Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 31:1-31

31  Àwọn ọ̀rọ̀ Lémúẹ́lì Ọba, ìhìn iṣẹ́ wíwúwo+ tí ìyá rẹ̀ fi fún un bí ìtọ́sọ́nà:+  Kí ni mo ń sọ, ìwọ ọmọ mi, kí sì ni, ìwọ ọmọ ikùn mi,+ kí sì ni, ìwọ ọmọ àwọn ẹ̀jẹ́ mi?+  Má fi ìmí rẹ fún àwọn obìnrin,+ tàbí àwọn ọ̀nà rẹ fún ohun tí ń ṣokùnfà nínu àwọn ọba nù.+  Kì í ṣe fún àwọn ọba, Lémúẹ́lì, kì í ṣe fún àwọn ọba láti máa mu wáìnì tàbí fún àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga láti máa sọ pé: “Ọtí tí ń pani dà?”+  kí ènìyàn má bàa mu, kí ó sì gbàgbé ohun tí a fàṣẹ gbé kalẹ̀, kí ó sì ṣe ìyípo ọ̀ràn ẹjọ́ èyíkéyìí lára àwọn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́.+  Ẹ fi ọtí tí ń pani fún ẹni tí ń sún mọ́ àtiṣègbé+ àti wáìnì fún àwọn ọlọ́kàn kíkorò.+  Kí ènìyàn mu kí ó sì gbàgbé ipò òṣì rẹ̀, kí ènìyàn má sì rántí ìdààmú tirẹ̀ mọ́.  La ẹnu rẹ fún ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀,+ nínú ọ̀ràn ẹjọ́ gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ.+  La ẹnu rẹ, ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo, kí o sì gba ọ̀ràn ẹjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì rò.+ א [Áléfì] 10  Ta ni ó lè rí aya tí ó dáńgájíá?+ Ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn. ב [Bétì] 11  Ọkàn-àyà olúwa rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, kò sì ṣaláìní èrè.+ ג [Gímélì] 12  Obìnrin náà fi ohun rere san án lẹ́san, láìjẹ́ ohun búburú, ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.+ ד [Dálétì] 13  Obìnrin náà wá irun àgùntàn àti aṣọ ọ̀gbọ̀, ó sì ń ṣe ohun yòówù tí ọwọ́ ara rẹ̀ ní inú dídùn sí.+ ה [Híì] 14  Ó dà bí àwọn ọkọ̀ òkun tí í ṣe ti olówò kan.+ Ibi jíjìnnàréré ni ó ti ń mú oúnjẹ rẹ̀ wá. ו [Wọ́ọ̀] 15  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó máa ń dìde nígbà tí ó ṣì jẹ́ òru,+ a sì fi oúnjẹ fún agbo ilé rẹ̀ àti ìpín tí a lànà sílẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀.+ ז [Sáyínì] 16  Ó gbé pápá kan yẹ̀ wò, ó sì tẹ̀ síwájú láti rí i gbà;+ nínú èso ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi gbin ọgbà àjàrà.+ ח [Kétì] 17  Ó fi okun di ìgbáròkó rẹ̀ lámùrè, ó sì mú apá rẹ̀ le.+ ט [Tétì] 18  Ó róye pé òwò òun dára; fìtílà rẹ̀ kì í kú ní òru.+ י [Yódì] 19  Ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀pá ìrànwú, ọwọ́ tirẹ̀ sì di ìrànwú mú.+ כ [Káfì] 20  Ó na àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òtòṣì.+ ל [Lámédì] 21  Ẹ̀rù kò bà á fún agbo ilé rẹ̀ nítorí ìrì dídì, nítorí pé ẹ̀wù oníṣẹ̀ẹ́po méjì ni gbogbo agbo ilé rẹ̀ wọ̀.+ מ [Mémì] 22  Ó ṣe àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn+ fún ara rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró.+ נ [Núnì] 23  Ẹni mímọ̀ ni olúwa obìnrin+ náà jẹ́ ní àwọn ẹnubodè,+ nígbà tí ó bá jókòó pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà. ס [Sámékì] 24  Ó ṣe àwọn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ pàápàá,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tà wọ́n, ó sì fi àwọn ìgbànú fún àwọn ọkùnrin oníṣòwò. ע [Áyínì] 25  Okun àti ọlá ńlá ni aṣọ rẹ̀,+ ó sì ń rẹ́rìn-ín nípa ọjọ́ tí ń bọ̀ níwájú.+ פ [Péè] 26  Ó fi ọgbọ́n la ẹnu rẹ̀,+ òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀.+ צ [Sádì] 27  Ó ń ṣọ́ àwọn ohun tí ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀, kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.+ ק [Kófì] 28  Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní aláyọ̀;+ olúwa rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.+ ר [Réṣì] 29  Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin ní ń bẹ tí ó fi ìdáńgájíá hàn,+ ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ lékè gbogbo wọn.+ ש [Ṣínì] 30  Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké,+ ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán;+ ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.+ ת [Tọ́ọ̀] 31  Ẹ fún un lára èso ọwọ́ rẹ̀,+ kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè pàápàá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé