Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 9:1-18

9  Ọgbọ́n+ tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀;+ ó ti gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ méjèèje.  Ó ti ṣètò ẹran pípa rẹ̀; ó ti ṣe àdàlù wáìnì rẹ̀; ju èyíinì lọ, ó ti ṣètò tábìlì rẹ̀.+  Ó ti rán àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ obìnrin jáde, kí ó lè ké jáde ní orí àwọn ibi gíga ìlú pé:  “Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ́ aláìní ìrírí, kí ó yà síhìn-ín.”+ Ẹnì yòówù tí ọkàn-àyà bá kù fún+—ó wí fún un pé:  “Ẹ wá, ẹ fi oúnjẹ mi bọ́ ara yín, kí ẹ sì ṣàjọpín nínú mímu wáìnì tí mo ti dà lù.+  Ẹ fi àwọn aláìní ìrírí sílẹ̀, kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó,+ kí ẹ sì máa rìn tààrà ní ọ̀nà òye.”+  Ẹni tí ó bá ń tọ́ olùyọṣùtì sọ́nà ń gba àbùkù fún ara rẹ̀,+ ẹni tí ó bá sì ń fún ẹni burúkú ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà—àbùkù ni fún un.+  Má ṣe bá olùyọṣùtì wí, kí ó má bàa kórìíra rẹ.+ Fún ọlọ́gbọ́n ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà, òun yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+  Fi fún ọlọ́gbọ́n, òun yóò sì túbọ̀ gbọ́n sí i.+ Fi ìmọ̀ fún olódodo, òun yóò sì pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́. 10  Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,+ ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.+ 11  Nítorí nípasẹ̀ mi ni ọjọ́ rẹ yóò fi di púpọ̀,+ a ó sì fi ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè kún un fún ọ.+ 12  Bí o bá ti di ọlọ́gbọ́n, o ti di ọlọ́gbọ́n fún ire ara rẹ;+ bí o bá sì ti yọ ṣùtì, ìwọ ni yóò rù ú, ìwọ nìkan ṣoṣo.+ 13  Dìndìnrìn obìnrin jẹ́ aláriwo líle.+ Òpè ni, kò sì mọ nǹkan kan rárá.+ 14  Ó jókòó sí ẹnu ọ̀nà ilé ara rẹ̀, sórí ìjókòó, ní àwọn ibi gíga ìlú,+ 15  láti nahùn pe àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà, àwọn tí ń lọ tààrà ní ipa ọ̀nà wọn,+ pé: 16  “Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ́ aláìní ìrírí, kí ó yà síhìn-ín.”+ Ẹnì yòówù tí ọkàn-àyà bá sì kù fún+—ó wí fún un pẹ̀lú pé: 17  “Omi tí a jí dùn,+ oúnjẹ tí a sì jẹ ní ìkọ̀kọ̀—ó dùn mọ́ni.”+ 18  Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú ń bẹ níbẹ̀, pé àwọn tí obìnrin náà pè wọlé ń bẹ ní àwọn ibi rírẹlẹ̀ Ṣìọ́ọ̀lù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé