Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 25:1-28

25  Ìwọ̀nyí pẹ̀lú ni òwe Sólómọ́nì+ tí àwọn ọkùnrin Hesekáyà ọba Júdà+ dà kọ:  Ògo Ọlọ́run ni pípa ọ̀ràn mọ́ ní àṣírí,+ ògo àwọn ọba sì ni wíwádìí ọ̀ràn kínníkínní.+  Ọ̀run fún gíga+ àti ilẹ̀ ayé fún jíjìn,+ àti ọkàn-àyà àwọn ọba, ìyẹn jẹ́ àwámáridìí.+  Kí mímú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ṣẹlẹ̀, gbogbo rẹ̀ yóò sì jáde wá ní yíyọ́ mọ́.+  Kí mímú ẹni burúkú kúrò níwájú ọba ṣẹlẹ̀,+ òdodo yóò sì fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+  Má bọlá fún ara rẹ níwájú ọba,+ má sì dúró ní àyè àwọn ẹni ńlá.+  Nítorí ó sàn kí ó sọ fún ọ pé: “Gòkè wá sí ìhín,”+ ju pé kí ó rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ níwájú ọ̀tọ̀kùlú tí ojú rẹ ti rí.+  Má fi ìkánjú jáde lọ ṣe ẹjọ́, kí ó má bàa jẹ́ ọ̀ràn kí ni ìwọ yóò ṣe ní òpin rẹ̀ nígbà tí ọmọnìkejì rẹ bá tẹ́ ọ lógo wàyí.+  Ro ẹjọ́ tìrẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ,+ má sì ṣí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹlòmíràn payá;+ 10  kí ẹni tí ń fetí sílẹ̀ má bàa kó ìtìjú bá ọ, tí ìròyìn búburú náà láti ẹnu rẹ kò sì ní ṣeé kó padà. 11  Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.+ 12  Yẹtí tí a fi wúrà ṣe, àti ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi àkànṣe wúrà ṣe, ni ọlọ́gbọ́n olùfi ìbáwí tọ́ni sọ́nà jẹ́ ní etí tí ń gbọ́ràn.+ 13  Gẹ́gẹ́ bí ìtutù minimini ìrì dídì+ ní ọjọ́ ìkórè ni olùṣòtítọ́ aṣojú jẹ́ fún àwọn tí ó rán an, nítorí ó ń mú ọkàn àwọn ọ̀gá rẹ̀ pàápàá padà bọ̀ sípò.+ 14  Bí àwọsánmà oníkùukùu àti ẹ̀fúùfù láìsí eji wọwọ ni ọkùnrin tí ń ṣògo lórí ẹ̀bùn èké.+ 15  Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.+ 16  Ṣé oyin ni o rí?+ Jẹ èyí tí ó tó ọ, kí o má bàa jẹ ẹ́ jù tí ìwọ yóò sì ní láti bì í.+ 17  Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣọ̀wọ́n ní ilé ọmọnìkejì rẹ, kí ọ̀ràn rẹ má bàa sú u, òun a sì kórìíra rẹ dájúdájú. 18  Bí ọ̀gọ ogun àti idà àti ọfà tí a pọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí ń jẹ́rìí lòdì sí ọmọnìkejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí èké.+ 19  Bí eyín tí ó ká àti ẹsẹ̀ tí ń gbò yèpéyèpé, bẹ́ẹ̀ ni ìgbọ́kànlé nínú ẹni tí ó jẹ́ aládàkàdekè ní ọjọ́ wàhálà.+ 20  Ẹni tí ó bá bọ́ ẹ̀wù ní ọjọ́ òtútù, jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọtí kíkan lórí ákáláì àti gẹ́gẹ́ bí akọrin tí ń kọrin fún ọkàn-àyà dídágùdẹ̀.+ 21  Bí ebi bá ń pa ẹni tí ó kórìíra rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.+ 22  Nítorí ẹyín iná ni ìwọ ń wà jọ lé e ní orí,+ Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì san ọ́ lẹ́san.+ 23  Ẹ̀fúùfù láti àríwá ń bí eji wọwọ gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí;+ ahọ́n tí ó sì ń tú àṣírí ń bí ojú tí a dá lẹ́bi.+ 24  Ó sàn láti máa gbé lórí igun òrùlé ju láti máa gbé pẹ̀lú aya alásọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ nínú ilé kan náà.+ 25  Bí omi tútù lára ọkàn tí ó rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ìròyìn rere láti ilẹ̀ jíjìnnà.+ 26  Ìsun tí ó di àìmọ́ àti kànga tí ó bàjẹ́ ni olódodo nígbà tí ó bá ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ níwájú ẹni burúkú.+ 27  Jíjẹ oyin ní àjẹjù kò dára;+ kí àwọn ènìyàn sì máa wá ògo ara wọn, ṣé ògo ni?+ 28  Bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé