Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Òwe 28:1-28

28  Ẹni burúkú ń sá lọ nígbà tí olùlépa kò sí,+ ṣùgbọ́n olódodo dà bí ẹgbọrọ kìnnìún tí ó ní ìgboyà.+  Nítorí ìrélànàkọjá ilẹ̀ kan, ọ̀pọ̀ ni àwọn ọmọ aládé rẹ̀+ tí ń dìde tẹ̀léra-tẹ̀léra, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ afòyemọ̀ tí ó ní ìmọ̀ ohun títọ́ ni ọmọ aládé yóò fi wà pẹ́ títí.+  Abarapá ọkùnrin tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ tí ó sì ń lu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì+ dà bí òjò tí ń gbá nǹkan lọ tí ó fi jẹ́ pé kò sí oúnjẹ.  Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ ń yin ẹni burúkú,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ń pa òfin mọ́ ń ru ara wọn sókè lòdì sí wọn.+  Àwọn ènìyàn tí wọ́n kúndùn ìwà búburú kò lè lóye ìdájọ́, ṣùgbọ́n àwọn tí ń wá Jèhófà lè lóye ohun gbogbo.+  Aláìnílọ́wọ́ tí ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀ sàn ju ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ oníwà wíwọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀.+  Ọmọ tí ó lóye máa ń pa òfin mọ́,+ ṣùgbọ́n èyí tí ń bá àwọn alájẹkì kẹ́gbẹ́ ń tẹ́ baba rẹ̀ lógo.+  Ẹni tí ó bá ń fi èlé+ àti ẹ̀dá owó sọ àwọn ohun ìní rẹ̀ tí ó níye lórí di púpọ̀ wulẹ̀ ń kó wọn jọ fún ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ni.+  Ẹni tí ó bá ń yí etí rẹ̀ kúrò nínú gbígbọ́ òfin+—àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+ 10  Ẹni tí ó bá ń mú kí àwọn adúróṣánṣán ṣáko+ lọ sí ọ̀nà búburú, òun alára yóò já sínú kòtò òun fúnra rẹ̀,+ ṣùgbọ́n àwọn aláìní-àléébù yóò wá ní ohun rere.+ 11  Ọlọ́rọ̀ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni rírẹlẹ̀ tí ó ní ìfòyemọ̀ a yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀.+ 12  Nígbà tí àwọn olódodo bá ń yọ ayọ̀ ńláǹlà,+ ẹwà púpọ̀ yanturu ní ń bẹ; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá dìde, ènìyàn a fi ẹni tí òun jẹ́ pa mọ́.+ 13  Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.+ 14  Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ń ní ìbẹ̀rùbojo nígbà gbogbo,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn-àyà rẹ̀ le yóò ṣubú sínú ìyọnu àjálù.+ 15  Bí kìnnìún tí ń kùn hùn-ùn àti béárì tí ń rọ́ gììrì síwájú ni olùṣàkóso burúkú lórí àwọn ènìyàn rírẹlẹ̀.+ 16  Aṣáájú tí ó ṣaláìní ìfòyemọ̀ tòótọ́ pọ̀ yanturu nínú ìwà jìbìtì pẹ̀lú,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu+ yóò fa ọjọ́ ara rẹ̀ gùn. 17  Ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọ̀ lọ́rùn nítorí ọkàn kan, òun alára yóò sá lọ sínú kòtò pàápàá.+ Kí wọ́n má dì í mú. 18  Ẹni tí ó bá ń rìn láìní àléébù ni a ó gbà là,+ ṣùgbọ́n ẹni tí a ṣe ní oníwà wíwọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ yóò ṣubú lójú ẹsẹ̀.+ 19  Ẹni tí ó bá ń ro ilẹ̀ tirẹ̀ yóò ní oúnjẹ tí ó pọ̀ tó,+ ẹni tí ó bá sì ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí yóò ní ipò òṣì tí ó pọ̀ tó.+ 20  Ènìyàn tí ó ń ṣe àwọn ìṣe ìṣòtítọ́ yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe kánkán láti jèrè ọrọ̀ kì yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.+ 21  Fífi ojúsàájú hàn kò dára,+ tàbí kí abarapá ọkùnrin ré ìlànà kọjá nítorí ẹ̀já búrẹ́dì lásán-làsàn. 22  Ènìyàn tí ó ní ojú ìlara ń mú ara rẹ̀ jí gìrì tẹ̀ lé àwọn ohun tí ó níye lórí,+ ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àìní yóò dé bá òun. 23  Ẹni tí ń fi ìbáwí tọ́ ènìyàn sọ́nà+ yóò rí ojú rere púpọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà ju ẹni tí ń fi ahọ́n rẹ̀ pọ́nni. 24  Ẹni tí ń ja baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ lólè+ tí ó sì ń sọ pé: “Kì í ṣe ìrélànàkọjá,”+ jẹ́ alájọṣe pẹ̀lú ènìyàn tí ń runni. 25  Ẹni tí ó jẹ́ aṣefọ́nńté ní ọkàn ń ru asọ̀ sókè,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbójú lé Jèhófà ni a óò mú sanra.+ 26  Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.+ 27  Ẹni tí ó bá ń fi fún aláìnílọ́wọ́ kì yóò ṣe aláìní,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ojú pa mọ́ yóò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.+ 28  Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá dìde, ènìyàn a fi ara rẹ̀ pa mọ́;+ ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣègbé, olódodo a di púpọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé