Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Àwọn Ọba 1:1-53

1  Wàyí o, Dáfídì Ọba ti darúgbó,+ ó sì pọ̀ ní ọjọ́; wọn a sì fi àwọn ẹ̀wù bò ó, ṣùgbọ́n ara rẹ̀ kì í móoru.  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n wá ọ̀dọ́mọbìnrin kan, wúńdíá,+ fún olúwa mi ọba, kí ó sì máa ṣe ìránṣẹ́+ fún ọba, kí ó lè di olùṣètọ́jú+ rẹ̀; kí ó sì dùbúlẹ̀ ní oókan àyà+ rẹ, ara olúwa mi ọba yóò sì móoru dájúdájú.”+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó lẹ́wà jákèjádò gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì, níkẹyìn, wọ́n rí Ábíṣágì+ ará Ṣúnẹ́mù,+ wọ́n sì mú un wọlé tọ ọba wá.  Ọ̀dọ́mọbìnrin náà sì lẹ́wà dé góńgó;+ ó sì wá di olùṣètọ́jú ọba, ó sì ń ṣèránṣẹ́ fún un, ọba kò sì ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.  Ní gbogbo àkókò yìí, Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì+ ń gbé ara rẹ̀ sókè,+ pé: “Èmi ni yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba!”+ Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí a ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún un pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti àádọ́ta ọkùnrin tí ń sáré níwájú rẹ̀.+  Baba rẹ̀ kò sì bà á nínú jẹ́ nígbàkígbà rí nípa sísọ pé: “Èé ṣe tí o fi ṣe báyìí?”+ Òun pẹ̀lú sì dára gidigidi ní ìrísí,+ ìyá rẹ̀ sì bí i lé Ábúsálómù.  Ó sì wá ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà àti pẹ̀lú Ábíátárì+ àlùfáà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrànlọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Ádóníjà.+  Ní ti Sádókù+ àlùfáà àti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà àti Nátánì+ wòlíì àti Ṣíméì+ àti Réì àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá+ tí wọ́n jẹ́ ti Dáfídì, wọn kò bá Ádóníjà lẹ̀dí àpò pọ̀.+  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Ádóníjà ṣe ìrúbọ+ àgùntàn àti màlúù àti ẹran àbọ́pa nítòsí òkúta Sóhélétì, èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹn-rógélì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké sí gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àwọn ọmọkùnrin ọba+ àti gbogbo ọkùnrin Júdà àwọn ìránṣẹ́ ọba; 10  Nátánì wòlíì àti Bẹnáyà àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá àti Sólómọ́nì arákùnrin rẹ̀ ni kò ké sí. 11  Wàyí o, Nátánì+ sọ fún Bátí-ṣébà,+ ìyá Sólómọ́nì,+ pé: “Ṣé ìwọ kò tíì gbọ́ pé Ádóníjà ọmọkùnrin Hágítì+ ti di ọba, àti pé olúwa wa Dáfídì kò mọ̀ nípa rẹ̀ rárá? 12  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, wá, jọ̀wọ́, kí n fi ìrònújinlẹ̀ gbà ọ́ nímọ̀ràn.+ Kí o sì pèsè àsálà fún ọkàn ara rẹ àti fún ọkàn ọmọkùnrin rẹ Sólómọ́nì.+ 13  Lọ, kí o sì wọlé tọ Dáfídì Ọba lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Olúwa mi, ọba, ìwọ ha kọ́ ni ó búra fún ẹrúbìnrin rẹ pé: “Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ ni ẹni tí yóò di ọba lẹ́yìn mi, òun sì ni ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi”?+ Nítorí náà, èé ṣe tí Ádóníjà fi wá di ọba?’ 14  Wò ó! Bí o ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ níbẹ̀, nígbà náà ni èmi alára yóò wọlé tẹ̀ lé ọ, èmi yóò sì fìdí òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ múlẹ̀ dájúdájú.”+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bátí-ṣébà wọlé tọ ọba lọ nínú yàrá inú lọ́hùn-ún,+ ọba sì ti darúgbó gidigidi,+ Ábíṣágì+ ará Ṣúnẹ́mù sì ń ṣèránṣẹ́ fún ọba. 16  Bátí-ṣébà sì tẹrí ba mọ́lẹ̀, ó sì wólẹ̀+ fún ọba, lẹ́yìn èyí ni ọba wí pé: “Kí ni o fẹ́ béèrè?”+ 17  Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Olúwa mi,+ ìwọ ni o fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ búra fún ẹrúbìnrin rẹ pé, ‘Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ ni ẹni tí yóò di ọba lẹ́yìn mi, òun sì ni ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi.’+ 18  Wàyí o, wò ó! Ádóníjà+ tìkara rẹ̀ ti di ọba, wàyí o, olúwa mi ọba alára kò sì mọ̀ nípa rẹ̀ rárá.+ 19  Nítorí náà, ó fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́pa àti àgùntàn rúbọ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì ké sí gbogbo ọmọ ọba+ àti Ábíátárì+ àlùfáà àti Jóábù+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; ṣùgbọ́n Sólómọ́nì ìránṣẹ́ rẹ ni kò ké sí.+ 20  Àti ìwọ olúwa mi ọba—ojú+ gbogbo Ísírẹ́lì wà lara rẹ, láti sọ fún wọn ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ̀.+ 21  Yóò sì ṣẹlẹ̀ dájúdájú pé, gbàrà tí olúwa mi ọba bá ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ èmi alára àti ọmọkùnrin mi Sólómọ́nì pẹ̀lú yóò di olùmúni-bínú.” 22  Sì wò ó! bí ó ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Nátánì wòlíì alára wọlé.+ 23  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sọ fún ọba pé: “Nátánì wòlíì nìyí!” Lẹ́yìn náà, ó wọlé wá síwájú ọba, ó sì wólẹ̀ fún ọba pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀.+ 24  Nígbà náà ni Nátánì sọ pé: “Olúwa mi ọba, ìwọ fúnra rẹ ha wí pé, ‘Ádóníjà ni ẹni tí yóò di ọba lẹ́yìn mi, òun sì ni ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi’?+ 25  Nítorí ó ti sọ̀ kalẹ̀ lọ lónìí kí ó lè fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́pa àti àgùntàn rúbọ+ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àti kí ó lè ké sí gbogbo ọmọ ọba àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti Ábíátárì àlùfáà;+ wọ́n sì ń jẹ, wọ́n sì ń mu níwájú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n sì ń wí pé, ‘Kí Ádóníjà Ọba kí ó pẹ́!’+ 26  Ṣùgbọ́n ní ti èmi ìránṣẹ́ rẹ, èmi àti Sádókù+ àlùfáà àti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà àti Sólómọ́nì ìránṣẹ́ rẹ ni kò ké sí.+ 27  Bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ olúwa mi ọba ni nǹkan yìí ti wá, nígbà náà, ìwọ kò tíì jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ mọ+ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ̀.” 28  Dáfídì ọba wá dáhùn, ó sì wí pé: “Ẹ pe Bátí-ṣébà+ wá fún mi.” Látàrí ìyẹn, ó wọlé wá síwájú ọba, ó sì dúró níwájú ọba. 29  Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí búra,+ ó sì wí pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ẹni tí ó tún ọkàn+ mi rà padà+ kúrò nínú gbogbo wàhálà,+ 30  gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún ọ pé: ‘Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ ni ẹni tí yóò di ọba lẹ́yìn mi, òun sì ni ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi!’ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe lónìí yìí.”+ 31  Nígbà náà ni Bátí-ṣébà tẹrí ba mọ́lẹ̀+ ní ìdojúbolẹ̀, ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó sì wí pé: “Kí olúwa mi Dáfídì Ọba kí ó wà pẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin!”+ 32  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì Ọba sọ pé: “Ẹ pe Sádókù+ àlùfáà àti Nátánì wòlíì àti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà wá fún mi.” Nítorí náà, wọ́n wọlé wá síwájú ọba. 33  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé: “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́+ olúwa yín dání, kí ẹ sì mú kí Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi gun abo ìbaaka tèmi,+ kí ẹ sì mú un sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Gíhónì.+ 34  Kí Sádókù àlùfáà àti Nátánì wòlíì sì fòróró yàn+ án níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì; kí ẹ sì fun ìwo,+ kí ẹ sì wí pé: ‘Kí Sólómọ́nì Ọba kí ó pẹ́!’+ 35  Kí ẹ sì gòkè tẹ̀ lé e wá, òun yóò sì wọlé, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi; òun ni yóò sì jẹ ọba ní ipò mi, dájúdájú, òun ni èmi yóò sì fàṣẹ yàn láti di aṣáájú lórí Ísírẹ́lì àti lórí Júdà.” 36  Ní kíá, Bẹnáyà ọmọkùnrin Jéhóádà dá ọba lóhùn, ó sì wí pé: “Àmín!+ Bẹ́ẹ̀ ni kí Jèhófà Ọlọ́run olúwa mi ọba kí ó wí.+ 37  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣe wà pẹ̀lú olúwa mi ọba,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó ṣe wà pẹ̀lú Sólómọ́nì,+ kí ó sì mú kí ìtẹ́ rẹ̀ tóbi ju+ ìtẹ́ olúwa mi Dáfídì Ọba.” 38  Sádókù+ àlùfáà àti Nátánì+ wòlíì àti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jéhóádà àti àwọn Kérétì+ àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì mú kí Sólómọ́nì gun abo ìbaaka Dáfídì Ọba,+ lẹ́yìn náà, wọ́n sì mú un wá sí Gíhónì.+ 39  Nígbà náà ni Sádókù àlùfáà mú ìwo òróró+ láti inú àgọ́,+ ó sì fòróró yan+ Sólómọ́nì; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo, gbogbo ènìyàn sì hó pé: “Kí Sólómọ́nì Ọba kí ó pẹ́!”+ 40  Lẹ́yìn náà, gbogbo ènìyàn gòkè tẹ̀ lé e lẹ́yìn, àwọn ènìyàn náà sì ń fun fèrè,+ wọ́n sì ń yọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà,+ tí ó fi jẹ́ pé ariwo wọ́n fa ilẹ̀+ ya. 41  Ádóníjà àti gbogbo àwọn tí a ké sí, tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì wá gbọ́ ọ, nígbà tí wọ́n jẹun tán.+ Nígbà tí Jóábù wá gbọ́ ìró ìwo, ó sọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Kí ni ariwo ìlú tí ó wà nínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀+ yìí túmọ̀ sí?” 42  Nígbà tí ó ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, họ́wù, bẹ́ẹ̀ ni Jónátánì+ ọmọkùnrin Ábíátárì àlùfáà dé. Nígbà náà ni Ádóníjà sọ pé: “Wọlé wá, nítorí akíkanjú ọkùnrin ni ọ́, ìhìn rere+ ni o sì mú wá.” 43  Ṣùgbọ́n Jónátánì dáhùn, ó sì wí fún Ádóníjà pé: “Rárá! Olúwa wa Dáfídì Ọba tìkára rẹ̀ ti fi Sólómọ́nì jẹ ọba.+ 44  Nítorí náà, ọba rán Sádókù àlùfáà àti Nátánì wòlíì àti Bẹnáyà ọmọkùnrin Jéhóádà àti àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì mú kí ó gun abo ìbaaka ọba.+ 45  Lẹ́yìn náà, Sádókù àlùfáà àti Nátánì wòlíì fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba+ ní Gíhónì; lẹ́yìn èyí tí wọ́n gòkè wá láti ibẹ̀, wọ́n ń yọ̀, ìlú náà sì wà nínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀. Ìyẹn ni ariwo tí ẹ̀yin gbọ́.+ 46  Àti pé, ní àfikún, Sólómọ́nì ti jókòó lórí ìtẹ́ àkóso.+ 47  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ìránṣẹ́ ọba ti wọlé láti wá súre fún olúwa wa Dáfídì Ọba pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ mú orúkọ Sólómọ́nì gbayì ju orúkọ rẹ, kí ó sì mú kí ìtẹ́ rẹ̀ tóbi ju ìtẹ́ rẹ!’+ Látàrí èyí, ọba tẹrí ba lórí ibùsùn.+ 48  Èyí sì ni ohun tí ọba sọ pẹ̀lú, ‘Ìbùkún+ ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti pèsè ẹnì kan láti jókòó lónìí lórí ìtẹ́ mi, tí ojú mi sì rí i!’”+ 49  Gbogbo àwọn tí a ké sí tí wọ́n wà pẹ̀lú Ádóníjà sì bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì, wọ́n sì dìde, wọ́n sì lọ, olúkúlùkù ní ọ̀nà rẹ̀.+ 50  Ádóníjà tìkára rẹ̀ sì fòyà nítorí Sólómọ́nì. Nítorí náà, ó dìde, ó sì lọ rá àwọn ìwo pẹpẹ mú.+ 51  Nígbà tí ó ṣe, a ròyìn fún Sólómọ́nì pé: “Kíyè sí i, Ádóníjà fòyà Sólómọ́nì Ọba; kíyè sí i, ó sì ti gbá àwọn ìwo pẹpẹ mú, pé, ‘Kí Sólómọ́nì Ọba kọ́kọ́ búra fún mi pé òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’” 52  Sólómọ́nì fèsì pé: “Bí òun yóò bá di akíkanjú ọkùnrin, fọ́nrán irun+ rẹ̀ kan kì yóò bọ́ sí ilẹ̀; ṣùgbọ́n bí a bá rí ohun tí ó burú lọ́wọ́ rẹ̀,+ òun yóò ní láti kú pẹ̀lú.”+ 53  Nítorí náà, Sólómọ́nì Ọba ránṣẹ́, wọ́n sì mú un sọ̀ kalẹ̀ kúrò lára pẹpẹ. Nígbà náà, ó wọlé, ó sì tẹrí ba fún Sólómọ́nì Ọba; lẹ́yìn èyí ni Sólómọ́nì sọ fún un pé: “Máa lọ ilé rẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé