Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Òwe 4:1-27

4  Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ, sí ìbáwí baba,+ kí ẹ sì fiyè sílẹ̀, kí ẹ lè mọ òye.+  Nítorí ìtọ́ni rere ni ohun tí èmi yóò fi fún yín dájúdájú.+ Ẹ má fi òfin mi sílẹ̀.+  Nítorí mo jẹ́ ọmọ gidi fún baba mi,+ ẹni ìkẹ́ àti ọ̀kan ṣoṣo níwájú ìyá mi.+  Baba mi a sì máa fún mi ní ìtọ́ni,+ a sì máa wí fún mi pé: “Ǹjẹ́ kí ọkàn-àyà+ rẹ di àwọn ọ̀rọ̀ mi mú ṣinṣin.+ Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè.+  Ní ọgbọ́n,+ ní òye.+ Má gbàgbé, má sì yà kúrò nínú àwọn àsọjáde ẹnu mi.+  Má fi í sílẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́. Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.  Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ.+ Ní ọgbọ́n; pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.+  Gbé e níyì gidigidi, yóò sì gbé ọ ga.+ Yóò ṣe ọ́ lógo nítorí tí o gbá a mọ́ra.+  Yóò fún orí rẹ ní ọ̀ṣọ́ òdòdó olóòfà ẹwà;+ adé ẹwà ni yóò fi jíǹkí rẹ.”+ 10  Gbọ́, ọmọ mi, kí o sì tẹ́wọ́ gba àwọn àsọjáde mi.+ Nígbà náà ni ọdún ìwàláàyè yóò di púpọ̀ fún ọ.+ 11  Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà ọgbọ́n pàápàá;+ èmi yóò mú kí o rin àwọn òpó ọ̀nà ìdúróṣánṣán.+ 12  Nígbà tí o bá ń rìn, ìṣísẹ̀rìn rẹ kì yóò há;+ bí o bá sì ń sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.+ 13  Di ìbáwí mú;+ má ṣe jẹ́ kí ó lọ.+ Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.+ 14  Má wọ ipa ọ̀nà àwọn ẹni burúkú,+ má sì rìn tààrà lọ sínú ọ̀nà àwọn ẹni búburú.+ 15  Yẹra fún un,+ má gbà á kọjá;+ yà kúrò nínú rẹ̀, kí o sì kọjá lọ.+ 16  Nítorí wọn kì í sùn bí kò ṣe pé wọ́n ṣe búburú,+ a sì ti gba oorun lójú wọn bí kò ṣe pé wọ́n mú ẹnì kan kọsẹ̀.+ 17  Nítorí wọ́n ti fi oúnjẹ ìwà burúkú bọ́ ara wọn,+ wáìnì ìwà ipá sì ni wọ́n ń mu.+ 18  Ṣùgbọ́n ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.+ 19  Ọ̀nà àwọn ẹni burúkú dà bí ìṣúdùdù;+ wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń kọsẹ̀ lára rẹ̀ ṣáá.+ 20  Ọmọ mi, fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.+ Dẹ etí rẹ sí àwọn àsọjáde mi.+ 21  Kí wọ́n má lọ kúrò ní ojú rẹ.+ Pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn-àyà rẹ.+ 22  Nítorí ìwàláàyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó wá wọn rí+ àti ìlera fún gbogbo ẹran ara wọn.+ 23  Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ,+ nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.+ 24  Mú ọ̀rọ̀ wíwọ́ kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ;+ sì mú békebèke ètè jìnnà réré sí ara rẹ.+ 25  Ní ti ojú rẹ, ọ̀kánkán tààrà ni kí ó máa wò,+ bẹ́ẹ̀ ni, kí ojú rẹ títàn yanran tẹjú mọ́ ọ̀kánkán gan-an ní iwájú rẹ.+ 26  Mú ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ rẹ jọ̀lọ̀,+ ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀nà tìrẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ 27  Má tẹ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì.+ Mú ẹsẹ̀ rẹ kúrò nínú ohun tí ó burú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé