Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 8:1-36

8  Ọgbọ́n kò ha ń bá a nìṣó ní kíké jáde,+ tí ìfòyemọ̀ sì ń bá a nìṣó ní fífọ ohùn rẹ̀ jáde?+  Ní orí àwọn ibi gíga,+ lẹ́bàá ọ̀nà, ibi ìsọdá àwọn òpópónà ni ó dúró sí.  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè, ní ẹnu ìlú,+ ibi àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà ni ó ti ń ké tòò pé:+  “Ẹ̀yin ènìyàn ni mo ń pè, ohùn mi sì ń kọ sí àwọn ọmọ ènìyàn.+  Ẹ̀yin aláìní ìrírí, ẹ lóye ìfọgbọ́nhùwà;+ àti ẹ̀yin arìndìn, ẹ lóye ọkàn-àyà.+  Ẹ fetí sílẹ̀, nítorí àwọn ohun àkọ́kọ́ ni mo ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀,+ ṣíṣí ètè mi sì jẹ́ nípa ìdúróṣánṣán.+  Nítorí òkè ẹnu mi ń sọ òtítọ́ jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́;+ ìwà burúkú sì jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ètè mi.+  Nínú òdodo ni gbogbo àsọjáde ẹnu mi.+ Kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ màgòmágó tàbí wíwọ́ nínú wọn.+  Gbogbo wọ́n jẹ́ títọ́ lójú ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀, àti adúróṣánṣán lójú àwọn tí ó rí ìmọ̀.+ 10  Ẹ gba ìbáwí mi kì í sì í ṣe fàdákà, àti ìmọ̀ dípò ààyò wúrà.+ 11  Nítorí ọgbọ́n sàn ju iyùn,+ a kò sì lè mú gbogbo ohun mìíràn tí ń fúnni ní inú dídùn bá a dọ́gba.+ 12  “Èmi, ọgbọ́n, mo ń bá ìfọgbọ́nhùwà gbé,+ mo sì ti wá ìmọ̀ agbára láti ronú pàápàá rí.+ 13  Ìbẹ̀rù Jèhófà túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú.+ Mo kórìíra ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn+ àti ọ̀nà búburú àti ẹnu+ tí ń ṣàyídáyidà. 14  Mo ní ìmọ̀ràn+ àti ọgbọ́n gbígbéṣẹ́.+ Èmi—òye;+ mo ní agbára ńlá.+ 15  Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba ń jọba, tí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ń gbé àṣẹ òdodo kalẹ̀.+ 16  Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọmọ aládé ń ṣàkóso bí ọmọ aládé,+ tí gbogbo àwọn ọ̀tọ̀kùlú sì ń ṣèdájọ́ ní òdodo.+ 17  Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni èmi alára nífẹ̀ẹ́,+ àwọn tí ń wá mi sì ni àwọn tí ń rí mi.+ 18  Ọrọ̀ àti ògo ń bẹ lọ́dọ̀ mi,+ àwọn ohun àjogúnbá oníyelórí àti òdodo.+ 19  Èso mi sàn ju wúrà, àní ju wúrà tí a yọ́ mọ́, àmújáde mi sì sàn ju ààyò fàdákà.+ 20  Ipa ọ̀nà òdodo ni mo ń rìn,+ ní àárín àwọn òpópónà ìdájọ́,+ 21  láti mú kí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ní ohun ìní ti ara;+ mo sì mú kí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ wọn kí ó kún.+ 22  “Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀,+ ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.+ 23  Láti àkókò tí ó lọ kánrin ni a ti gbé mi kalẹ̀,+ láti ìbẹ̀rẹ̀, láti àwọn àkókò tí ó wà ṣáájú ilẹ̀ ayé.+ 24  Nígbà tí kò sí àwọn ibú omi, a ti bí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí,+ nígbà tí kò sí àwọn ìsun tí omi kún dẹ́múdẹ́mú. 25  Kí a tó fìdí àwọn òkè ńláńlá kalẹ̀,+ ṣáájú àwọn òkè kéékèèké, a ti bí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, 26  nígbà tí kò tíì ṣe ilẹ̀ ayé+ àti àwọn àyè gbayawu àti apá àkọ́kọ́ lára àwọn ìwọ́jọpọ̀ ekuru ilẹ̀ eléso.+ 27  Nígbà tí ó pèsè ọ̀run, mo wà níbẹ̀;+ nígbà tí ó fàṣẹ gbé òbìrìkìtì kalẹ̀ sí ojú ibú omi,+ 28  nígbà tí ó mú àwọn ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ti òkè le gírígírí,+ nígbà tí ó mú kí àwọn ìsun ibú omi lágbára,+ 29  nígbà tí ó fi àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ fún òkun pé kí omi rẹ̀ má ṣe ré àṣẹ ìtọ́ni òun kọjá,+ nígbà tí ó fàṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé kalẹ̀,+ 30  nígbà náà ni mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́,+ mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe+ lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà,+ 31  tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sí ilẹ̀ eléso ilẹ̀ ayé rẹ̀,+ àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.+ 32  “Wàyí o, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi; bẹ́ẹ̀ ni, àní aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́.+ 33  Ẹ fetí sí ìbáwí kí ẹ sì di ọlọ́gbọ́n,+ ẹ má sì fi ìwà àìnáání èyíkéyìí hàn.+ 34  Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ń fetí sí mi nípa wíwà lójúfò lẹ́nu àwọn ilẹ̀kùn mi lójoojúmọ́, nípa ṣíṣọ́ arópòódògiri àwọn ẹnu ọ̀nà mi.+ 35  Nítorí ẹni tí ó bá rí mi yóò rí ìyè+ dájúdájú, yóò sì rí ìfẹ́ rere gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+ 36  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá tàsé mi ń ṣe ọkàn ara rẹ̀ léṣe;+ gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan ni àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ ikú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé