Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 10:1-29

10  Wàyí o, ọbabìnrin Ṣébà+ ń gbọ́ ìròyìn nípa Sólómọ́nì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà.+ Nítorí náà, ó wá láti fi àwọn ìbéèrè apinnilẹ́mìí+ dán an wò.  Níkẹyìn, ó dé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ abánirìn wíwúnilórí+ gan-an, àwọn ràkúnmí+ tí ó ru òróró básámù+ àti wúrà púpọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye; ó sì wọlé tọ Sólómọ́nì wá, ò sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ ohun gbogbo tí ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ̀.+  Sólómọ́nì, ẹ̀wẹ̀, ń bá a lọ láti sọ gbogbo ọ̀ràn+ obìnrin náà fún un. Kò sí ọ̀ràn kankan tí ó fara sin fún ọba, tí kò sọ fún obìnrin+ náà.  Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà wá rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tí ó kọ́,+  àti oúnjẹ orí tábìlì+ rẹ̀ àti jíjókòó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìṣètò ìgbóúnjẹfúnni àwọn aṣèránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn àti àwọn ohun mímu+ rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun rẹ̀ tí ó máa ń fi rúbọ déédéé ní ilé Jèhófà, nígbà náà, kò wá sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú rẹ̀.+  Nítorí náà, ó wí fún ọba pé: “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ tèmi nípa àwọn ọ̀ràn rẹ àti nípa ọgbọ́n+ rẹ já sí.  Èmi kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà títí mo fi wá kí ojú èmi fúnra mi lè rí i; sì wò ó! a kò sọ ìdajì+ wọn fún mi. Ìwọ ta yọ ní ọgbọ́n àti aásìkí ré kọjá àwọn ohun tí a gbọ́ èyí tí mo fetí sí.+  Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ;+ aláyọ̀+ ni àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ wọ̀nyí tí ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n+ rẹ!  Kí ìbùkún+ jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn+ sí ọ nípa fífi ọ́ sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì;+ nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ tí ó fi yàn ọ ṣe ọba+ láti máa ṣe ìpinnu ìdájọ́+ àti òdodo.”+ 10  Nígbà náà ni ó fún+ ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ńtì wúrà+ àti ọ̀pọ̀ jaburata òróró básámù+ àti àwọn òkúta iyebíye. Òróró básámù tí ó pọ̀ tó irú èyí tí ọbabìnrin Ṣébà fún Sólómọ́nì Ọba kò tún dé mọ́ rárá. 11  Àti pé, ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun+ ti Hírámù, tí ó ru wúrà láti Ófírì,+ tún kó àwọn ẹ̀là gẹdú igi álígúmù+ ní iye púpọ̀ gidigidi àti àwọn òkúta iyebíye+ wá láti Ófírì. 12  Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ẹ̀là gẹdú igi álígúmù náà ṣe àwọn ọwọ̀n fún ilé Jèhófà+ àti fún ilé ọba, àti àwọn háàpù+ àti àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ fún àwọn akọrin pẹ̀lú. Àwọn ẹ̀là gẹdú igi álígúmù bí irú èyí kò wọlé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò tíì rí wọn títí di òní yìí. 13  Sólómọ́nì Ọba alára sì fún ọbabìnrin Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ̀, èyí tí òun béèrè, yàtọ̀ sí ohun tí ó fún un gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ọ̀làwọ́+ Sólómọ́nì Ọba. Lẹ́yìn náà, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ilẹ̀ tirẹ̀, òun pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀. 14  Ìwọ̀n wúrà+ tí ó ń dé sọ́dọ̀ Sólómọ́nì ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà tálẹ́ńtì wúrà,+ 15  yàtọ̀ sí àwọn ọkùnrin arìnrìn-àjò àti èrè láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti gbogbo ọba+ àwọn ará Arébíà+ àti àwọn gómìnà ilẹ̀ náà. 16  Sólómọ́nì Ọba sì tẹ̀ síwájú láti fi àyọ́lù wúrà+ ṣe igba apata ńlá (ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ lé apata ńlá kọ̀ọ̀kan),+ 17  ó sì fi àyọ́lù wúrà ṣe ọ̀ọ́dúnrún asà (mínà mẹ́ta wúrà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ lé asà kọ̀ọ̀kan).+ Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú ilé Igbó Lẹ́bánónì.+ 18  Síwájú sí i, ọba ṣe ìtẹ́+ eyín erin ńlá+ kan, ó sì fi wúrà tí a yọ́ mọ́+ bò ó. 19  Àtẹ̀gùn mẹ́fà ni ìtẹ́ náà ní, ìtẹ́ náà sì ní ìbòrí aṣíjiboni rìbìtì kan lẹ́yìn rẹ̀, ibi ìgbápálé sì wà ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi ìjókòó, kìnnìún méjì+ sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé+ náà. 20  Kìnnìún méjìlá sì ni ó wà, tí ó dúró níbẹ̀ lórí àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Kò sí ìjọba mìíràn tí ó ní èyíkéyìí tí a ṣe bí èyí gan-an.+ 21  Gbogbo ohun èlò fún ohun mímu Sólómọ́nì Ọba sì jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò ilé Igbó Lẹ́bánónì+ sì jẹ́ ògidì wúrà.+ Kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ ti fàdákà; a kò kà á sí nǹkan kan rárá ní àwọn ọjọ́ Sólómọ́nì. 22  Nítorí pé ọba ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun láti Táṣíṣì+ lórí òkun pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ti Hírámù. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta-mẹ́ta ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì ń gbé wúrà+ àti fàdákà, eyín erin,+ àti àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ológe wá. 23  Nítorí náà, Sólómọ́nì Ọba pọ̀ ní ọrọ̀+ àti ọgbọ́n+ ju gbogbo àwọn ọba yòókù ní ilẹ̀ ayé. 24  Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé sì ń wá ojú Sólómọ́nì láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 25  Olúkúlùkù wọn sì ń mú ẹ̀bùn+ tirẹ̀ wá, àwọn ohun èlò fàdákà+ àti àwọn ohun èlò wúrà àti àwọn ẹ̀wù àti ìhámọ́ra+ àti òróró básámù, àwọn ẹṣin àti ìbaaka,+ gẹ́gẹ́ bí ìṣe ọdọọdún.+ 26  Sólómọ́nì sì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin ogun jọ ṣáá; ó sì wá ní egbèje kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá ẹṣin ogun,+ ó sì yàn wọ́n dúró sí àwọn ìlú ńlá kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 27  Ọba sì wá ṣe fàdákà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù bí àwọn òkúta,+ ó sì ṣe igi kédárì bí àwọn igi síkámórè tí ó wà ní Ṣẹ́fẹ́là ní ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 28  A sì ń kó àwọn ẹṣin ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì láti Íjíbítì, àwùjọ ẹgbẹ́ àwọn olówò ọba a sì fúnra wọn gba agbo ẹṣin náà ní iye owó+ kan. 29  Kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan sì sábà máa ń gòkè wá, a sì máa ń fi í ránṣẹ́ láti Íjíbítì fún ẹgbẹ̀ta ẹyọ fàdákà, àti ẹṣin kan fún àádọ́jọ; bí ó sì ti rí nìyẹn fún gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn ọba Síríà. Ipasẹ̀ wọn ni wọ́n gbà ń ṣe ìfiránṣẹ́ náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé