Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 26:1-28

26  Bí ìrì dídì ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti bí òjò ní ìgbà ìkórè,+ bẹ́ẹ̀ ni ògo kò yẹ fún arìndìn.+  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ní ìdí fún fífò lọ àti gan-an gẹ́gẹ́ bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ ti ní ìdí fún fífò, bẹ́ẹ̀ ni ìfiré kì í wá láìsí ìdí gúnmọ́ kan.+  Pàṣán wà fún ẹṣin,+ ìjánu+ wà fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọ̀pá sì wà fún ẹ̀yìn àwọn arìndìn.+  Má ṣe dá arìndìn lóhùn ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, kí ìwọ pẹ̀lú má bàa dà bí tirẹ̀.+  Dá arìndìn lóhùn ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, kí ó má bàa di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀.+  Bí ẹni tí ń gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ jù nù, bí ẹni tí ń mu kìkìdá ìwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń fi àwọn ọ̀ràn sí ọwọ́ arìndìn.+  Ẹsẹ̀ arọ ha ti fa omi sókè bí? Nígbà náà, òwe wà ní ẹnu àwọn arìndìn.+  Bí ẹni tí ń sé òkúta kan mọ́ nínú òkìtì àwọn òkúta, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń fi ògo fún arìndìn lásán-làsàn.+  Bí èpò ẹlẹ́gùn-ún ti wà ní ọwọ́ ọ̀mùtípara, bẹ́ẹ̀ ni òwe ní ẹnu àwọn arìndìn.+ 10  Bí tafàtafà tí ń gún ohun gbogbo ni ẹni tí ó háyà arìndìn+ tàbí ẹni tí ó háyà àwọn tí ń kọjá lọ. 11  Gẹ́gẹ́ bí ajá tí ń padà sídìí èébì rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni arìndìn ń tún ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hù.+ 12  Ìwọ ha ti rí ènìyàn tí ó gbọ́n ní ojú ara rẹ̀ bí?+ Ìrètí ń bẹ fún arìndìn+ jù fún un lọ. 13  Ọ̀lẹ sọ pé: “Ẹgbọrọ kìnnìún ń bẹ ní ọ̀nà, kìnnìún ń bẹ ní àwọn ojúde ìlú.”+ 14  Ilẹ̀kùn ń yí lórí ìkọ́ rẹ̀ olóyìípo, àti ọ̀lẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀.+ 15  Ọ̀lẹ fi ọwọ́ rẹ̀ pa mọ́ sínú àwokòtò àsè; àárẹ̀ ti mú un púpọ̀ jù láti mú un padà wá sí ẹnu ara rẹ̀.+ 16  Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀+ ju àwọn méje tí ń fúnni ní èsì olóyenínú. 17  Bí ẹni tí ó rá etí ajá mú ni ẹnikẹ́ni tí ń kọjá lọ, tí ó ń bínú kíkankíkan sí aáwọ̀ tí kì í ṣe tirẹ̀.+ 18  Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ya wèrè tí ń fi ohun ọṣẹ́ oníná tafà,+ àwọn ọfà àti ikú, 19  bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣe àgálámàṣà sí ọmọnìkejì rẹ̀, tí ó sì wí pé: “Eré ha kọ́ ni èmi ń ṣe?”+ 20  Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú, níbi tí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ kò bá sì sí, asọ̀ a dá.+ 21  Bí èédú ti wà fún ẹ̀ṣẹ́ná àti igi fún iná, bẹ́ẹ̀ ni alásọ̀ ènìyàn rí fún mímú kí aáwọ̀+ pọ́n yòò. 22  Àwọn ọ̀rọ̀ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ dà bí ohun tí a ó fi ìwọra gbé mì, èyí tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ikùn.+ 23  Bí fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́ tí a fi bo àpáàdì ni ètè tí ń jó belebele pa pọ̀ pẹ̀lú ọkàn-àyà búburú.+ 24  Olùkórìíra fi ahọ́n rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní ẹni tí kò ṣeé dá mọ̀, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀tàn sí inú ara rẹ̀.+ 25  Bí ó tilẹ̀ mú ohùn rẹ̀ kún fún oore ọ̀fẹ́,+ má gbà á gbọ́,+ nítorí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí méje+ ní ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀. 26  Ẹ̀tàn ni ó bo ìkórìíra mọ́lẹ̀. Ìwà búburú rẹ̀ ni a óò tú síta nínú ìjọ.+ 27  Ẹni tí ń wa kòtò yóò já sí inú rẹ̀ gan-an,+ ẹni tí ó sì ń yí òkúta kúrò—ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni yóò padà sí.+ 28  Ahọ́n èké kórìíra ẹni tí a fi í bàjẹ́,+ ẹnu ìpọ́nni a sì máa fa ìbìṣubú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé