòótọ́, wọn yóò tẹ ọkàn-àyà yín láti tọ àwọn ọlọ́run+ wọn lẹ́yìn.” Àwọn ni Sólómọ́nì rọ̀ mọ́+ láti nífẹ̀ẹ́ wọn.  Ó sì wá ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin aya, àwọn ọmọbìnrin ọba, àti ọ̀ọ́dúnrún wáhàrì; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀,+ àwọn aya rẹ̀ tẹ ọkàn-àyà rẹ̀.  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó+ lọ pé àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ+ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run+ mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré+ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba rẹ̀.  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ Áṣítórétì,+ abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì lẹ́yìn àti Mílíkómù,+ ohun ìríra àwọn ọmọ Ámónì.  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú+ ní ojú Jèhófà, kò sì tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba+ rẹ̀.  Nígbà náà ni Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ibi gíga+ fún Kémóṣì,+ ohun ìríra+ Móábù, lórí òkè ńlá+ tí ó wà ní iwájú+ Jerúsálẹ́mù, àti fún Mólékì, ohun ìríra àwọn ọmọ Ámónì.  Bí ó sì ti ṣe nìyẹn fún gbogbo aya rẹ̀+ tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, tí ń rú èéfín ẹbọ, tí ó sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn.+  Ìbínú Jèhófà sì wá ru+ sí Sólómọ́nì, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ̀ ti tẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tí ó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì.+ 10  Nípa ohun yìí sì ni ó pàṣẹ fún un pé kí ó má tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn;+ ṣùgbọ́n kò pa èyí tí Jèhófà pa láṣẹ mọ́. 11  Jèhófà wí fún Sólómọ́nì wàyí pé: “Nítorí ìdí náà pé èyí ti ṣẹlẹ̀ sí ọ, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ìlànà àgbékalẹ̀ mi tí mo gbé kalẹ̀ ní àṣẹ fún ọ, láìkùnà, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, dájúdájú, èmi yóò sì fi í fún ìránṣẹ́+ rẹ. 12  Bí ó ti wù kí ó rí, èmi kì yóò ṣe é+ ní àwọn ọjọ́ rẹ, nítorí ti Dáfídì baba rẹ.+ Ọwọ́ ọmọkùnrin rẹ ni èmi yóò ti fà á ya.+ 13  Kìkì pé kì í ṣe gbogbo ìjọba náà ni èmi yóò fà ya.+ Ẹ̀yà kan ni èmi yóò fi fún ọmọkùnrin rẹ, nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi+ àti nítorí ti Jerúsálẹ́mù tí mo yàn.”+ 14  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé alátakò+ kan dìde sí Sólómọ́nì,+ èyíinì ni, Hádádì ọmọ Édómù, lára àwọn ọmọ ọba. Édómù+ ni ó wà. 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì ṣá Édómù+ balẹ̀, nígbà tí Jóábù olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun gòkè wá láti sin àwọn tí a pa, pé ó gbìyànjú láti ṣá gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní Édómù+ balẹ̀. 16  (Nítorí oṣù mẹ́fà ni Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì fi gbé ibẹ̀ títí ó fi ké gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní Édómù kúrò.) 17  Hádádì sì fẹsẹ̀ fẹ, òun àti àwọn kan lára àwọn ọkùnrin Édómù, lára àwọn ìránṣẹ́ baba rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, láti wá sí Íjíbítì, nígbà tí Hádádì jẹ́ ọ̀dọ́mọdékùnrin. 18  Nítorí náà, wọ́n dìde láti Mídíánì,+ wọ́n sì wá sí Páránì, wọ́n sì kó àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ara wọn láti Páránì,+ wọ́n sì wá sí Íjíbítì, sọ́dọ̀ Fáráò ọba Íjíbítì, ẹni tí ó wá fún un ní ilé. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó yan oúnjẹ lé e lọ́wọ́, ó sì fún un ní ilẹ̀. 19  Hádádì sì ń bá a lọ láti rí ojú rere+ ní ojú Fáráò, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fún un ní aya,+ arábìnrin aya tirẹ̀, arábìnrin Tápénésì, ìyáàfin. 20  Nígbà tí ó ṣe, arábìnrin Tápénésì bí Génúbátì ọmọkùnrin rẹ̀ fún un, Tápénésì sì já a lẹ́nu ọmú+ nínú ilé Fáráò gan-an; Génúbátì sì ń bá a lọ láti wà ní ilé Fáráò láàárín àwọn ọmọ Fáráò gan-an. 21  Hádádì alára sì gbọ́ ní Íjíbítì pé Dáfídì ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ àti pé Jóábù olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti kú.+ Nítorí náà, Hádádì wí fún Fáráò pé: “Rán mi lọ,+ kí n lè lọ sí ilẹ̀ tèmi.” 22  Ṣùgbọ́n Fáráò wí fún un pé: “Kí ni o ṣaláìní bí o ti wà pẹ̀lú mi, tí ó fi jẹ́ pé nísinsìnyí, o ń wá ọ̀nà àtilọ sí ilẹ̀ tìrẹ?” Ó fèsì pé: “Kò sí; ṣugbọn ó yẹ kí o rán mi lọ láìkùnà.” 23  Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti gbé alátakò+ mìíràn dìde sí i, èyíinì ni, Résónì ọmọkùnrin Élíádà, ẹni tí ó fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀, Hadadésà+ ọba Sóbà.+ 24  Ó sì ń bá a nìṣó láti kó àwọn ọkùnrin jọ síhà ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì wá di olórí ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí, nígbà tí Dáfídì pa wọ́n.+ Nítorí náà, wọ́n lọ sí Damásíkù,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní Damásíkù. 25  Ó sì wá di alátakò Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì,+ ìyẹn pa pọ̀ pẹ̀lú ìṣeléṣe tí Hádádì ṣe; ó sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra+ Ísírẹ́lì nígbà tí ó ń jọba lórí Síríà. 26  Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì ọmọ Éfúráímù láti Sérédà sì ń bẹ, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì,+ orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Sérúà, obìnrin opó kan. Òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba.+ 27  Ìdí tí ó sì fi gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba nìyí: Sólómọ́nì alára mọ Òkìtì.+ Ó ti dí àlàfo Ìlú Ńlá Dáfídì baba rẹ̀.+ 28  Wàyí o, ọkùnrin náà Jèróbóámù jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin.+ Nígbà tí Sólómọ́nì wá rí i pé ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́ òṣìṣẹ́ kára,+ ó tẹ̀ síwájú láti fi í ṣe alábòójútó+ lórí gbogbo iṣẹ́ ìsìn àpàpàǹdodo+ ti ilé Jósẹ́fù.+ 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn gan-an pé Jèróbóámù alára jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù, Áhíjà+ ọmọ Ṣílò,+ tí í ṣe wòlíì, sì wá rí i ní ojú ọ̀nà, Áhíjà sì fi ẹ̀wù tuntun bo ara rẹ̀; àwọn méjèèjì nìkan sì ni wọ́n wà ní pápá. 30  Áhíjà di ẹ̀wù tuntun tí ó wà lọrùn ara rẹ̀ mú wàyí, ó sì fà á ya+ sí abala méjìlá.+ 31  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún Jèróbóámù pé: “Kó abala mẹ́wàá fún ara rẹ; nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómọ́nì, dájúdájú, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá+ fún ọ. 32  Ẹ̀yà kan ṣoṣo+ sì ni yóò máa jẹ́ tirẹ̀ lọ nítorí ti ìránṣẹ́ mi Dáfídì+ àti nítorí ti Jerúsálẹ́mù,+ ìlú ńlá tí mo yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì. 33  Ìdí èyí ni pé wọ́n ti fi mí+ sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún Áṣítórétì,+ abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì, fún Kémóṣì,+ ọlọ́run Móábù, àti fún Mílíkómù,+ ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì; wọn kò sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi nípa ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú mi àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀. 34  Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà pátá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí ìjòyè ni èmi yóò yàn án ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn,+ nítorí tí ó pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́. 35  Dájúdájú, èmi yóò sì gba ipò ọba kúrò ní ọwọ́ ọmọkùnrin rẹ̀, èmi yóò sì fi í fún ọ, àní ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 36  Ọmọkùnrin rẹ̀ ni èmi yóò sì fún ní ẹ̀yà kan, kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa bá a lọ láti ní fìtílà níwájú mi nígbà gbogbo ní Jerúsálẹ́mù,+ ìlú ńlá tí mo yàn fún ara mi láti fi orúkọ mi síbẹ̀.+ 37  Ìwọ sì ni ẹni tí èmi yóò mú, ìwọ yóò sì jọba lórí gbogbo èyí tí ọkàn rẹ fà+ sí ní tòótọ́, ìwọ yóò sì di ọba lórí Ísírẹ́lì dájúdájú. 38  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ìwọ bá ṣègbọràn sí gbogbo èyí tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú mi ní ti tòótọ́, nípa pípa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́ àti àwọn àṣẹ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe,+ dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ èmi yóò sì kọ́ ilé wíwà pẹ́ títí fún ọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ́ fún Dáfídì,+ èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ. 39  Èmi yóò sì tẹ́ ọmọ Dáfídì lógo ní tìtorí èyí,+ kìkì pé kì í ṣe títí lọ.’”+ 40  Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti fi ikú pa+ Jèróbóámù. Nítorí náà, Jèróbóámù dìde, ó sì sá lọ+ sí Íjíbítì sọ́dọ̀ Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì, ó sì ń gbé ní Íjíbítì títí Sólómọ́nì fi kú. 41  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Sólómọ́nì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé àwọn àlámọ̀rí Sólómọ́nì bí? 42  Àwọn ọjọ́ tí Sólómọ́nì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì sì jẹ́ ogójì ọdún.+ 43  Nígbà náà ni Sólómọ́nì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì+ baba rẹ̀; Rèhóbóámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé