Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Òwe 29:1-27

29  Ènìyàn ti a fi ìbáwí tọ́ sọ́nà léraléra,+ ṣùgbọ́n tí ó mú ọrùn rẹ̀ le,+ yóò ṣẹ́ lójijì, kì yóò sì ṣeé mú lára dá.+  Nígbà tí olódodo bá di púpọ̀, àwọn ènìyàn a máa yọ̀;+ ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.+  Ènìyàn tí ó nífẹ̀ẹ́ ọgbọ́n ń mú baba rẹ̀ yọ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá kárùwà kẹ́gbẹ́ ń pa àwọn ohun tí ó níye lórí run.+  Ìdájọ́ òdodo ni ọba fi ń mú kí ilẹ̀ máa bá a nìṣó ní dídúró,+ ṣùgbọ́n ènìyàn tí ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń ya á lulẹ̀.+  Abarapá ọkùnrin tí ń pọ́n alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀+ ń na kìkì àwọ̀n jáde fún ìṣísẹ̀ rẹ̀.+  Ìdẹkùn wà nínú ìrélànàkọjá ènìyàn búburú,+ ṣùgbọ́n olódodo ń fi ìdùnnú ké jáde, ó sì ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.+  Olódodo mọ ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin tí ó jẹ́ ti àwọn ẹni rírẹlẹ̀.+ Ẹni burúkú kì í ronú nípa irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀.+  Àwọn ènìyàn tí ń sọ ọ̀rọ̀ ìfọ́nnu ń mú ìlú gbiná,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbọ́n máa ń yí ìbínú padà.+  Ọlọ́gbọ́n tí ó kó wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú òmùgọ̀—ó di ẹni tí a ru sókè, ó sì rẹ́rìn-ín pẹ̀lú, kò sì sí ìsinmi.+ 10  Àwọn ènìyàn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìlẹ́bi;+ àti ní ti àwọn adúróṣánṣán, wọ́n ń wá ọkàn olúkúlùkù.+ 11  Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.+ 12  Níbi tí olùṣàkóso bá ti ń fetí sí ọ̀rọ̀ èké, gbogbo àwọn tí ń ṣèránṣẹ́ fún un yóò jẹ́ ẹni burúkú.+ 13  Aláìnílọ́wọ́ àti ènìyàn tí ń nini lára ti pàdé ara wọn;+ ṣùgbọ́n Jèhófà ni ó ń mú ojú àwọn méjèèjì mọ́lẹ̀ kedere.+ 14  Níbi tí ọba bá ti ń fi òótọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀,+ ìtẹ́ rẹ̀ yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ìgbà gbogbo.+ 15  Ọ̀pá àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ni ohun tí ń fúnni ní ọgbọ́n;+ ṣùgbọ́n ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.+ 16  Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá di púpọ̀, ìrélànàkọjá a di púpọ̀ gidigidi; ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò wo ìṣubú wọn pàápàá.+ 17  Na ọmọ rẹ, yóò sì mú ìsinmi bá ọ, yóò sì fún ọkàn rẹ ní ọ̀pọ̀ adùn.+ 18  Níbi tí kò bá ti sí ìran, àwọn ènìyàn yóò wà láìníjàánu,+ ṣùgbọ́n aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa òfin mọ́.+ 19  Ìránṣẹ́ kì yóò jẹ́ kí a fi kìkìdá ọ̀rọ̀ tọ́ òun sọ́nà,+ nítorí tí ó yé e ṣùgbọ́n kò kọbi ara sí i.+ 20  Ìwọ ha ti rí ènìyàn tí ń fi ìkánjú sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀?+ Ìrètí ń bẹ fún arìndìn jù fún un lọ.+ 21  Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí aye rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá. 22  Ènìyàn tí ó fi ara fún ìbínú ń ru asọ̀ sókè,+ ẹnikẹ́ni tí ó sì fi ara fún ìhónú ní ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.+ 23  Àní ìrera ará ayé ni yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ ní ẹ̀mí yóò di ògo mú.+ 24  Ẹni tí ó jẹ́ alájọṣe pẹ̀lú olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀.+ Ó lè gbọ́ ìbúra tí ó ní ègún nínú, ṣùgbọ́n kò ní ròyìn nǹkan kan.+ 25  Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.+ 26  Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ń wá ojú olùṣàkóso,+ ṣùgbọ́n ìdájọ́ ènìyàn ń wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+ 27  Ènìyàn tí ó jẹ́ aláìṣèdájọ́ òdodo jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn olódodo,+ ẹni tí ó sì jẹ́ adúróṣánṣán ní ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú ẹni burúkú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé