Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 3:1-35

3  Ọmọ mi, má gbàgbé òfin mi,+ kí ọkàn-àyà rẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́,+  nítorí ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè+ àti àlàáfíà ni a ó fi kún un fún ọ.+  Kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ má fi ọ́ sílẹ̀.+ So wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.+ Kọ wọ́n sára wàláà ọkàn-àyà rẹ,+  kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ojú rere àti ìjìnlẹ̀ òye rere ní ojú Ọlọ́run àti ti ará ayé.+  Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+ má sì gbára lé òye tìrẹ.+  Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ,+ òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.+  Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ.+ Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yí padà kúrò nínú ohun búburú.+  Ǹjẹ́ kí ó di amúniláradá+ fún ìdodo rẹ àti ìtura fún egungun rẹ.+  Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà+ àti àkọ́so gbogbo èso rẹ.+ 10  Nígbà náà, àwọn ilé ìtọ́jú ẹrù rẹ yóò kún fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ;+ wáìnì tuntun yóò sì kún àwọn ẹkù ìfúntí rẹ ní àkúnwọ́sílẹ̀.+ 11  Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà;+ má sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà rẹ̀,+ 12  nítorí pé ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà,+ àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.+ 13  Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí,+ àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀,+ 14  nítorí níní in gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà+ pàápàá. 15  Ó ṣe iyebíye ju iyùn,+ a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba. 16  Ọjọ́ gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;+ ọrọ̀ àti ògo sì ń bẹ ní ọwọ́ òsì rẹ̀.+ 17  Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, gbogbo òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ àlàáfíà.+ 18  Ó jẹ́ igi ìyè+ fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin+ ni a ó pè ní aláyọ̀.+ 19  Ọgbọ́n ni Jèhófà fúnra rẹ̀ fi fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀.+ Ìfòyemọ̀ ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ 20  Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni a fi pín àwọn ibú omi níyà,+ tí àwọn sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀ sì ń fún òjò wutuwutu sílẹ̀.+ 21  Ọmọ mi, kí wọ́n má ṣe lọ kúrò ní ojú rẹ.+ Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú,+ 22  wọn yóò sì jẹ́ ìyè fún ọkàn+ rẹ àti òòfà ẹwà fún ọrùn+ rẹ. 23  Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò máa rìn nínú ààbò+ ní ọ̀nà rẹ, ẹsẹ̀ rẹ pàápàá kì yóò sì gbún ohunkóhun.+ 24  Nígbàkigbà tí o bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò ní ìbẹ̀rùbojo;+ dájúdájú, ìwọ yóò dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò sì dùn mọ́ ọ.+ 25  Kì yóò sí ìdí fún ọ láti fòyà ohun òjijì èyíkéyìí tí ó jẹ́ akún-fún-ìbẹ̀rùbojo,+ tàbí ìjì lórí àwọn ẹni burúkú, nítorí pé ó ń bọ̀.+ 26  Nítorí, ní ti tòótọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ ìgbọ́kànlé rẹ,+ dájúdájú, kì yóò jẹ́ kí a gbá ẹsẹ̀ rẹ mú.+ 27  Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún,+ nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.+ 28  Má sọ fún ọmọnìkejì rẹ pé: “Máa lọ, kí o sì padà wá lọ́la, èmi yóò sì fi fún ọ,” nígbà tí nǹkan kan wà lọ́wọ́ rẹ.+ 29  Má fẹ̀tàn hùmọ̀ ohunkóhun tí ó burú sí ọmọnìkejì rẹ,+ nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú rẹ nínú ìmọ̀lára ààbò.+ 30  Má ṣe bá ènìyàn ṣe aáwọ̀ láìnídìí,+ bí òun kò bá ṣe ọ́ ní búburú.+ 31  Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá,+ bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀.+ 32  Nítorí oníbékebèke+ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà,+ ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.+ 33  Ègún Jèhófà wà lórí ilé ẹni burúkú,+ ṣùgbọ́n ibi gbígbé àwọn olódodo ni ó ń bù kún.+ 34  Bí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn olùyọṣùtì,+ òun fúnra rẹ̀ yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín;+ ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò fi ojú rere hàn sí.+ 35  Ọlá ni àwọn ọlọ́gbọ́n yóò wá ní,+ ṣùgbọ́n àwọn arìndìn ń gbé àbùkù ga.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé